Ẹ sọ fun Ọba Ilu Ilọrin ko ma gbagbe itan o

Spread the love

Aye ko ye ọpọlọpọ eeyan. Awọn ẹlomi-in wọn yoo sọ pe awọn lọgbọn, awọn ni imọ, koda, awọn eeyan mi-in yoo pe ara wọn ni aafaa tabi wolii, wọn yoo ni awọn lawọn sun mọ Ọlọrun julọ. Sibẹ, wọn ki i mọ ọrọ ile aye yii, ati bi Ọlọrun Ọba to laye ṣe n ṣe eto aye, ati bo ṣe n ṣedajọ aye. Ẹnikẹni to ba n rẹ ọmọlakeji jẹ, tabi to fi eru gbabukun, tabi to jokoo lori ohun olohun to si fi n ṣe aye tirẹ, ti iru ẹni bẹẹ waa n ro pe oun ti ṣe kinni naa gbe, eeso aburu lo n gbin silẹ fawọn ọmọ rẹ, nitori lọjọ to ba ya, lọjọ ti iji lile ẹsan ba de, awọn ọmọ ọmọ ati arọmọdọmọ, titi dori iran yoowu to ba wa laye nigba naa ni yoo jẹ iya naa ni ajẹdọba. Bi ọba kan ba fọtẹ joye, to waa n fi agidi ati agbara ipo tẹ ori awọn to ni nnkan gan-an bolẹ, to n jẹ wọn niya, to n tẹ wọn loju, bẹẹ oun lo gba nnkan wọn, oun lo gba ilẹ wọn, ki iru ọba bẹẹ ma gbagbe itan, nitori ohun to wa lẹyin Ọfa ju Oje lọ.

Nigba ti mo ka ọrọ ti ẹgbọn wa agba pata, Ọlọla Kasumu, sọ lati Ilọrin, bo ba jẹ mo ni omi loju ni, n ba ja omi soju, ṣugbọn pẹlu aileṣomi loju naa, ọgbẹ nla gba inu ọkan mi. O gba ọkan mi nitori irẹjẹ ti awọn ti wọn lagbara ninu awọn ẹya Fulani Ilọrin ro pe awọn n ṣe fun awọn ọmọ Yoruba Ilọrin. Mo fẹ ki ẹ jẹ ka mu ọrọ yii ni ọna ti yoo fi ye wa o, n ko fẹ ki ọrọ naa da ija silẹ laarin awọn eeyan ilu, awọn ọmọ ilu Ilọrin ti wọn gba pe ọmọ Ilọrin tootọ lawọn, boya Fulani ni wọn o, tabi Yoruba ni wọn. Ṣe ẹ ri i, ẹran ti wọ inu eegun, eegun ti wọ inu ẹran. Oponu eeyan ni yoo sọ pe awọn Fulani Ilọrin ki i ṣe ọmọ ilu Ilọrin. Ọmọ Ilọrin ni wọn, koda, Yoruba ni wọn, wọn kan jẹ ẹya kan ninu iran Yoruba, bi a ṣe ni Ekiti, ti a ni Ẹgba, ati awọn mi-in ni. Ki i ṣe awọn ọmọ ilu Ilọrin yii ni mo n ba wi o, ṣugbọn awọn Ẹmaya ati iran wọn ti wọn n jọba ilu Ilọrin ni.

Yoruba ni wọn o. Ṣugbọn nigba ti wọn ba fẹẹ fi orukọ Fulani lu jibiti,  wọn yoo ni Fulani lawọn, koda wọn yoo maa ba yin jiyan pe awọn ki i ṣe Yoruba rara. Ṣugbọn ẹ da wọn jokoo, kẹ ẹ beere ile baba wọn ni Sokoto tabi Gwandu. Bi wọn ba ni awọn ko mọ ile baba awọn nibẹ, ẹ beere ile baba baba wọn, tabi baba to bi baba baba wọn. Wọn ko lẹni kan ninu iran wọn ni awọn ilu yii, koda Abdu-Salih ti Afọnja pe wa si Ilọrin ki i ṣe ọmọ Sokoto tabi Gwandu, Nijee lo ti wa. Nitori idi eyi, awọn eeyan yii ko ni ede kan tabi orukọ kan to jẹ ti Fulani, ti a ba ti yọ orukọ Islam kuro ninu orukọ wọn, orukọ Yoruba lo ku. Tabi ki ẹ beere oriki wọn lọwọ wọn, wọn ko loriki mi-in ju ti Yoruba yii lọ. Tabi Fulani loriki ni! Ohun ti ẹ oo fi mọ pe Yoruba ni wọn ree, nitori  Yoruba ni baba wọn, Yoruba ni baba to bi baba wọn, ati baba baba wọn kẹrin, ilu Ilọrin ni wọn bi gbogbo wọn si.

Ṣugbọn onijibiti lawọn eeyan, ika si ni wọn pẹlu. Nitori pe awọn Fulani lagbara ni Naijiria, ti awọn eeyan yii si n ri jẹ labẹ wọn, iyẹn ni wọn ṣe n wa ara wọn mọ Fulani lọrun, ti wọn n sọ pe Fulani lawọn, awọn ki i ṣe Yoruba. Bi eeyan ba si fẹẹ jẹ Fulani, ko si ohun to buru nibẹ rara, ko fi ilẹ Yoruba silẹ fun Yoruba, ko yee waa fi orukọ Fulani jọba ilẹ Yoruba, ki wọn si jokoo sibi kan ki wọn maa sọ isọkusọ jade lẹnu. Mo ti sọ fun yin nigba kan pe iran awọn ti wọn n jọba wọn ni ilu Britain ti a n pe ni England, nibi ti ọba ilu oyinbo yii wa, lati orilẹ-ede Germany ni wọn ti lọ, ogun ni wọn ja debẹ. Ṣugbọn loni-in, awọn lọba ibẹ, ko si sẹni ti yoo gbọ lẹnu ọba kan ti yoo jẹ ni England ko sọ pe ọmọ Jamani loun, baba oun tabi pe ile baba oun wa ni Berlin. Lọjọ ti ọba kan ba sọ bẹẹ naa ni yoo fi ipo Ọba England silẹ, ṣeeṣi ni wọn ko si ni i mu un fun iwa idoju-ijọba bolẹ, tabi idaluru.

Orilẹ-ede tiwa nibi ni palapala oriṣiriṣi ti wa, ti wọn yoo maa rẹ awọn eeyan jẹ, ti wọn yoo si maa fihan pe wọn awọn n rẹ wọn jẹ. Bi awọn ti wọn n jọba Fulani kan ba duro ti wọn ba ni awọn ko Yoruba logun n’Ilọrin, ẹ sọ fun tọhun pe irọ lo n pa, koda ẹ bu iya rẹ kẹ ẹ fi baba rẹ le e. Awọn Fulani ti wọn n jọba ilu Ilọrin loni-in yii, wọn dalẹ ni, ilẹ ni wọn da, wọn gbẹyin bẹbọ jẹ. Iyẹn ki i ṣe pe eeyan jagun gba ilẹ ẹnikan. Ẹni to n ṣe iṣẹ aafaa rẹ jẹẹjẹ, ti olori ologun si ranṣẹ si i pe ko waa ba oun bẹ Ọlọrun si iṣoro to wa niwaju oun, to waa debẹ to ba a bẹ Ọlọrun tan, ti adura to ṣe si gba, to waa jokoo to loun o lọ mọ, to si dẹ awọn ọmọ ogun rẹ si ẹni naa lati gba ilẹ rẹ, ati awọn ohun-ini rẹ lọwọ rẹ, to wa n yan fanda pe toun ni. Ṣe to ba ya, Ọlọrun ko ni i bẹ iru iran awọn eeyan to ba n ṣe bẹẹ yẹn wo ni. Yoo ṣẹlẹ nijọ kan,  o le ma jẹ loju iru wa. Ṣugbọn yoo ṣẹlẹ.

Ọrọ aafaa to dalẹ Afọnja ko yatọ si ọrọ ọkunrin kan ti iyawo rẹ ko ri ọmọ bi, to waa lọ si ọdọ baba aafaa kan pe ko ba oun ṣe oogun oyun, to si ri oogun naa ṣe fun iyawo yii, ti iyawo waa loyun, to si bimọ, ti aafaa dide to gba iyawo rẹ, to si gba ọmọ, to waa pa ọkọ obinrin to mu iyawo rẹ wa fun itọju. Iwa ọdalẹ kan wa tun ju bẹẹ lọ ni! Ọrọ Ọlọla Kasumu lo jẹ ki n maa ronu loriṣiriṣi bayii, ki n si maa fibinu sọ awọn ọrọ ti mo n sọ. Ọlọla Kasumu ni ni gbogbo Ilọrin, ko si ibi ti wọn ti fi ileeṣẹ kan, tabi adugbo kan, tabi nnkan pataki kan pe Afọnja to jẹ ọmọ onilẹ, to jẹ ọmọ ẹni to tẹ ilu Ilọrin do. Kasumu ni gbogbo ohun yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe lorukọ Afọnja, awọn ọba Fulani yii ni wọn yoo gbegi di i, pe gbogbo ohun to wa lọkan wọn ni bi ẹnikẹni ko ṣe ni i ranti orukọ Afọnja mọ, ti wọn yoo gbagbe rẹ tiran-tiran.

Bẹẹ iyẹn ko si ṣee ṣe, ko le ṣee ṣe rara. Idi ni pe lati ọrun l’Afọnja ti gbe orukọ tirẹ wa, orukọ rẹ ko si le parẹ lara Ilọrin. Boya ọba Fulani kan fẹ tabi o kọ, bi wọn ba ti n pe Ilọrin, wọn yoo maa pe Afọnja mọ ọn. Bẹẹ ole lo n pa wọn ku, iyẹn ni mo ṣe sọ pe ọrọ Ilọrin ki i ṣe laarin awọn ọmọ Yoruba to jẹ ilẹ Fulani ni wọn ti wa, ọrọ laarin awọn ọmọ Yoruba to n sọ pe Fulani lawọn ni, bẹẹ wọn ko nile nilẹ Fulani, ko sẹni to da wọn mọ nibẹ, nitori owo ti wọn n gba l’Abuja ni wọn ṣe n sọsọkusọ. Ko si si beeyan yoo ṣe ṣe iyẹn ti ko ni i kan adanwo nijọ kan, bi oun ko ba kan an, awọn ọmọ ọmọ rẹ yoo kan an. Nijọ ti ẹsan iru nnkan bẹẹ ba waa de, awọn ti iru rẹ ti ṣẹlẹ si ninu awọn iwe itan ọrọ Ọlọrun, wọn maa  n pa wọn run nibi ti wọn wa ni, nitori awọn ọmọ onilẹ yoo gba ilẹ naa patapata, wọn ko si ni i fi oju ire wo awọn ajoji to ti fi ọpọlọpọ ọdun rẹ wọn jẹ. Bi a ti n wi yii, iru rẹ n ṣẹlẹ ni orilẹ-ede South Afrika, laarin awọn oyinbo ibẹ ati awọn alawọ-dudu ti wọn ni ilẹ wọn.

Fun bii ọgọrun-un meji ọdun lawọn oyinbo fi jẹ gaba le awọn ti wọn ni ilẹ wọn lori, ṣugbọn nijọ kan, wọn gba ilẹ wọn pada, awọn ọmọ onilẹ si bẹrẹ si i le awọn oyinbo yii kiri, bi ko si jẹ tawọn aṣaaju wọn to ṣi wọn lọwọ, ọrọ naa kiba buru ju bẹẹ lọ. Ṣugbọn awọn ilu mi-in ko ri bẹẹ, aburu to ba awọn arẹnijẹ naa ko tan lara iran wọn titi laye, nitori awọn ti wọn ti n jọba tẹlẹ pada waa di ẹru awọn ọmọ onilẹ ni. Nijọ kan, ẹnikan n bọ ni Ilọrin yii, ọmọ Afọnja kan yoo dide, yoo si pada gba awọn ogun ti awọn to n pe ara wọn ni Fulani yii gbẹsẹ tẹ, wọn yoo si le wọn danu lori itẹ ati ni agbegbe naa, yoo si ṣẹku awọn ọmọ Yoruba ti wọn ti ilẹ Fulani wa, ti wọn si ti mọ pe Ilọrin ni ile awọn, Yoruba lawọn, awọn kan wa lati Fulani ni. Ṣugbọn awọn wahala to n bọ naa ṣee bi danu, ko si si ohun ti wọn yoo fi bi i danu ju iwa daadaa lọ.

Ẹ ranti Afọnja, ẹ fi orukọ rẹ sọ awọn ileeṣẹ nla tabi ibudo nla, ẹ fi orukọ rẹ sọ opopona nla ni ilu Ilọrin, nigba to jẹ orukọ Alimi wa nibẹ. Ẹ fi orukọ Afọnja ṣe nnkan meremere, ki ẹ si tun eto oye Ilọrin ṣe, bi Fulani ba jẹ ọba tan, ki Yoruba naa jẹ. Bi ọba kan ba jẹ ni Ilọrin to ba ṣe eleyii, oun nikan lo gba awọn Yoruba to n pe ara wọn ni Fulani yii silẹ, bi bẹẹ kọ, bo ba jẹ bo ṣe n lọ yii lo n lọ, lọjọ ti wahala rẹ ba de, awọn Yoruba ti wọn n pe ara wọn ni Fulani yii yoo parẹ, yoo ku awọn ojulowo ọmọ Yoruba  ati awọn ọmọ Fulani to ti gba pe Yoruba lawọn, awọn yii gan-an ni yoo si jẹ ojulowo ọmọ ilu Ilọrin.

(114)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.