E lo Awolowo Awon oba wa ati ipo asaaju ile Yoruba

Spread the love

Mo ri awon atejise ti e sare te si mi ni Sannde lori oro ibo ti won di lOsun lose to koja, sugbon n ko ti i fee wi kinni kan, mo fe ki won yanju ibo naa ka to jo gbe oro ibe wo lose to n bo, nitori bi alaboyun ba n bimo re lowo, eeyan ki i wo iwa alaboyun ko ba ibi ojo ikunle mu un, o digba to ba bimo. Nnkan ti n sele ko daa, awon to n se e mo pe ko daa, sugbon ibi ti a ba ara wa de naa la n ri yii, bi a se n fowo ara wa se nnkan ara wa naa la n ri yii, nitori ireje ko si ninu foto, bi eeyan ba se jokoo ni yoo ba ara re, iru igi ti a ba fi sina ni eefin ti yoo jade fun wa. Iyen ni inu mi ko se dun nigba ti ore mi kan so pe Yoruba ko ni i ni asaaju laelae, koda ki n pariwo lati oni di ola. Inu mi ko le dun, nitori mo saa n so o, mo si n wi, bi ilu kan ba wa ti ko ni asaaju, bi iran kan wa wa ti ko leni ti won n tele tabi gboro si lenu, ofo lasan ni.

Loni-in yii, oba wa niluu oyinbo, ni England, koda oba obinrin ni. Bi agbara awon oloselu ibe si se po to, won ki i de odo oba won. Ki won too bere ijoba, oba ni yoo fun won lase, bi won ba si pari ijoba won naa tan, oba naa ni won yoo gbe e fun. Idi ni pe oba lo nile, nitori awon oba yii ni won n sejoba orile-ede won ki awon oloselu too de. Nigba ti awon oloselu de, ti won fee gba agbara lowo awon ti won nile yii, oro naa dija laarin won, sugbon nigba ti won fa a lo ti won fa a bo, won pada sori pe oba lo nile, oun ni yoo si maa pase lori ile re lo. Sugbon yoo fun awon oloselu laaye lati maa sejoba tiwon lo, ti ko si ni i di won lowo tabi da si oro won. Idi niyi to se pe oba to ba je niluu oyinbo yi ki i se oselu, koda lati kekere ti won ba ti mo pe iru eni bee le di oba lojo iwaju ni won yoo ti so pe ko le se oselu, ko si le da soro won.

Awon ore mi kan maa n so kinni kan, iyen awon mi-in ti a jo je egbe, ti won si tun je omowe ati ojogbon. Ohun ti won maa n wi ni pe a ko le fi ilu oyinbo we ile tiwa nibi, nitori gbogbo ohun ti a n ba koja yii, awon oyinbo naa ti ba ibe koja ri, pe a ko le fi ijoba demokiresi ati ohun ti won n se lAmerika we ti Naijiria wa nibi, nitori o ti le ni ogorun-un meji odun ti won ti n ba kinni naa bo, gbogbo ohun to si n sele si wa loni-in yii ti sele si awon naa daadaa. Won aa ni awa naa yoo ni suuru ni. Ohun ti mo maa n beere ni pe odun wo ni a oo ni suuru da? Ohun to sele si won lAmerika tabi ni London nigba ti oju won dudu ko ye ko sele si awa mo. Idi ti ko fi ye ko sele ni pe opo nnkan to sele si won yii ni won ko sinu iwe, awon ti won si le kawe ri idi ti tiwon fi sele, won si ri asise ti awon eeyan igba naa se.

Opolopo nnkan ni won ti ko nipa awon oba to se oselu laye ijosi laarin won, ati awon ohun to sele si awon oba bee, ohun ti eni to ba fee kogbon yoo kan se ni lati ka awon iwe yii, ati awon itan wonyi, yoo si le mo ohun ti oun yoo se ti tire ko fi ni i pada ri bee mo. Ni aye atijo, ileele ni a  n jokoo si, nitori a ko ti i ja ogbon aga, sugbon nigba ti aga ti de, to je orisiirisii re lo wa, eni meloo ni yoo wa fi aga sile ti yoo jokoo sileele, tabi ti yoo ni ka duro ki eko aga lilo ye wa daadaa. Nigba ti a ti le maa lo foonu, ti a n wo telifisan, ti a n kawe, ti a n se orisiirisii ohun tawon oyinbo asiko yii n se, ko si ohun to fa a ti a ko le huwa ti won n hu naa, paapaa awon iwa to mu ogbon dani, to si maa n mu alaafia wa laarin won. Olori iwa ti oyinbo n hu ti won si fi yato si wa gedengbe ko ju pe won n tele ofin won lo. Ofin ti won ba se, ko seni kan to gbodo ru u, won ko si ni i tori eni kan ru u.

Awon oyinbo ni won ti koko bere si i fi awon oba wa wole, sugbon ki i se awon oyinbo naa lo fa a, awon oba wa funra won ni. Boya o see se ko je ti ko ba si ija to wa laarin awon omo oba Eko meji, Akitoye ati Kosoko, boya ni oyinbo iba waa sejoba le wa lori ni Naijiria. Ki i se pe won ko ni i wa si Naijiria, sugbon o see se ko je bii onisowo meji ni a oo maa se. Sugbon Kosoko n ba aburo baba re ja nitori ipo oba, nigbeyin, o le Akitoye kuro niluu nitori agbara re. Akitoye lo be awon oyinbo pe ki won ba oun gba ilu oun pada lowo Kosoko, ki oro si le dun, o so fun won pe ise owo-eru ni Kosoko n se ju, asiko naa si lawon oyinbo ko fe owo-eru mo. Sebi ohun to je ki oyinbo ti won n pe ni Beecroft ko awon soja sodi lojo Keresi odun 1851 niyen, nigba ti yoo si fi di ojo odun tuntun, won ti gba ilu Eko fun Akitoye.

Won gba ilu Eko tan, won ni awon yoo duro ti Akitoye nitori ki Kosoko ma le pada wa, Akitoye ni oun fara mo on be, nitori eru Kosoko n ba oun naa. Awon oyinbo ni yoo towo bo iwe adehun ni o, yoo gba pe awon yoo maa sejoba nibe, yoo gba pe oun ko ni i se owo eru mo, pelu awon ofin orisiirisii mi-in. Sebi ojo naa ni awon oyinbo wo ilu Eko wa, nibe  ni won si ba wo Naijiria, ti won si gba ase pipa kuro lowo awon oba. Oro naa le debii pe nigba ti Akitoye ku, ki awon ijoye ti mo ohun ti won yoo se, ki awon afobaje paapaa too gbo, oyinbo ajele igba naa ti fi Dosumu sipo oba, o si je oba naa gbe pata. Lati iba naa lo ti je pe awon oyinbo yii ni won n pase fawon oba wa, ohun ti won si n pe ni ijoba gan-an niyen. Won gba agbara ijoba lowo won, won si n fi agbara naa pase, ko si si ohun ti oba kan le se.

Ohun ti won se fun Eko yii naa ni won se yika gbogbo Naijiria pata. Alagbara nla kan ni Ijebu laye igba naa, sugbon awon oyinbo yii fi nnkan kan kewo, won si loo ko ogun ja ilu Ijebu, ogun naa le debii pe won dana sun ilu naa, won si fi oba won si igbekun, leyin ti oba ti gba lati maa se tiwon ni won too je ki ilu naa tun bere si i kun pada. Tabi ti awon oyinbo ajele ti won daamu Alaafin la fee so ni, sebi won ki ori oun naa mo abe won ni. Ni gbogbo akoko yii ni agbara bo lowo awon oba, won ko si ni ase kan lenu ju eyi ti oyinbo igba naa ba pa lo. Ohun to waa fa wahala fun wa titi doni ni pe nigba ti awon oyinbo lo, awon oloselu ti won gbajoba naa ki ori awon oba mo abe ni. Tabi boya ki i se awon ni won ko ori won mo abe, boya awon oba wonyi funra won ni won ki ori ara won mo abe awon oloselu nitori lati ri nnkan gba lowo won.

Boya ni oba kan wa nile Yoruba ni aarin odun 1950 si 1966 ti ko si ninu egbe oselu kan tabi omi-in, tabi ti ko se aatileyin fun won. Oro naa si dara laarin won pupo nigba naa debii pe won n fi awon oba yii se minisita, oba si n je aye ti awon oloselu naa n je, agaga eyi to ba mowe die ninu won. Sugbon kinni kan wa ti won ko kiyesi nigba naa, iyen naa ni pe nigba ti enikeni ba ti n se oselu, o di dandan ko foribale fun eni to ba je olori egbe won. Eleyii lo fa a to je gbogbo awon oba naa pata, o loju eyi to je babara kan loju Awolowo, nitori oun ni olori egbe, ase to ba si pa, ko si oba to gbodo yi i. Bo se ri nile Hausa naa niyen o, bee naa lo si ri ni ile Ibo. Sugbon ki i se pe won fi tipatipa ko awon oba yii sinu oselu o, oba ti ko ba se ko se naa niyen, won o le mu un nipa pe dandan ni ko se oselu, ohun to le faja ko ju ko wa leyin egbe kan, ko si maa se atako fun egbe mi-in.

Oro naa dara laarin won gan-an nigba ti ko si ija laarin awon oloselu yii, amo lojo ti ija Awolowo ati Akintola ti bere nitori oro oselu, lojo naa ni awon oba ile Yoruba ti di yepere, ti ko si ase tabi agbara kan lowo won mo. Bawo leleyii se ri bee? A oo maa so o lo lose to n bo.

(58)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.