Ẹ sọ ohun to n ṣe yin gan-an

Spread the love

Afi ki ijọba Buhari sọ ohun ti wọn n fẹ fawọn araalu, ati idi ti wọn ṣe fẹ ẹ. Gbogbo eyi ti wọn n ṣe ati ariwo ti wọn n pa yii, ohun ti wọn n fẹ kọ ni wọn n ṣe yii o. Kinni kan wa lọkan wọn, ṣugbọn wọn ko le sọ ọ sita nitori pe nnkan naa, ohun aburu ni. Bi awọn Fulani ajinigbe ṣe n ṣe wahala kiri, ti wọn n da ijangbọn silẹ, ti wọn n ji awọn eeyan gbe, ti wọn n pa awọn ti wọn fẹẹ pa, ti wọn si n ba iṣẹ oniṣẹ jẹ kaakiri, ijọba apapọ ko mu eto kan gidi jade lori ohun ti awọn fẹẹ ṣe lati kapa iwa yii. Bi ẹnikẹni ba sọrọ, wọn yoo yi tọhun sọtun-un, wọn yoo yi i sosi, wọn yoo maa sọ ohun ti ko ṣẹlẹ, wọn yoo tun maa purọ. Wọn le ni ọrọ naa ko le to bawọn eeyan ti n sọ ọ, tabi ki wọn ni ko tilẹ si ohun to jọ bẹẹ. Lọna Ibadan si Eko lọsẹ to kọja, wọn ji awọn mẹta kan gbe, ọmọ dokita to ni ileewosan Lafia Hospital, wa laarin wọn. Ṣugbọn ko sẹni ti yoo gba wọn, awọn ọlọpaa ko ri awon ajinigbe yii mu, wọn ko ri awọn eeyan yii gba silẹ, ko si si ṣọja tabi ọlọpaa ti yoo wọ inu igbo lọọ ba wọn. Afi igba ti wọn gba owo lọwọ awọn eeyan wọnyi, ti wọn si ṣe wọn bo ti wu wọn ki wọn too tu wọn silẹ. Ijọba yoo si ni awọn ko gbọ, awọn ọlọpaa yoo ni awọn ko tilẹ mọ, tabi ko jẹ lẹyin ti wọn ti gbe awọn ti wọn fẹẹ gbe ni wọn yoo maa sare kiri, ti wọn yoo maa dalẹ laamu, ti wọn yoo maa ṣa awọn ti ko mọwọ ti ko mẹsẹ to ba n rin lọ jẹẹjẹ wọn da satimọle lati gba owo lọwọ tiwọn. Ọkan ninu ọna lati mu awọn eeyan yii ni lilo baaluu ofurufu kan to jẹ oun funra ẹ lo maa n da rin, amọ gbogbo bi o ba ti n da rin ni yoo maa ka fidio ohun gbogbo to ba ri, iyẹn ni wọn n pe ni duroonu (drone). Awọn gomina kan ti mura lati ra baaluu to n da ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ yii, ki wọn le maa fi ri awọn ti wọn n ṣe iṣẹ aburu wọnyi ati ibi ti wọn n gbe. Ṣugbọn ijọba apapọ ko jẹ ki wọn ṣe e, bi wọn ba ti n gbe ọwọ kan ni wọn yoo maa ni ko ri bẹẹ, ki wọn ni suuru, awọn naa fẹẹ ṣe iru rẹ, awọn ko si le jẹ ki awọn ipinlẹ dojukọ eto aabo, awọn mọ ohun ti awọn n ṣe. Ohun ti awọn eeyan yii n ṣe ko ye ẹni kan, awọn nikan lo ye. Bẹẹ ni ki i ṣe pe ko ye awọn eeyan, awọn ti wọn lọgbọn mọ pe wọn n gbe lẹyin awọn ti wọn ṣe iṣẹ aburu yii ni. Tabi ki lo yẹ ko fa wahala tabi idaduro ninu iyẹn, ki ọkunrin ri ejo ki obinrin pa a, ṣebi bi ejo ba ti ku, abuṣe buṣe. Bi ijọba ipinlẹ kan ba mọ pe ohun ti yoo kapa iwa ọdaran nipinlẹ toun ree, to ba fẹẹ ṣe e, kin ni ijọba apapọ yoo maa mu un lọwọ dani si. Kin ni wọn fẹẹ gba ninu ohun ti wọn n ṣe yii gan-an. Awọn eeyan yii ko fẹran mẹkunnu ilẹ Yoruba o, wọn ko si fẹran araalu rara. O buru pe ijọba apapọ ni yoo maa kin awọn ọdaran lẹyin, ti wọn yoo maa gbe lẹyin wọn lati ṣe aburu kaakiri. Amọ iru awọn nnkan bayii ki i lọ ko pẹ titi laye, Ọlọrun yoo da si ọrọ Naijiria yii nijọ kan, Ọlọrun yoo gba wa, oju yoo si ti gbogbo awọn ti wọn n ṣe aburu gbogbo. Ẹ sọ fun ijọba apapọ ko jẹ ki wọn gba awọn ipinlẹ laaye lati ṣeto aabo lọdọ wọn, ohun to le tete mu ọrọ awọn ajinigbe ati awọn apaayan yii yanju niyẹn o.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.