Ẹ maa jẹ irẹsi ọfada, yoo ran ipese ounjẹ wa lọwọ—- Gomina Amosun

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti rọ gbogbo eeyan lorile-ede yii lati maa jẹ irẹsi ọfada, yatọ si tilẹ okeere, o ni rira ati jijẹ irẹsi ilẹ wa yoo ran ipese ounjẹ ni Naijiria lọwọ, yoo si tun ọrọ aje wa ṣe pẹlu.

Amosun sọrọ yii nibi eto ọlọdọọdun ti Yunifasiti Ọbafẹmi Awolọwọ maa n ṣe ti wọn pe ni ‘Festival of Food and Identity’ Iyẹn Ajọdun Ounjẹ ati Idanimọ wọn. Eyi ti ẹka to n ri si ẹkọ nipa aṣa ati iṣẹ ni fasiti naa ṣagbatẹru ẹ.

Gomina Amosun ṣalaye pe yatọ si pe jijẹ irẹsi ọfada yoo jẹ ki a ni anito ati aniṣẹku ounjẹ, yoo tun jẹ iwuri ati nnkan iyi fawọn agbẹ to n ṣọgbin rẹ, yoo si pawo wọle silẹ wa.

O fi kun un pe bi Naijiria ṣe gbe gbogbo ọna atirowo rẹ sori epo bẹntiroolu ko dara to, o ni bi a ba tun dari sọna nnkan ọgbin bii eyi, yoo ṣe wa lanfaani gidi.

Amosun tun ṣalaye pe yatọ si pe irẹsi ọfada dun lẹnu ju tawọn atọhunrinwa ti wọn ti di sapo tipẹ ki wọn too ko wọn debi lọ, o ni o tun daa fun ilera wa to bẹẹ to jẹ pe awọn dokita gan-an ti n polongo ẹ pe irẹsi ọfada lo daa ju fun jijẹ.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ naa, ọga agba Fasiti OAU, Ọjọgbọn Eyitọpẹ Ogunbọdẹde, ṣalaye pe yunifasiti yii n tiraka lati ma ṣe jẹ ki igbiyanju awọn to gbe e kalẹ ja sasan, nitori ẹ lawọn ṣe ṣagbakalẹ eto olounjẹ ibilẹ bii eyi, tawọn si n gbinyanju lati jẹ kawọn eeyan mọ pataki aṣa ilẹ adulawọ ati iṣẹ wa.

Awọn eeyan jankan-jankan lagbaaye ni wọn peju pesẹ sibi eto yii, lara wọn ni Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ati Aarẹ orilẹ-ede Rwanda, Paul Kagame, ti minista fun iṣẹ ọgbin ati nnkan amuṣọrọ ilu naa ṣoju fun.

 

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.