Ẹ kuku yanju Dino Melaye lẹẹkan

Spread the love

Awọn ọlọpaa lo lọọ gbe Dino Melaye tẹlẹ, ti wọn duro nile ẹ fun odidi ọsẹ kan ki wọn too ri i mu. Wọn lara ẹ ko ya, wọn ru u lọ si ọsibitu, ọsibitu lo si wa ti awọn DSS fi lọọ gbe e, wọn sa a sinu oorun nita gbangba, wọn si jẹ kawọn to n lọ to n bọ maa ya fọto rẹ. Awọn DSS tun gbe e kuro lọdọ tiwọn, wọn gbe e lọ si ọdọ awọn SARS, boya o digunjale ni ko ye ẹnikan. O daju pe ki i ṣe ẹsun pe wọn yinbọn ni Kogi ni wọn n tori rẹ daamu ọkunrin yii mọ, ẹsun pe wọn ho le Buhari lori lọjọ to lọ sile-igbimọ aṣofin ni. Ohun ta a n sọ niyẹn pe ijọba yii ti di oloju-ba-n-dẹru-bọmọ, ti ko sẹni to gbọdọ gbin pẹnkẹn mọ. Bẹni kan ba sọrọ, wọn aa gbe e ni, wọn aa ka ẹsun buruku si i lọrun ti ko ni i bọ ninu ẹ kia. Bi Dino Melaye ba ṣe ohun ti ko daa, ẹ gbe e lọ sile-ẹjọ ki adajọ si dajọ rẹ, bo ba jẹ ẹwọn lo tọ si i ki wọn tete ju u sibẹ. Tabi kin ni wọn n gbe e kiri ọdọ DSS, SARS atawọn ọlọpaa fun bii ọsẹ meji si bayii. Bo ba si jẹ wọn fẹẹ pa a naa ni, ki lo de ti wọn ko yanju rẹ lẹẹkan, ki wọn yee fi ariwo di araalu lọwọ, ohun ti kaluku ba kuku ṣe loni-in, ọrọ itan naa ni yoo da lọla. Ẹyin oniranu, ẹ bara yin sọhun-un jare.

 

 

 

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.