Ẹ ma jẹ kawọn awakusa ipinlẹ Zamfara ya wọ Ọṣun o, Oyetola Pariwo!

Spread the love

Latari bi ijọba ipinlẹ Zamfara ṣe fi ofin de awọn a-ji-kusa-wa (illegal minners), ti wọn si le wọn jade kuro nibẹ, Gomina Oyetọla ti ke si gbogbo awọn oṣiṣẹ alaabo lati jigiri si iṣẹ wọn, ki awọn ọbayejẹ yii ma baa ya wọ ipinlẹ Ọṣun.

 

Bakan naa ni gomina ke si awọn ori-ade lati jẹ ori lalakan fi i ṣọri lori ọrọ naa lagbegbe kọọkan ti wọn wa, nitori pe lẹyin ipinlẹ Zamfara, o da bii ẹni pe ipinlẹ Ọṣun ni ẹlẹdaa tun fi awọn nnkan alumọọni jinki ju lorileede yii.

 

Nibi ti ọrọ naa ka gomina lara de, o pe ipade awọn ti wọn ni i ṣe pẹlu eto aabo nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ lawọn lọbalọba labẹ alaga wọn, Ọọni ti ilu Ileefẹ, Ọba Babatunde Ẹnitan Ogunwusi, naa ko gbẹyin nibẹ rara.

 

Nibi ipade naa ni Oyetọla ti ṣalaye pe ipa buburu ni wiwa kusa lawọn ibi tijọba ko fọwọ si maa n ko, o maa n fa ilẹ-riri, bẹẹ ni nnkan oko to jẹ orisun ounjẹ fun araalu ko ni i jade bo ṣe yẹ.

 

O rọ awọn ori-ade lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba, ki iwa buburu naa le rokun igbagbe nipinlẹ Ọṣun, nitori pe lai si amọsi awọn ọba, ijọba nigbagbọ pe awọn ajikusa wa ọhun ko lee rọwọ mu.

 

Bakan naa ni gomina rọ awọn lanlọọdu, paapaa, lawọn igberiko gbogbo nipinlẹ Ọṣun lati mọ iru awọn eeyan ti wọn ba fẹẹ maa gba sile lasiko ti wọn ti ya kuro nipinlẹ Zamfara bayii.

 

O ni ki i ṣe ijọba nikan ni yoo fara gba ninu laasigbo to ba ti ẹyin ọrọ naa jade, awọn lanlọọdu ti wọn ba gba awọn ọdaran naa sile paapaa ko ni i ṣalai pin ninu wahala to ba tidi rẹ yọ.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘ni bayii ti ọrọ owo to n wa lati idi epo bẹntiroolu ko ti ṣe e gbọkanle mọ, ohunkohun ti ipinlẹ kọọkan ba ni gẹgẹ bii nnkan alumọọni lo gbọdọ mojuto daadaa, ko ma baa di eyi ti awọn ọdaran naa yoo maa ṣe bo ṣe wu wọn.’

 

O ni ipinnu ijọba oun ni lati mu aye rọrun fun gbogbo araalu, idi niyi toun fi n gbaruku ti iṣẹ agbẹ, toun si fi mu ọrọ aabo lọkun-un-kundun, o waa ku si awọn agbofinro lọwọ lati kun ijọba oun lọwọ lori bi alaafia yoo ṣe tubọ maa jọba kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

 

Lara awọn ti wọn wa nibi ipade naa ni kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Arabinrin Abiọdun Ige, adari ajọ ọtẹlẹmuyẹ l’Ọṣun, Ọgbẹni Brown Ekwoaba, adari ajọ to n gbogun ti egboogi oloro nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Samuel Egbeola ‎ati adele ọga agba ajọ to n ri si iwọlewọde awọn ajeji, Ibong Osato Aideyan.

 

Ninu ọrọ idaniloju rẹ, Ọba Ogunwusi ṣeleri lorukọ gbogbo awọn ori-ade lati daabo bo agbegbe wọn, ki alaafia pupọ le wa nipinlẹ Ọṣun.

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.