Ẹ ma dan raurau kankan wo l’Ekiti o

Spread the love

Ibo Ekiti ti n sun mọ, bi ibo ba si ti n sun mọ bayii, oriṣiiriṣii nnkan lẹ o maa gbọ.  Awọn INEC, iyẹn awọn ti wọn fẹẹ fun wọn niwe idibo ti wa l’Ekiti, ṣugbọn alaye ti ọpọ awọn araalu n ṣe bayii ni pe awọn oṣiṣẹ naa ko fun awọn ni kaadi idibo, wọn ko jẹ ki awọn ri i gba. Wọn ni bi awọn mi-in ti n beere owo, lo jẹ awọn mi-in ti ni iwe ti wọn ti kọ orukọ awọn eeyan si wa, iwe yii ni wọn n tẹlẹ lati fi tọju kaadi idibo naa fun awọn ti orukọ wọn ti wa lọwọ wọn. Ohun to n ṣẹlẹ ni pe awọn oloṣelu ti gbe iṣe wọn de ni, bi ẹ ba ti ri iru awọn iwa palapala bayii, kẹ ẹ ti mọ pe o lọwọ oloṣelu ninu. Ijọba tabi awọn ọga INEC ko sọ pe ki oṣiṣẹ wọn kankan gba owo lọwọ wọn, bẹẹ ni wọn ko sọ pe ki wọn maa fi orukọ ẹnikẹni silẹ, ṣugbọn awọn oloṣelu ni yoo ko owo fun awọn oṣiṣẹ yii, ti wọn yoo ni orukọ awọn kan lawọn fẹ, ti wọn yoo si gba kaadi rẹpẹtẹ lọwọ wọn. Ko si ohun ti wọn fẹẹ fi i ṣe ju lati fi ṣe eru lọ. Awọn eeyan gidi ti wọn fẹẹ dibo, ti wọn si ti pinnu lati yan ẹni to wu wọn ko ni i ri kaadi idibo, bi wọn ko ba si ti ni kaadi idibo, ko si ohun ti wọn le ṣe, ohun tawọn oloṣelu ba fẹ ni yoo ṣẹ, bo tilẹ jẹ pe ipalara ni iru nnkan bẹẹ n mu wa. Ki i ṣe gbogbo awọn oṣiṣẹ INEC ni onijẹkujẹ tabi oniwakiwa, awọn tawọn oloṣelu ti fowo lu lọwọ ninu wọn ni wọn n ba nnkan jẹ. Amọ ki awọn ọga INEC, ati awọn alaṣẹ ilu gbogbo jade, ki wọn ri i pe awọn eeyan ri kaadi gba, ki wọn ri i pe ko sẹni to fẹ iwe idibo to lọ lọwọ ofo. Eleyii ko pọ ju ohun ti ijọba le ba wọn da si lọ, awọn ẹgbẹ alaaanu oriṣiiriṣii naa si le dide, ti wọn yoo maa kiri ibi igbakaadi kan si ekeji, ki wọn le ri ohun to n lọ. Nibi ti wọn ba ti ri i pe aiṣedeede wa, ki wọn tete pariwo saraalu leti, ko too di pe wọn ba nnkan jẹ fun wọn. Ẹ kilọ fun awọn oṣiṣẹ INEC ẹlẹgun-un-jẹ, pe ki wọn ma dan palapala wo l’Ekiti, ki wọn ma fi ori gbe ohun ti ki i ṣe tiwọn.

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.