Ẹ jẹ yaa tete ba gomina Kano sọrọ ni tiẹ

Spread the love

Lara awọn onibajẹ gomina ni ti Kano yii, Ọkunrin kan ti wọn n pe ni Ganduje. Lara awọn ohun tawọn Buhari n ṣe ti ko tun nnkan ṣe rara ni ti Ganduje yii. Ni bii oṣu meji sẹyin ni ariwo gba igboro pe ọkunrin gomina yii gba abẹtẹlẹ, owo ẹyin, owo Dọla lọwọ awọn to n gbe iṣẹ ijọba fun ni ipinlẹ rẹ. Ki i ṣe pe ọrọ naa jẹ irọ, ori fidio ni wọn ka gbogbo ohun to ṣẹlẹ si, wọn si fi fidio yii han lori ẹrọ ayelujara. Gbogbo aye lo ri ibi ti ọkunrin yii ti n gba dọla, wọn si ri bo ti n ko owo naa sapo ara tiẹ. Awọn EFCC to maa n sare sọrọ si iru nnkan bayii ko wi kinni kan, lẹyin ti Ganduje si ti ni oun da ẹgbẹ kan silẹ, ẹgbẹ awọn alatilẹyin Buhari, ileeṣẹ aarẹ sọrọ pe eeyan daadaa ni Ganduje i ṣe. Iroyin to waa jade ni Kano lọsẹ to kọja bayii ni pe miliọnu mẹta awọn ọmọ keekeekee ipinlẹ naa to yẹ ki wọn lọ sileewe ni ko si ileewe ti wọn fẹẹ lọ, ti wọn kan wa nile lai ṣe kinni kan, ti wọn si n ringboro ilu Kano kiri. Miliọnu mẹta! Awọn eleyii ti to lati ba odidi orilẹ-ede kan jẹ, nigba ti wọn ko ba ni ẹkọ kan to ye kooro. Ọmọ ti a bi ti a ko kọ, yoo gbe ile ti a ba kọ ta ni, o si daaju pe awọn ọmọ miliọnu mẹta to wa ni Kano ti ko rele iwe yii, ti wọn ko si kọ iṣẹ ọwọ kan, iru wọn ko ni i wulo fun ilu naa, wọn ko ni i wulo fun ipinlẹ naa, wọn ko si le wulo fun Naijiria lapapọ. Bẹẹ oun to yẹ ki gomina yii mojuto niyẹn, ẹkọ lo yẹ ko fun awọn ọmọ ipinlẹ rẹ, ṣugbọn oun lo wa nibẹ to n ko owo jẹ yẹn. Kaka ki awọn ti wọn n ṣejọba si ba a sọrọ, ki wọn mu un fun iwa ibajẹ, ẹyin rẹ ni wọn wa, ti wọn ni eeyan daadaa ni. Awọn ohun tawọn ti wọn wa lẹyin Buhari n ṣe niyi, awọn iwa ti ko si mu eto ọrọ-aje wa daa ree, nitori bẹẹ ni Buhari ṣe gbọdọ ba wọn sọrọ. Awọn eeyan yii lo n fiya jẹ awọn araalu, awọn ni wọn n mu nnkan wa le koko. Ki Buhari le awọn opurọ ati ole paraku jinna lẹyin rẹ, ki wọn too ba nnkan to dara jẹ, ki wọn too sọ Naijiria di ilu awọn akuṣẹẹ patapata.

 

 

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.