Ẹ ma sọ Tinubu d’Ọlọrun o, eeyan ni

Spread the love

Awọn ti wọn ba n ri jẹ labẹ ẹni kan ki i mọgba ti wọn yoo maa pe onitọhun ni orukọ ti ko jẹ, titi ti wọn yoo si fi ṣẹ Ọlọrun Ọba, wọn ko ni i mọ. Ọpọ awọn eeyan ti wọn ri ohun to ṣẹlẹ l’Ekoo lọsẹ to kọja ni wọn n pariwo pe Tinubu l’Ọlọrun Eko, aṣẹ to ba pa bẹẹ ni i ri, ohun to ba sọ bẹẹ ni yoo ṣẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọti oṣelu lo n pa awọn eeyan yii, ki i ṣe ọrọ gidi ni wọn si n sọ lẹnu. Loootọ ni Tinubu lagbara nidii oṣelu asiko yii, to si jẹ nilẹ Yoruba loni-in yii, ko si oloṣelu bii tirẹ, ṣugbọn iyẹn ko sọ ọ di Ọlọrun, nitori awọn kan naa ti lagbara nidii oṣelu yii nilẹ yii naa ri, wọn ti lo igba tiwọn, wọn si ti lọ. Igba ti Tinubu naa lo n lo yii, bo ba si ṣe lo o si, a o maa royin rẹ bo ba lọ tan. Ohun kan to mu Tinubu yatọ si awọn oloṣelu ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ ṣe gomina nilẹ Yoruba yii ni pe ẹran-bu-jẹ bu-danu ni, iyẹn awọn ti wọn n pe ni jẹ-ki-n-jẹ, tabi jẹun-soke! Tinubu mọ bi wọn ti n fi owo abu ṣe abu lalejo, bi owo awọn araalu ba bọ si apo Tinubu, yoo mọ bi yoo ti fun awọn diẹ ni diẹ ninu owo naa, awọn yii yoo si maa pariwo, “Aṣiwaju ṣeeyan, Aṣiwaju ṣeeyan,” iru awọn yii naa ni wọn si n mura lati sọ ọkunrin naa di Ọlọrun. Bo ba jẹ eto oṣelu ri bo ti yẹ ko ri, yoo ṣoro ki iru Tinubu too di ẹni-bii-Ọlọrun lọdọ awọn oloṣelu, nitori owo ilu ko ni i ṣee ji ko, owo ilu yoo wa lọdọ awọn araalu, awọn araalu naa yoo si mọ pe owo awọn ni. Ko sẹni kan ti i ṣiṣẹ ti i ri owo ti yoo na an bi awọn oloṣelu ti n nawo, igba ti oloṣelu ba ri owo ilu ji ko naa ni wọn n na an bo ba ṣe wu wọn, nigba to ṣe pe owo ọfẹ ni. Awọn ti wọn ṣeto idibo Eko ti wọn fi yọ Ambọde, ko si ohun meji ti wọn ni Ambọde ṣe ju pe o di ọna ounjẹ awọn mọ awọn lọ. Ọna ounjẹ yii, awọn ọna ti Tinubu ti la silẹ fun awọn ọmọ ẹyin rẹ lati maa fi ri owo ilu gba ni, koda, nigba ti wọn ko ṣe iṣẹ gidi kankan fun ilu rara. Bi wọn ti ṣe e ni pe wọn yoo gbe iṣẹ awuruju kan ti ko lori ti ko nidii kalẹ, wọn yoo si ni ki ẹni to ba jẹ gomina maa sanwo fun awọn ti wọn ba pe ni ọga iṣẹ naa. Awọn ti wọn ba pe ni ọga iṣẹ yii, awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin oloṣelu nla bii Tinubu ni. Ohun to ṣẹlẹ l’Ekoo niyẹn. Gbogbo awọn aṣaaju ẹgbẹ APC Eko ti wọn bẹwu silẹ ti wọn gbe apẹrẹ wọ yii, awọn ti wọn ko ri owo awuruju ti wọn n gba lai ṣiṣẹ gidi kan fun ilu gba mọ ni. Iyẹn ni ẹnu wọn ṣe ko, ti wọn si le yọ gomina naa kuro nipo. Ki i ṣe oogun, bẹẹ ni ki i ṣe agbara kan, owo ti wọn n ri lo pa gbogbo wọn pọ, bi ko ba si owo naa mọ, abuṣebuṣe niyẹn. Bi ẹgbẹ oṣelu mi-in ba de ti wọn ba ri Eko gba lọwọ Tinubu lọla, nigba naa ni aye yoo ri i pe ki i ṣe pe ọbọ mọ ara rẹpẹtẹ kan i da lori igi, nitori pe igi sun mọ igi lasan ni. Nitori ẹ ni ẹnikan ko ṣe gbọdọ fi Tinubu we Ọlọrun, oloṣelu ni, saa tirẹ la wa yii, owo Eko wa lọwọ rẹ, owo lo si sọ ọ di alagbara. Bi owo Eko ko ba si lọwọ ẹ mọ, aye yoo ri i pe ko si alagbara kan nibi kan. Ẹbẹ naa la o si maa bẹ wọn, pe ki wọn fi owo Eko tun Eko ṣe o, ki owo naa ma parẹ si apo awọn olori ẹgbẹ oṣelu lasan.  

 

(46)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.