Ẹ wo o, ẹ ma da Oshiomhole lohun o jare

Spread the love

Ọlorun ko ni i gba fun un, nitori ninu awọn to fẹẹ ba orilẹ-ede yii jẹ, ọga kan ni Adams Oshiomhole. Awọn ọrọ ti ọkunrin naa n sọ lati ọjọ yii ti fi han pe o mọ daadaa si iṣẹlẹ to ṣẹ nile-igbimọ aṣofin naa, o lọwọ si i, o si lẹsẹ si i. Adanu lọkunrin yii jẹ fun APC, nitori fun ẹni to ti ṣe gomina fọdun mẹjọ lati maa huwa bii ọmọ gareeji bayii, ko sọ pe ada ati ipanle loun yoo fi gbajọba lọwọ ẹni to wa nibẹ, ko maa funra ẹ sọ pe awọn yoo yọ Saraki, ọrọ were ti ko mu laakaye dani rara ni. Saraki le ma jẹ eeyan daadaa, ṣugbọn oun kọ lo fi ara rẹ ṣe olori ile-igbimọ aṣofin, awọn kan ni wọn yan an sibẹ. Ninu awọn ti wọn yan Saraki yii, awọn ti wọn ti ṣe gomina nigba ti Oshiomhole ko ti i jẹ kinni kan wa ninu wọn, awọn ti wọn si tun jọ ṣe gomina wa ninu wọn, awọn ti wọn kawe, ti wọn ni laakaye ju Oshiomhole lọ wa ninu wọn, bi wọn ko ba si fẹ Saraki mọ, funra wọn ni wọn yoo yọ ọ. Ẹgbẹ APC nikan kọ lo wa nile-igbimọ, awọn ẹgbẹ oṣelu bii marun-un mi-in ni wọn tun wa nibẹ. Ki waa ni ariwo yẹyẹ ti Oshiomhole n pa pe oun yoo yọ Saraki gẹgẹ bii olori ile-igbimọ aṣofin. Bẹẹ ọkunrin alainitiju yii lo lọọ gba Akpabio to kuro ninu PDP bọ sinu ẹgbẹ tiwọn lalejo lọsẹ to kọja yii naa, ki lo de ti ko ni ko kuro nile-igbimọ aṣofin. Eeyan yẹpẹrẹ, eeyan iranu gbaa lọkunrin Oshiomhole yii, awọn ti wọn n lo agbara ijọba nilokulo ni. Ẹ ma da a lohun o, ki ẹ ma si tẹle e, ọjọ ẹlẹya rẹ ti sun mọ etile.

 

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.