Ẹ sọ fun baba onirungbọn yẹukẹ Akurẹ ko gbe suuru jẹ

Spread the love

Inu Gomina Rotimi Akeredolu ko dun rara. Ko si sohun meji to n ṣe e ju pe awọn eeyan to fa kalẹ pe ki wọn di ipo oṣelu mu ni ipasẹ rẹ ko raaye kọja lọ. Awọn ti wọn wa nijọba l’Abuja, ati olori ẹgbẹ oṣelu wọn yẹgi mọ ọn lẹsẹ, wọn da a riboribo, gbogbo awọn to ti ro pe awọn ni wọn yoo di nnkan nla ni Abuja ko si le kọja sọhun-un, wọn da wọn jokoo si Akurẹ. Iyẹn lo fa ibinu rẹpẹtẹ, Akeredolu ko si fi ọrọ si abẹ ahọn sọ to fi ko ilaali buruku fun Adams Oshiomhole ti i ṣe olori ẹgbẹ wọn. O ni Oshisko lọkunrin naa, o ni ko mọṣẹ rara, ko si yẹ lẹni to yẹ ko di ipo olori ẹgbẹ oṣelu awọn mu. Loootọ si ni, giragira Oshiomhole paapaa pọ, niṣe lo n sare kiri bii ẹni pe ipo ti wọn gbe e si yii, ipo igbakeji Ọlọrun ni. Iru wọn yii lo maa n jẹ ki wọn pe awọn eeyan kukuru ni “Eeyan Kukuru Biliisi”, nitori bo ti n ṣe yii, yoo da ẹgbẹ APC ru ni. Gbogbo eeyan lo n ba ja, ọpọ ibi lo si jẹ ẹni ti ko ba ti fẹ ko wọle, tabi gomina ti ko ba fẹran, gbogbo ẹni ti ẹgbẹ ba mu yoo fidi-rẹmi ni, tabi ki wọn yi orukọ rẹ pada lati Abuja. Ẹgbẹ oṣelu to ba n ṣe bẹẹ, iya ni wọn n ko jẹ awọn aṣaaju ẹgbẹ wọn. Ṣugbọn Akeredolu ko le binu. Haa, haa, ko le binu o. Ọna ti oun naa gba wọle ni oun naa yoo maa ro, o ṣa gbọdọ maa ranti pe bi ko ba si awọn alagbara lati Abuja yii kan naa, oun naa ko le de ipo ti oun wa yii. Awọn alagbara Abuja lo gbe oun naa wọle, bi wọn ba si ṣetan lati lo agbara le e lori si i, afi ko ni suuru, ko gba kamu, bi bẹẹ kọ, yẹyẹ lawọn eeyan yoo maa fi i ṣe o. Ẹ sọ fun baba onirungbọn yẹukẹ Akurẹ pe ko gbe suuru jẹ.

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.