“Ẹ juko fun un, ọmọ ajẹ Wọja, ẹ juko fun un!”

Spread the love

Apani o ni i fẹ ki wọn mu ida kọja niwaju oun, ẹni to ba si n fibọn paayan, bo ba ri ọpa lasan ti wọn gbe kọja nitosi ẹ, ariwo ni yoo pa pe ki wọn ma gbe iru irin bẹẹ kọja lẹgbẹẹ oun. Bi ọrọ ti ri niyi fun awọn ọmọ ẹgbẹ NPC, ẹgbẹ awọn Sardauna Ahmadu Bello, ni 1964, lasiko ti rogbodiyan buruku n lọ ni Western Region, ilẹ Yoruba. Ẹgbẹ Dẹmọ, NNDP, iyẹn ẹgbẹ awọn Oloye Ladoke Akintọla lo gbooro, ẹgbẹ naa fi dandan le  e pe awọn yoo gba ilẹ Yoruba pata kuro lọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu meji to ku, iyẹn ẹgbẹ Action Group, AG ti wọn tun n pe ni ẹgbẹ Ọlọpẹ, ati ẹgbẹ NCNC, ti wọn n pe ni ẹgbẹ Alakukọ. Ẹgbẹ Ọlọwọ lawọn NNDP n jẹ ni tiwọn, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ Dẹmọ lo mọ wọn lori. Ẹgbẹ awọn Akintọla ni, ẹgbẹ naa lo si n ṣejọba West, gbogbo agbara pata lo wa lọwọ wọn. Akintọla ni olori ijọba, Fani-Kayọde si ni igbakeji rẹ.

Ṣugbọn awọn araalu ko fẹran ẹgbẹ naa nitori ọna ti wọn fi gba di olori ijọba. Ẹgbẹ Action Group, ẹgbẹ Ọlọpẹ ni gbogbo wọn pata wa tẹlẹ, awọn ti ko si si ninu ẹgbẹ Ọlọpẹ wa ninu ẹgbẹ NCNC. Ija lo de laarin Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ti i ṣe olori ẹgbẹ Ọlọpẹ ati igbakeji rẹ, Ladoke Akintọla, ija naa si le debii pe wọn pada sọ Awolọwọ sẹwọn, nitori awọn ọta Awolọwọ lati ilẹ Hausa, iyẹn awọn Ahmadu Bello, ti wọn ti n wa ọna lati fi mu Awolọwọ tẹlẹ gbe lẹyin igbakeji rẹ lati mu un, wọn si ronu ọna ti wọn le fi yọwọ rẹ kuro nidii oṣelu to n lọ nigba naa, wọn ko ri i, ni wọn ba ṣeto lati ju u sẹwọn. Ni gbogbo igba ti ija ṣi n le ni West ni 1964 yii, ẹwọn ni Awolọwọ wa, ohun to si jẹ ki ija naa kan awọn araalu niyẹn. Awọn n binu pe Akintọla atawọn ti wọn n tẹle e dalẹ Awolọwọ ni, nitori ẹ ni wọn ṣe koriira ẹgbẹ wọn, ti wọn ko si fẹẹ ba wọn ṣe.

Akintọla naa mọ, Fani-Kayọde ti i ṣe igbakeji rẹ naa si mọ, nitori rẹ ni wọn ṣe n lo agbara ijọba, ti wọn si ko ọpọlọpọ awọn ọmọ tọọgi jọ lati maa ba awọn oloṣelu ti ko ba fẹ tiwọn ja, ati araalu to ba n gbo wọn lẹnu. Bi wọn ṣe n lo tọọgi ni wọn n lo awọn ọlọpaa, nitori awọn ọlọpaa ijọba ibilẹ ti wọn n lo nigba naa, tiwọn ni wọn n ṣe. Igba ti ariwo pọ ni ijọba apapọ ko awọn ọlọpaa mi-in wa si ilẹ Yoruba, awọn ọlọpaa yii ko si gbọrọ si awọn Akintọla lẹnu, wọn n mu awọn tọọgi wọn, wọn n sọ wọn sẹwọn, eleyii ko si dun mọ awọn Akintọla ninu, paapaa Fani-Kayọde to jẹ pe oun gan-an lo ni tọọgi to pọ ju ninu awọn oloṣelu West igba naa, ni gbogbo ibi to ba n lọ ni wọn yoo fi mọto meji tabi mẹta ru tọọgi tẹle e. Amọ pẹlu ẹ naa, ko si bi wọn yoo ti ṣe e ti wọn ki i kojangbọn lọdọ awọn eeyan ilu, nitori wọn koriira ẹgbẹ wọn.

Igba ti awọn ọlọpaa lu ọkan ninu awọn tọọgi Fani-Kayọde to n ba wọn ṣe agidi lọna Ibadan pa, ti adajọ ti ijọba West gbe dide si da Fani lare pe ko si oloṣelu gidi kan to wa ni Western Region nigba naa ti ko ni i ni ohun ija oloro atawọn tọọgi tirẹ, lawọn oloṣelu ẹgbẹ AG naa ba jade, awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin Awolọwọ, wọn ni kawọn ọlọpaa bẹrẹ si i fawọn nibọn. Wọn lawọn fẹẹ gba iwe aṣẹ, awọn fẹẹ gba pamiiti lati maa gbe ibọn kiri, nigba ti adajọ awọn Akintọla ti le sọ pe ko si oloṣelu gidi kan ti yoo wa ni West ti ko ni i ni awọn tọọgi tirẹ ati awọn ohun ija gidi ti yoo maa ko rin kaakiri. Awọn ọmọlẹyin Awolọwọ ninu ẹgbẹ AG yii ni awọn mọ pe ẹmi awọn ko de, nitori awọn tọọgi Ẹgbẹ Dẹmọ, ṣugbọn eyi ti ọkunrin adajọ ijọba West tun waa sọ yii fihan pe bi awọn ba jafara, iku yoo pa gbogbo awọn nikọọkan.

Ọrọ yii lo ba awọn ẹgbẹ NPC lẹru, awọn ẹgbẹ Sardauna sare jade, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn wa nilẹ Yoruba. Ọdọ ọga ọlọpaa ni wọn lọ taara, wọn si tun gbe odidi iwe kan jade. Wọn ni ki olori ọlọpaa naa jare ko jọwọ, ẹbẹ kan lawọn fẹẹ bẹ ẹ o, ẹbẹ naa si ni ko ma fun awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu AG kankan niwee-aṣẹ, ko ma fun wọn ni pamiiti pe ki wọn maa gbe ibọn rin, bo ba ṣe bẹẹ, awọn ọmọ ẹgbẹ naa yoo kan maa fi kinni naa paayan lọ rẹkẹrẹkẹ ni o. Wọn ni awọn ko mọ ohun ti awọn eeyan naa fẹẹ fi ibọn ṣe, nigba ti wọn ki i ṣe ọlọpaa, ti wọn ki i ṣe ṣọja, ti ki i si i ṣe pe wọn fẹẹ di ogboju-ọdẹ-ninu-igbo-irunmalẹ, ọkunrin to n fibọn pẹran kaakiri. Wọn ni awọn mọ pe bi ọwọ wọn ba tẹ ibọn ti wọn n beere fun yii, awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ, ati awọn ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ NPC, ni wọn yoo doju ibọn naa kọ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ NPC yii ni awọn ọmọlẹyin Awolọwọ koriira awọn, wọn si koriira gbogbo awọn ti wọn n ba awọn ṣe, wọn si mọ pe ko si alajọṣe gidi kan ti awọn ni ni West bayii ju ẹgbẹ Dẹmọ ti i ṣe ẹgbẹ awọn Akintọla lọ, bi ọwọ wọn ba waa tẹ ibọn ti wọn n beere fun yii, oku yoo sun, bẹẹ awọn ko ni ibọn kankan lọwọ ni tawọn, Ọlọrun nikan lawọn gbojule. Malam Lawal Isa to gbe iwe jade lorukọ ẹgbẹ NPC ni ki wọn beere lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ Awolọwọ ohun ti wọn fẹẹ fibọn ṣe, o lo da oun loju pe ki i ṣe pe wọn fẹẹ fi daabo bo ara wọn, wọn fẹẹ maa fi pa awọn ọta wọn ni. Bẹẹ ni wọn ko ni ọta meji to ju awọn ọmọ ẹgbẹ Demọ ati NPC lọ, igbagbọ wọn si ni pe bi awọn ba fibọn pa wọn tan, ẹgbẹ wọn yoo le wọle ibo ti awọn fẹẹ di yii, wọn ko si bẹru Ọlọrun pe ohun ti awọn fẹẹ ṣe yii, ọmọ eṣu nikan lo le ṣe bẹẹ.

Amọ ibinu ni awọn ọmọ ẹgbẹ Awolọwọ fi dahun. Oloye Sunday Ọrẹdehin to jẹ ọkan ninu awọn Baameto ẹgbẹ Ọlọpẹ lo sọrọ, oun lo pa owe Yoruba fun wọn pe ọmọ to ba n san ọbẹ sun, to tun n fi apo rọri, to si n ṣe oogun okigbẹ kaakiri, iwa rẹ lo n ba a lẹru. O ni ohun ti awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ n ṣe, paapaa awọn aṣaaju wọn, iyẹn lo n ba wọn lẹru, ti wọn fi n rojọ eke kiri. O ni gbogbo aye lo mọ pe ko si tọọgi nidii oṣelu awọn ni West tẹlẹ, awọn Akintọla ati Fani-Kayọde lo ko kinni naa de nigba ti wọn ti da ẹgbẹ Dẹmọ silẹ, awọn ni wọn n lo tọọgi ti wọn fi n dẹruba awọn eeyan, ti wọn si fi n gba ara wọn lọwọ awọn ti inu n bi si wọn nitori awọn iwa ọdalẹ ti wọn hu kaakiri. Ọrẹdẹhin ni awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ lẹru n ba, awọn naa ni wọn wa nidii iwa ika to n gbilẹ kiri yii, ko si si ohun to n mu wọn ṣe bẹẹ ju ibo to n bọ yii lọ.

Ọrẹdehin ni wọn fẹẹ wọle ibo, ki wọn le maa ṣejọba lọ, bẹẹ awọn araalu ni awọn ko fẹ wọn. O ni ko si ohun meji ti awọn araalu si ṣe n sọ pe awọn ko fẹ wọn ju pe ara n ni wọn lọ, gbogbo ohun to yẹ ki wọn ṣe ni wọn ko ṣe, bi ẹnikẹni ba si sọrọ pe ki lo de ti wọn ko ṣe bẹẹ, wọn yoo ni ki ọlọpaa gbe e, bi wọn ko si ni ki ọlọpaa gbe e, wọn yoo dẹ awọn tọọgi si i ti wọn yoo lu tọhun kan lapa, tabi ki wọn lu u kan lẹsẹ, ti wọn yoo si sọ tọhun di alaabọ ara. O ni iwa ijọba amuninipa yii lo n ba awọn eeyan lẹru, oun lo n dun wọn ti wọn si fi sọ pe awọn ko fẹ Ẹgbẹ Ọlọwọ, awọn ko ṣe Ẹgbẹ Dẹmọ. Ṣugbọn ọrọ naa n ba awọn aṣaaju Dẹmọ yii lẹru, pe ti awọn ko ba wọle ibo to n bọ yii, bawo ni aye awọn yoo ṣe ri. Ohun ti wọn ṣe lo tọọgi niyi o, kaka ki wọn ṣe ohun ti awọn araalu fẹ.

Bi wọn ti n fa ọrọ naa mọ ara wọn lẹnu ti wọn n fa a bọ niyẹn, ṣugbọn ija ko duro ni Western Region, lati ilu Eko titi de Ekiti, lati Ibadan titi wọ Ọyọ, Ogbomọṣọ, awọn tọọgi awọn ẹgbẹ oṣelu yii ko yee ba ara wọn fa kuraku kaakiri. Ohun to si ṣẹlẹ ni pe nigba ti wahala awọn tọọgi ẹgbẹ Dẹmọ yii pọ, awọn tọọgi ẹgbẹ oṣelu to ku naa jade, nitori ko kuku si ẹni ti ko ni tọọgi ninu wọn, tawọn kan kan pọ ju tawọn mi-in lọ ni. Nitori pe ẹgbẹ Dẹmọ lo n ṣejọba, ti wọn si n ri owo ati ipo fawọn eeyan, tọọgi tiwọn pọ ju tawọn AG ati NCNC lọ, ṣugbọn ki i ṣe pe awọn ẹgbẹ oṣelu meji to ku yẹn naa ko ni tọọgi rara o, awọn naa ni awọn ti wọn n lo bi ija ba de, wọn ni awọn ti wọn n lo bi ọrọ ba di ariwo. Eyi to waa tubọ ran ẹgbẹ oṣelu AG lọwọ ni pe awọn araalu wa lẹyin wọn, wọn si n gbeja wọn.

Bi wọn ti n ṣe e ni pe nibikibi ti wọn ba ti ri ẹgbẹ Dẹmọ, boya mọto wọn ni wọn ri tabi wọn ri awọn eeyan wọn ti wọn n pariwo, koda ko ma si tọọgi laarin awọn ti wọn ba nibẹ tẹlẹ, awọn ọdọ agbegbe naa yoo ṣa ara wọn jọ, wọn yoo si kọlu wọn kia. Ibikibi ti wọn ba gburoo aṣaaju ẹgbẹ Demọ kan si, kia ni awọn eeyan yoo ti ṣa ara wọn jọ, wọn yoo si rọ lọ sibẹ, bi wọn ba si ri aṣaaju ẹgbẹ Dẹmọ naa nibi to wa, boya o waa raja tabi o n lọ jẹẹjẹ rẹ ni, wọn yoo kọlu u gidigidi. Eyi di ijaya gidi fawọn aṣaaju Dẹmọ, paapaa awọn ti wọn ti jẹ ọmọlẹyin Awolọwọ tẹlẹ: awọn ni awọn araalu yii koriira ju, wọn ni ọdalẹ ni wọn, awọn ni wọn ko ba wọn ni Western Region. Ko si ibi ti wọn ti ri awọn eeyan yii ti ija ko ni i ṣẹlẹ. Lọjọ kan, Akintọla funra rẹ lọ si ode kan, ṣugbọn ere lo sa kuro nibẹ, nigba to gbọroyin pe awọn eeyan ti n ṣarajọ lati kọlu u.

Eko ni wọn ti waa ṣe ode naa, bẹẹ ni ki i ṣe gẹgẹ bii olori ijọba lo wa, Akintọla wa sibẹ bii ọrẹ awọn ti wọn n ṣenawo naa ni. Loootọ awọn ọlọpaa ati awọn tọọgi diẹ wa lẹyin rẹ, ṣugbọn nigba ti ariwo de pe awọn eeyan n ya bọ waa ba a, kia lo pe awọn ọmọlẹyin rẹ pe ki wọn gbe mọto jade, awọn gbọdọ maa lọ. Nigba ti awọn eeyan naa yoo fi de, mọto Akintọla ti n lọ, ṣugbọn wọn le e gidigidi, wọn si bẹrẹ si i sọ awọn oko rigidirigidi lu mọto naa, wọn n pariwo ole, ole, ole le e lori bi mọto naa ti n sare buruku lọ laarin igboro. Eyi yoo fihan bi ọrọ naa ti ri, ati bi ọrọ naa ti le to, nigba ti awọn araalu ba gbarajọ bẹẹ, ti wọn si le olori ijọba kuro ni pati, ti wọn le mọto rẹ kitakita lati mu oun ati awọn ti wọn tẹle e, o si daju pe bi ọwọ wọn ba tẹ ẹ nijọ naa, ohun ti wọn yoo fi ṣe ko ni i ṣee fẹnu sọ. Gbogbo eeyan lọrọ naa n ba lẹru.

Afi Fani-Kayọde ni tiẹ, oun ko ni ibẹru kan, nitori ẹkun-un-rẹrẹ ni mọto rẹ ni gbogbo ibi ti oun ba n lọ, awọn tọọgi ti yoo si tẹle oun nikan lẹyin le da odidi ilu kan ru. Bo ba ti mu ọlọpaa kan ṣoṣo dani to fi iyẹn digẹrẹwu, awọn tọọgi ẹyin rẹ yoo le ni ogun, wọn yoo le ni ọgbọn nigba mi-in, hẹrimọ hẹrimọ ni aya wọn si to, ẹni ti yoo duro niwaju wọn yoo ṣe ko too jẹ. Iyẹn lo ṣe jẹ ninu awọn oloṣelu Dẹmọ igba naa, ko si meji Fani-Kayọde, oun lalagbara inu wọn. Nigba to si ti di pe wọn fẹẹ kọlu Akintọla bẹẹ, oun aa lọọ tun ṣeto tọọgi kun tọọgi, to jẹ nibi ti Akintọla ba n lọ, awọn tọọgi ẹgbẹ Dẹmọ yoo ti duro de e lọhun-un, bẹẹ lawọn mi-in yoo si tẹle e bo ba ti n lọ. Gbogbo ẹ naa, lati ri i pe awọn tọọgi ti Ẹgbẹ Ọlọpẹ, ati araalu to n ti wọn lẹyin, ko kọlu olori ijọba naa ni. Ọrọ yii ko jẹ ki ọkan ẹnikẹni balẹ laarin ilu rara.

Ọkan wọn ko le balẹ, nitori wọn ti mọ pe ode yoowu ti awọn ba gbe awọn oloṣelu yii si, wọn yoo da ibẹ ru ni. Ani lọjọ kan, ninu oṣu kẹjọ, ọdun 1964, awọn oniṣọọṣi nla ilu Eko kan fẹẹ ṣe ayẹyẹ ajọdun ikore wọn, ni wọn ba fi Fani-Kayọde ṣe alejo pataki nibẹ. Ṣọọṣi St. Peter’s, Eko ni o, wọn ni awọn yoo ṣe ayẹyẹ naa, yoo jẹ alarinrin, ko si si ẹni to yẹ ki awọn pe sibẹ ju ọkan pataki ninu awọn olori ijọba West lọ. Iyẹn ni wọn ṣe pe Fani-Kayọde o, wọn ni oun lawọn fẹ, ko maa bọ waa fi ijokoo ọlọla yẹ awọn si. Inu Fani-Kayọde dun, nitori ọkan ninu awọn ṣọọṣi to tobi ju ni Naijiria nigba naa ni St Peter’s yii n ṣe. Inu rẹ dun pe awọn eeyan naa ka oun si to bẹẹ, o si ti mura lati waa fi ijokoo yẹ wọn si gẹgẹ bi wọn ti ṣe sọ. O kọwe si wọn pe oun ti ri lẹta wọn gba, oun si fi n da wọn loju pe oun n bọ o, awọn yoo jọ ṣe ayẹyẹ naa ni.

Amọ ko pẹ ti awọn oniṣọọṣi yii gba lẹta ti wọn tun jokoo ipade mi-in, wọn ni ki awọn da ọrọ naa ro laarin ara awọn o, wọn ni pẹlu tọọgi ti Fani-Kayọde n ko rin yii, ati awọn tọọgi ẹgbẹ oṣelu mi-in ti yoo waa pade rẹ lọdọ awọn, bi awọn ko ba ṣọra, awọn tọọgi ni yoo da ikore awọn ru o. N ni wọn ba yaa sare gbe lẹta mi-in, ni wọn ba tun kọ ọ si Fani-Kayọde, wọn ni awọn bẹ ẹ ko ma binu, awọn ko le fi i ṣe alejo pataki nibi ikore naa mọ, wọn ni ko ma wulẹ wa mọ, awọn yoo fi ẹlomiiran ṣe e. Wọn ṣalaye o, wọn ni awọn ohun to n ṣẹlẹ ni West lọwọlọwọ bayii ni ko ni i jẹ ki awọn le gba a lalejo mọ, nitori ko si ẹni to mọ ibi ti kinni naa yoo ti tun ṣẹlẹ, ati ọna ti yoo gba ṣẹlẹ rara. Wọn ni awọn ko ba ti kọ iru lẹta yii si i bi ko jẹ ohun to ṣẹlẹ si Ayọ Rosiji laipẹ yii, Rosiji to jẹ ọkan pataki ninu ọmọ ẹgbẹ wọn.

Ṣe loootọ si ni, ori lo ko Ayọ Rosiji yọ, awọn eeyan fẹẹ lu u pa nigboro Eko lọjọ kan. Lori ọrọ awọn Akintọla yii naa ni o, lori ọrọ awọn ẹgbẹ Dẹmọ. Ṣe ẹni to ba si mọ Rosiji daadaa, ọkan ninu awọn ogboju ọmọlẹyin Awolọwọ ni, oun paapaa ni akọwe ẹgbẹ AG tẹlẹ ki ija too de, amọ nigba ti ija de, ọta tirẹ to ba Awolọwọ ṣe ju ti awọn ti ko sun mọ Awolọwọ rara lọ. Niṣe lo sọ ija naa di ija ajaku, o si wa ninu awọn to rojọ mọ Awolọwọ lẹsẹ daadaa, awọn ọrọ to sọ ati ẹjọ to ro, ati nitori pe oun jẹ akọwe ẹgbẹ AG wa ninu ohun ti wọn fi ju Awolọwọ sẹwọn. Paripari rẹ ni pe ọkan ninu awọn ti wọn ti Akintọla nidii lati da ẹgbẹ oṣelu tuntun silẹ ni, ọkan pataki ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ Dẹmọ si ni. O gbajumọ daadaa bii iṣaana ẹlẹẹta ni, gbogbo eeyan lo si mọ ọn. Ki ọrọ too dija nibikibi ti awọn eeyan ba ti ri i bẹẹ, wọn yoo bẹrẹ si i pariwo orukọ rẹ ni.

Bi wọn ti n pariwo “A. Y. O.” tẹle e lẹyin, bẹẹ ni wọn yoo maa pariwo “Awoo! Awooo!” bi wọn ba ti ri i. Ṣugbọn ti ọjọ buruku yii ko ri bẹẹ, nigba ti wọn ri i l’Ekoo ti oun ati ọrẹ rẹ kan lọ, okuta ribitiribiti lawọn eeyan naa ṣa jọ, ibi ti wọn si ti sare ri ara wọn bẹẹ ko ye ẹnikan. Ni Marina ni, Rosiji ati ọrẹ rẹ kan ni wọn wa sibẹ. Bo si ti bọ silẹ ninu mọto mẹsidiisi to wọ loun ati ọrẹ rẹ naa n lọ, wọn fẹẹ wọ ileeṣẹ nla ti wọn pe ni Investment House, l’Ekoo, nigba naa. Nibẹ lawọn eeyan ti ri i, ni wọn ba n pariwo laarin ara wọn, Rosiji niyẹn, Ayọ Rosiji niyẹn. Oun kọkọ ro pe ere ni, o ro pe awọn ti wọn fẹran oun ni, afi nigba ti ariwo, ‘ooolee, ooleee’ bẹrẹ si i dun leti rẹ, ko si too ṣẹju pẹu, oko nla nla ti n sọlẹ sitosi rẹ, wọn fẹẹ ju u lokoo pa. Kia lawọn mi-in ti bẹrẹ si i kọrin laarin wọn, wọn n pe, “Ọmọ ajẹ wọja, ẹ juko fun un!”

Rosiji naa mọ pe ọrọ naa ko kere mọ, ni jagunlabi ba ka a nilẹ, ọmọ ọkunrin naa fẹsẹ fẹ ẹ.

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

 

 

 

 

 

 

 

 

 

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.