Ẹ wa, ẹ jẹ ka dupẹ lọwọ Ọṣinbajo

Spread the love

Ohun yoowu ki ẹnikẹni sọ, boya Buhari ni wọn lo fun un laṣẹ ni o, abi oun funra rẹ lo paṣẹ naa, ko si ẹni to yọ wa kuro ninu ewu bi ko ṣe Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo. Lile to le olori awọn SSS, Lawal Daura, kuro lẹnu iṣẹ lẹẹkan naa ti ọrọ yii ṣẹlẹ fi ọkan awọn araalu balẹ, o si mu ki ọkan awọn orilẹ-ede agbaye gbogbo to n woye ohun to ṣẹlẹ naa balẹ pe Naijiria ko ti i di ilu awọn ologun, ati orilẹ-ede ti dẹrẹba rẹ ti mugbo yo, to kan n wa mọto kiri titi, to fẹẹ fori mọto naa sọgi. Bakan naa ni eeyan gbọdọ dunnu si pe wọn n wadii ọkunrin yii wo, iyẹn Daura, nitori iwa rẹ ko jọ ti ẹni to fẹ alaafia fun Naijiria, ẹni to n fẹẹ da rukerudo ti yoo da Naijiria ru silẹ ni. Ọwọ ọkunrin naa ko mọ, oun nikan lo si le sọ ẹni to n ba ṣiṣẹ. Bo ba tiẹ jẹ bi wọn ti n royin rẹ pe o fẹran owo ẹyin yii ni, ohun ti Ọṣinbajo ṣe nipa rẹ yii lo dara julọ. Ki Buhari too gbajọba nijọsi lo ti ṣeleri pe ijọba oun ko ni i da sọrọ ile-igbimọ aṣofin, bẹẹ lawọn o ni i di awọn to n ṣeto idajọ lọwọ. Ṣugbọn ko mu ọrọ naa ṣẹ. Eyi ti Ọṣinbajo ṣe yii fọkan ọpọ eeyan balẹ diẹ, ohun ti a si n ro bayii ni pe nnkan yoo yipada, ijọba Buhari yoo maa tẹle ofin Naijiria ninu ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe.

 

(59)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.