Ẹ ma ṣe bẹẹ yẹn, ko daa

Spread the love

Awọn eeyan kan ko niṣẹ. Ki i ṣe pe wọn ko niṣẹ nikan ni, wọn ko tun ni laakaye. Ṣe bi eeyan o ba niṣẹ, to ba wa nile rẹ to ba n jẹun, tabi to ba wa ọna ti yoo fi ri iṣẹ gidi ṣe, ko si ki nnkan rẹ ko ma daa, ohun ti ko dara yoo si ṣẹku. Ṣugbọn awọn kan wa to jẹ laye wọn ti wọn wa yii, ọmọọta, iwa were, iwa ọmọ pami-n-ku lo wa lọwọ wọn, oun naa ni wọn yoo si maa hu titi ti iku buruku, ikuugbona yoo fi ka wọn mọbẹ. Ẹni to fẹẹ du ipo gomina PDP l’Ekoo, Jimi Agbaje, lo ke sita pe niṣe ni awọn kan n lọọ ti bọọdu, iyẹn patako ipolongo nla, ti awọn n lẹ kaakiri wo, ti wọn si n ya fọto oun ati gbogbo iwe ti oun lẹ mọta ya. O fi fidio awọn ibi ti wọn ti n ṣe aburu naa fun un han. Ohun to ya awọn eeyan lẹnu ni pe patako ipolongo tirẹ nikan ni wọn n bajẹ, bọọdu yii ni wọn n bajẹ, posita tirẹ to lẹ ni wọn n fa ya, ti Sanwoolu ti yoo dije lorukọ APC wa kaakiri horo ati ibi to tọ ati ibi ti ko tọ, awọn oniranu yii ko ya wọn. Nigba ti a ba fẹẹ dibo bayii, gbogbo ẹni to ba ni awọn fẹẹ du ipo kan ni wọn lẹtọọ lati polowo ara wọn, ohun to n mu ki eto idibo labẹ ijọba dẹmokiresi dun niyẹn. Ẹni ti yoo wọle yoo polowo ara rẹ, ẹni ti ko ni i wọle yoo polowo ara rẹ. Ẹni to mọ ohun to n ṣe yoo polowo ara rẹ, ẹni ti ko mọ ohun to n ṣe yoo polowo ara rẹ, ẹni ti gbogbo ilu mọ pe ọlọgbọn ni yoo polowo ara rẹ, ẹni ti wọn si tun mọ pe omugọ hanran-un ni naa yoo polowo ara rẹ. Ko si ohun to buru ninu gbogbo iyẹn ara. Anfaani wa fawọn araalu lati yan ẹni to ba wu wọn lọkan ara wọn ni. Ko si si pe awọn ko mọ lagbaja tabi awọn ko gbọ orukọ tamẹdo, kaluku to fẹẹ du ipo ni wọn yoo ri, funra wọn ni wọn yoo si mọ ẹni to ba yẹ ko ṣe olori ijọba adugbo wọn. Nibi ti ẹ ba ti waa ri i ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan ba n lọọ ya posita tabi ba ipolongo awọn ẹgbẹ mi-in jẹ, iru ẹgbẹ bẹẹ ki i ṣe ẹgbẹ to nigbagbọ ninu ara rẹ, ẹgbẹ to ro pe oun ko le wọle ti oun ko ba ṣe ojooro tabi lo agbara ijọba nilokulo ni. APC ti kọja iyẹn, paapaa l’Ekoo yii, ko sẹni ti ko mọ wọn, bi ko ba si jẹ wọn ṣe aṣeju, ko sẹni to le gba ipinlẹ naa kuro lọwọ wọn, nitori agbara to wa lọwọ wọn. Ki waa ni ijaya, ki waa lo de to jẹ awọn ni wọn yoo ba nidii iwa ọbayejẹ, omugọ ati tọọgi bayii. Ki lo de ti ẹgbẹ APC yoo maa fi tọọgi ati awọn ọmọọta ṣeto idibo. Ṣe awọn ọga wọn lo ran wọn ni abi awọn ọmọọta kan lo n ṣe oṣi bayii kiri ni. Ẹyin aṣaaju APC l’Ekoo, ẹ ba awọn tọọgi wọnyi sọrọ, nitori wọn kan fẹẹ ba orukọ ẹgbẹ yin jẹ ni.

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.