Ẹ wo o, ẹ jẹ kawọn oloṣelu yii maa ṣe tiwọn, kemi naa maa ṣe temi

Spread the love

Nigba ti mo sọ pe ajalu buruku kan n bọ lori Naiijiria, awọn kan ni ki n ma sọ bẹẹ, wọn ni mo n ṣepe, bẹẹ agbalagba ki i ṣepe. Ṣe iyẹn ṣee ṣe ni! Bawo ni mo ṣe fẹẹ ṣepe fun Naijiria, ṣebi ibẹ lemi naa wa, ko si sibi ti mo fẹẹ sa gba lasiko yii mọ, ohunkohun to ba n bọ, oju wa yii naa ni yoo ṣe. Ṣugbọn iyẹn ko sọ pe ti a ba ri ootọ ọrọ, ka ma sọ ọ. Ko sọ bẹẹ rara. Ọpọ igba ni mo ti sọ ọ nibi yii pe ko sohun meji to n fa aburu ni Naijiria ju irẹjẹ lọ. Awọn ti wọn lagbara n rẹ awọn ti wọn ko lagbara jẹ, bi o ba si bi wọn idi ti wọn fi n ṣe bẹẹ, wọn yoo sọ fun ọ pe ko sohun talagbara yoo jẹ ti ko ba rẹ ẹni ti ko lagbara jẹ. Ọrọ awọn ika ati tawọn ọdaju niyẹn, ọrọ awọn ti wọn n ja ile onile fi bo tiwọn lẹyin, ọrọ awọn ti wọn n pa ọmo ẹlomi-in lẹkun kọmọ tiwọn le maa rẹrin-in, awọn ti wọn n ba aye jẹ ti wọn lawọn lawọn n tun aye ṣe.

Gbogbo yin lẹ n yọ mi lẹnu pe ki n sọrọ lori ọrọ ibo to waye ni ipinlẹ Ọṣun ati ohun to ṣẹlẹ si Ambọde l’Ekoo. Ṣugbọn mo yẹra, mi o fẹẹ sọ kinni kan, nitori bi ọrọ to ṣẹlẹ naa ko ba ye awọn mi-in, yoo ye awọn ti wọn n ka ọrọ mi bọ latẹyin: gbogbo ọrọ yii ni mo ti ṣalaye sẹyin ko too di asiko yii rara. Ẹyin lẹ koriira ologbo ti ẹ n gbe kọlọkọlọ sabẹ, ẹyin ni ẹ ko mọ pe ika ati aburu ti kọlọkọlọ yoo ṣe yoo le ju ti ologbo lọ. Gbogbo igba ti mo n pariwo pe ko si iyatọ ninu oloṣelu Naijiria, pe ko siyatọ kan ninu APC ati PDP, pe awọn kan naa ti wọn n ṣe PDP naa lo pada di APC, pe orukọ wọn lo yatọ, iwa wọn ko yatọ. Ọpọ awọn ọrẹ mi tẹlẹ ni wọn mu mi lọtaa nitori ọrọ bẹẹ, koda, awọn mi-in sọ mi dọmọ ẹgbẹ PDP, wọn ni wọn ti gbowo fun mi ni. Ọrọ omugọ gbaa!

Sebi gbogbo wa la jọ wa niluu yii. Bo ba jẹ loootọ ni mo gbowo wọn, ko sohun to bo labẹ ọrun, aṣiri iba ti tu, koda, bo jẹ miliọnu kan ni wọn fun mi, o da mi loju pe awọn kan yoo ti sọ ọ di ọgọrun-un miliọnu, funra mi ni n o si maa ṣepe pe n ko gba miliọnu ọgọrun-un, miliọnu kan pere ni wọn fun mi. Ṣugbọn awọn eeyan koriira ootọ ọrọ, nitori ole lo pọ ninu yin! Ohun ti awọn oloṣelu to n ji owo ko n ṣe yii lọpọ ẹyin naa yoo ṣe tẹ ẹ ba debẹ! Tabi kin ni iyatọ ninu oloṣelu to n ha owo lati ra ibo ati ẹni to n ta ibo tirẹ lati gba owo. Ole kan naa ni gbogbo wọn. Oloṣelu to n ra ibo tilẹ tun san ju ẹni to n ta ibo lọ. Oloṣelu to n ra ibo mọ pe owo loun n lọọ ṣe, ko si fi pamọ fẹnikẹni pe oun n lọọ jale nibi ti oun n lọ yii ni, ṣugbọn ẹni to mọ pe o n lọọ jale ni, to wa n gba owo lọwọ rẹ nkọ! Oun gangan ni baba omugọ ati alailọpọlọ. Ole gidi!

Nigba ti wọn n ṣejọba Ọṣun, ti mo pariwo pe Rauf ko gbajumọ laarin awọn eeyan to bo ṣe ri tẹlẹ mọ, ati pe iṣejọba rẹ, ariwo ati ẹtan lasan lo pọ nibẹ, awọn kan ti wọn ki i ronu – wọn si n ronu o, aimọkan ati ohun ti wọn n jẹ lẹnu lo n ko wọn ni laakaye lọ – wọn n bu mi, awọn mi-in n ṣepe, wọn ni kin ni Rauf gba lọwọ mi. Rauf waa jẹ ẹni ti n ko mọ tabi ẹni ti mo koriira, lẹni ti a ti jọ ṣeto ijọba ilẹ Yoruba yii daadaa ri ko too depo to de. Ṣugbọn nigba ti ẹnikan ba n tan araalu jẹ, ti wọn n sọ pe oṣelu lawọn n ṣe, emi ki i si nidii iru ajọṣe bẹẹ, nibi ti mo ti yatọ si ọpọ awọn ti ẹ n ri ree. Tabi kin ni awọn aṣaaju APC Ọṣun yoo wi, PDP gba ipinlẹ naa lọwọ wọn, ẹni ti ko si yẹ ko tilẹ duro niwaju iru awọn Rauf lo n fi wọn ṣe yẹyẹ, bi ko si si agbara ijọba apapọ, ati etekete awọn eeyan yẹpẹrẹ bii Omiṣore, ṣe PDP ko ti gba ipinlẹ Ọṣun ni. Njẹ o tilẹ ṣee gbọ seti pe Rauf ati Omiṣore jokoo nitori oselu? Haa, o ma ṣe o!

Bi mo ba wa sibi ti mo ba sọ pe Bọla ko ṣe oṣelu tirẹ nitori Yoruba, tabi nitori Eko paapaa, awọn eeyan kan ti duro ti wọn yoo gbẹnu soke: “Baba yii lọọ jokoo jẹẹ. Kin ni Bọla ṣe fun ẹ! Bo ba jẹ owo lo niidi, sọ fun un, o maa fun ẹ lowo! Olori ilẹ Yoruba niyẹn!”, awọn ọrọ rirun ti wọn maa n sọ ranṣẹ si mi ree. Ṣugbọn ẹni ti Ọlọrun ba jogun laakaye fun, ko lo o bayii o! Se yiyọ ti wọn fẹẹ yọ Ambọde nipo to wa yii, ti wọn ni ko le ṣe gomina mọ yii, ṣe awọn ara Eko ni wọn sọ pe Ambọde ko ṣe daadaa gẹgẹ bii gomina ni, abi Bọla lo sọ pe ko ṣe daadaa. Ki lo ṣe ti ko daa? Wọn ni ko kowo fawọn aṣaaju APC ti wọn n ṣe oselu Eko, ati pe o di ọna ibi tawọn agbaagba APC kan ti n rowo ko tẹlẹ mọ wọn, ko mọ bi wọn ti n tọju awọn agbaagba ẹgbẹ. N lawọn agba ẹgbẹ APC ba lawọn ko fẹ ẹ. Ta ni agbaagba APC Eko lẹyin Bọla?

Ile Yoruba wa ninu igbekun, igbekun gidi paapaa. Iru ohun to n ṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ gbẹyin si Yoruba, laye Akintọla ni. Nibi ti awọn oṣelu yoo maa fi irọ bo ootọ mọlẹ, nibi ti awọn ti wọn n ba aye awọn eeyan jẹ yoo maa sọ pe awọn lawọn n tun aye wọn ṣe. Nibi ti wọn aa ti sọ awọn eeyan di ọta ara wọn nitori ki awọn le ri ọna lọ, ti wọn yoo jẹ kawọn eeyan maa pa ara wọn danu lasan nitori wọn fẹẹ di ọga oṣelu, ti wọn yoo sọ awọn ọmọọta dọga, ti wọn yoo sọ tọọgi dalagbara, ti tọọgi yoo maa halẹ mọ awọn ọmọwe ati awọn ọjọgbọn ilu, to si jẹ gbogbo ẹ naa, nitori pe wọn fẹẹ wa nipo lati ji owo ilu ko ni. Ariwo ti wọn yoo maa pa fun yin ni pe gbogbo ohun ti awọn n ṣe yii, awọn n ṣe e nitori yin ni, nitori araalu, awọn fẹẹ gba yin lọwọ awọn kan ti wọn n ji owo yin ko, awọn fẹẹ gba yin lọwọ awọn kan ti wọn n fiya jẹ yin.

Ṣugbọn ti agbara ti a n wi yii ba de ọwọ wọn, iya ti wọn yoo fi jẹ yin yoo ju ti awọn ti wọn sọ yin di ọta wọn yii lọ.  Tabi ilọsiwaju wo lo ba ilẹ Yoruba lati ọdun 2015! Bi o ba si sọrọ bayii, kia ni wọn yoo ti ta pẹẹrẹpẹ mọ ọ, wọn aa ni ilọsiwaju kan ko le si nilẹ Yoruba nitori Jonathan atawọn PDP ti ṣejọba lọdun mẹrindinlogun, wọn ti ko gbogbo owo jẹ. Wọn ko jẹ sọ pe laye PDP yii l’Ọbasanjọ ṣejọba to ko GSM delẹ yii, ati pe ki ẹgbọn yii too de, mẹkunnu kan ki i lo foonu. Wọn ti gbagbe pe Naijiria ko ni ATM ni banki tẹlẹ, iṣẹ ọwọ ẹgbọn yii ni. Ṣe iyẹn sọ pe ẹgbọn tabi awọn eeyan rẹ ko jale ni. Ṣugbọn awọn ti wọn n jale lojoojumọ bayii, ti wọn o si ṣe nnkan kan fun ilu yii nkọ! Lọjọ wo ni idajọ tiwọn fẹẹ de, lọjọ wo ni awọn eeyan yoo si gbọn lati mọ pe awọn ni wọn n ṣe wọn ni aburu to pọ julọ.

Bọla ko ni i sọ fun yin pe PDP ni Atiku nigba ti oun pẹlu ẹ fẹẹ gbajọba lọwọ Yaradua ni 2007. Wọn ko ni i sọ fun yin pe PDP ni Saraki, Amaechi, Tambuwal, El Rufai, atawọn to ku wọn ti wọn sare lọọ ba nigba ti wọn fẹẹ gbajọba lọwọ Jonathan. Bisi ati Rauf o ni i ran yin leti pe PDP ni Omiṣore nigba ti wọn fẹẹ lọọ lo o lati feru gbabukun, ti wọn ji ibo awọn ara Ọsun. Bi mo ba ti n ro o ni ori mi si n ṣe bakan, pe ninu ẹgbẹ oṣelu ti Bisi wa, ẹgbẹ oṣelu naa ni yoo bẹ Omiṣore lati wiini ibo! Iyiọla kan naa! Tabi Bisi ati Raufu ko ranti awọn ohun to ṣẹlẹ ni 2001 mọ ni!

Ohun ti mo n sọ fun yin niyẹn. Oṣelu Naijiria, kidaa ẹtan ni, irẹjẹ ni, ika ni! Nibi ti awọn nnkan wọnyi ba si ti wa, ajalu nla n bọ nibẹ, ki olori dori ẹ mu ni.

Ẹ wo o, n ko fẹẹ sọrọ oṣelu mọ jare, nitori n ko fẹ arifin awọn ọmọ kan. Ẹ jẹ kawọn oloṣelu yii maa ṣe tiwọn, ki emi naa si maa ṣe temi. A o maa ba ọrọ aṣaaju Yoruba ti a n sọ bọ lọsẹ to n bọ.

 

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.