Ẹ ma ṣe ṣọdun gbagbe Leah Sharibu-Biṣọọbu Badejọ

Spread the love

Biṣọọbu agba fun ijọ Aguda, ẹkun ti Ọyọ, Rẹfurẹndi Emmanuel Adetoyose Badejọ, ti ke si awọn alaṣẹ lorileede yii lati ma ṣe gbagbe ọmọbinrin to wa nigbekun ikọ Boko Haram nni, Leah Sharibu.

O sọrọ naa lasiko ikini ku ọdun to ṣe lagbegbe Oke-Ogun ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ. Badejọ sọ pe bi ọmọbinrin naa ṣi ṣe wa nigbekun yẹ ko jẹ nnkan ibanujẹ fun awọn ọmọ Naijiria, ṣugbọn dipo bẹẹ, niṣe ni awọn oloṣelu wa gbaju mọ idibo ọdun yii.

Bi wọn yoo ṣe jawe olubori ninu eto idibo ọdun to n bọ lo jẹ wọn logun.

O waa rọ awọn ijọba lẹka mẹtẹẹta lati ma ṣe fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ eto aabo, o si lo akoko naa lati gbadura fun alaafia orileede yii ati fun eto idibo to n bọ.

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.