Ẹ tọju pata yin o ẹyin obinrin

Spread the love

Eyi ti a tun n gbọ bayii ko yeeyan o, pata awọn obinrin ni wọn sọ pe awọn kan tun n ka lọ lati fi ṣoogun owo o. Wọn ti n mu wọn kaakiri, iroyin ọrọ naa si ti gbilẹ o, eeyan ko si gba a gbọ, nitori ko sẹni to mọ ohun ti awọn eeyan yoo fi pata onipata ṣe. Ṣugbọn awọn kan ti wa to jẹ pata obinrin ni wọn n ji ka, bẹẹ ni wọn n ko awọn tọilẹẹti-roolu ti wọn fi n ṣe nnkan oṣu, wọn yoo si ko o, wọn yoo di i rugudu, awọn nikan ni wọn mọ ohun ti wọn fẹẹ fi i ṣe. Bi ko si jẹ ti ẹni ti wọn mu ni Ondo, baba agbalagba ti wọn mu yii ni, awọn eeyan iba ṣi maa sọ pe irọ ni wọn n pa ni. Wọn ni wọn mu ọkunrin naa ni Akurẹ, o ti ko pata onipata sinu apo, pata awọn obinrin ni gbogbo ẹ.  Bi ko jẹ wọn ri i ti wọn si gba a lọwọ rẹ, Ọlọrun nikan lo mọ ohun to fẹẹ fi i ṣe. Ṣugbọn awọn araadugbo naa sọ pe bi ko ba jẹ o fẹẹ lo o funra rẹ fun oogun owo, aa jẹ pe o fẹẹ ta a fun awọn ti wọn n lo o ni, nitori owo gọbọi lo ku ti awọn eeyan yii n ra pata, paapaa eyi to ba ni nnkan oṣu obinrin ninu, ti ẹjẹ ṣi wa lara rẹ. Pata obinrin lo ku tawọn eeyan yii tun n lo foogun owo o. Nnkan ti bajẹ, aye paapaa si ti dorikodo, o jọ pe igba ikẹyin ti wọn n pariwo ti de. Ko si ohun ti awọn eeyan ki i fi wa owo mọ lasiko ti a wa yii, ọna okunkun si ni, ki i ṣe ọna to dara. Awọn ti wọn n mu lọ lati wa owo ojiji yii naa da bii awọn ti wọn n ṣe,**** eṣu ti ti wọn debi ti ko daa. Awọn ti wọn n mu awọn ọmọbinrin, awọn ọmọ ọlọmọ, ti wọn n fi wọn ṣe etutu, ti wọn n ge wọn lori ati ẹya ara lọ, ti wọn sọ awọn eeyan doku nitori pe awọn fẹẹ lowo, awọn lo kọkọ pọ nigboro tẹlẹ, eyi ti wọn si tun waa ko de yii, Ọlọrun lo mọ bo ti jẹ o. Ohun to ṣẹlẹ ṣaa ni pe ẹni yoowu ti wọn ba ri nnkan oṣu rẹ, tabi pata to ti fi si oju ara rẹ lati fi ṣe ohunkohun ko ni i gbaduna aye rẹ mọ, awọn ẹni eṣu yii yoo lo o fun iṣẹ aburu wọn ni. Tori bẹẹ, ẹyin obinrin, ẹ tọju pata yin o, ẹ tọju nnkan oṣu yin daadaa, ẹ ma jẹ ko bọ sọwọ awọn abatẹnijẹ o. Ọlọrun ko ni i jẹ ka rogun arinfẹsẹsi, a ko ni i ha sọwọ awọn apanilẹkunjaye o.

 

 

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.