Ẹ mura si i, ara yin lẹ n ṣe

Spread the love

Ọlọrun o ni i jẹ ko pẹ ko too ye awọn ara Kogi. Aṣofin Dino Melaye waa kọ awọn ileewe kan si ipinlẹ naa lara owo ti wọn fun un nile-igbimọ pe ko fi ṣiṣẹ si agbegbe ẹ, o si ku dẹdẹ ko ṣi ileewe naa, awọn oloṣelu ko awọn tọọgi jọ, wọn si lọọ dana sun awọn yara ikawe ti wọn ti kọ pari, ti wọn ti kun lọda, to jẹ ki wọn kan ṣi i ni. Loju awọn oponu yii, wọn yoo ro pe Dino Melaye lawọn ṣe. Dino Melaye to jẹ owo to na yẹn ki i ṣe owo ẹ, owo to n gba nile-igbimọ aṣofin ni, owo awọn ara Kogi naa ni. Awọn aṣofin yii to jẹ nigba ti wọn ba ko iru owo yii fun wọn, wọn yoo ti ji kọja ilaji nibẹ, awọn mi-in yoo tilẹ ji i tan ni. Iwọnba diẹ ti Dino jaja ko silẹ fawọn eeyan rẹ, to fi kọ ileewe fun wọn, awọn oponu kan tun lọọ dana sun un. Ṣe Dino lo ṣọọti abi awọn ara Kogi. Tabi nijọ wo ni wọn ro pe eleyii to n ṣe gomina to sọ ara rẹ di aja ati agbẹnusọ Fulani yoo ranti ileewe kan fun wọn. Ẹni to jẹ owo oṣu to jẹ, ko san an, ti ko si bikita bi ara ṣe n ni awọn eeyan ni ipinlẹ rẹ nitori airowo oṣu gba, ṣe iyẹn ni yoo waa kọ ileewe fẹnikan. Ijọba kan n lọ, ijọba kan n bọ ni. Dino lo n ṣe sẹnetọ loni-in, ẹlomi-in ni yoo waa ṣe e lọla, ṣugbọn iwọnba ohun ti oloṣelu kan ba ṣe fun ilu, ti ilu ni laelae, nitori owo ẹ kọ lo fi ṣe e, owo araalu ni. Afi ki awọn araalu wa awọn ti wọn huwa aburu yii jade o, ki awọn ọlọmọ si kilọ fun ọmọ wọn, ki wọn ma fọwọ ara wọn ṣera wọn.

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.