Ẹ jẹ ma fori sọ biriki, abi ki lo n bi wọn ninu

Spread the love

Bi inu eeyan ba le laleju, oṣi lo maa n fi ta oninu, nitori inu buruku, oogun oṣi ni. Awọn ti wọn n ba Aarẹ Muhammadu Buhari binu rẹpẹtẹ lọsẹ to kọja, eeyan ko si le mọ boya Buhari funra rẹ mọ si ibinu odi naa, boya ko mọ si i. Ohun to n bi wọn ninu ko ju ọrọ olootu ti iwe iroyin Punch gbe jade lọ, nibi ti iwe naa ti sọ pe Aarẹ wa n sọrọ bii alaimọkan, kaka ko mojuto iṣoro to wa nilẹ, ọrọ to n sọ lẹnu ko yatọ si ọrọ ẹni ti ko mọ nnkan kan. Ki lo de ti Punch fi sọ ọrọ to le to bẹẹ yẹn. Aarẹ funra rẹ lo fa a. Abi nigba ti Buhari sọ pe awọn Fulani to n paayan yẹn, ko si ohun to jẹ ki wọn maa pa awọn eeyan kaakiri bẹẹ bi ko ṣe pe wọn ko ri ibi gbe mọ lọ, o ni ibi ti wọn n gbe ninu aṣalẹ Sahara Desert yẹn ti gbona ju, iyẹn ni wọn ṣe n sa jade lati wa sigboro, ti wọn si fi n wọ ilẹ onilẹ nibi ti wọn ko de ri. O ni yatọ si ti pe awọn Fulani naa n sa jade, awọn oniroyin lo tun n da kun ọrọ naa, nitori ariwo ti wọn maa n pa, bi ọrọ kekere kan ba si ti ṣẹlẹ ni wọn aa fẹ ẹ loju gbaragada, ti wọn yoo si maa pariwo bii ẹni pe laye ijọba Buhari nikan ni wọn ti kọkọ fẹẹ paayan. Ọrọ ti Buhari sọ niyẹn, ọrọ naa ni awọn olootu iwe Punch si sọrọ le lori, pe bawo ni Aarẹ yoo ṣe maa sọ bayii, bawo ni yoo ṣe maa sọrọ awọn Fulani apaayan pe kinni kan lo le wọn nibi ti wọn n gbe ni wọn ṣe n waa paayan nilẹ onilẹ, tabi pe awọn oniroyin lo n fẹ ọrọ naa loju. Ki lawọn oniroyin yoo fẹ loju ninu ọrọ yii, ṣe bi awọn kan ba paayan, kawọn oniroyin sọ pe wọn ko pa wọn ni, nigba to jẹ ojuṣe tiwọn ni lati sọ ohun to ba ṣẹlẹ fun gbogbo aye. Lọna keji loootọ, bawo ni olori ijọba Naijiria yoo ṣe sọ iru ọrọ bẹẹ yẹn jade. Ṣe bi wahala ba ṣẹlẹ nibi ti awọn kan n gbe, ẹtọ si ni fun wọn lati lọ si ọdọ awọn mi-in ki wọn maa pa wọn ni. Ọna kan ṣoṣo to wa nilẹ ni lati doju ibọn kọ awọn apaayan yii, bi wọn ti n paayan, ki awọn ṣọja si pa awọn naa. Ọpọ igba lawọn eeyan ti sọ ọ, awọn araalu oyinbo ti wi bẹẹ, awọn ti ki i ṣe ti ilu oyinbo ti sọ ọ, awọn ọjọgbọn aye ti sọ ọ, pe ijọba Buhari ni ko mojuto ọrọ awọn Fulani yii, nitori pe ijọba ko si ṣe nnkan gidi kan sọrọ wọn lawọn naa ṣe n paayan lojoojumọ si i, nigba ti wọn ti mọ pe ko si kinni kan ti yoo ṣe awọn. Ko si ibinu kan to yẹ ki awọn eeyan Buhari tabi Buhari funra rẹ bi ninu ọrọ yii, o yẹ ki wọn gba imọran naa bii imọran otitọ ni, ki wọn si ṣe ohun to ba yẹ ki wọn ṣe. O pẹ ti awa naa ti n sọrọ nibi yii, pe ki Buhari paṣẹ ki awọn ṣọja dojukọ awọn Fulani apaayan, nibi ti wọn ba ti paayan, ki wọn pa awọn naa. Ṣugbọn Buhari ko fẹ ki wọn pa wọn, kaka ko pe awọn eeyan naa ni afẹmiṣofo, yoo ni awọn ti wọn n ja lasan pẹlu awọn ẹya mi-in ni. Wọn yoo ni ki ọlọpaa mu wọn, awọn ọlọpaa yoo ni apa awọn ko ka wọn. Loootọ ati lododo, Buhari ni ko fẹ iṣọkan ati iduro ṣinṣin orilẹ-ede yii, nitori oun lo sọ awọn ọmọ Naijiria to ku di ounjẹ fawọn Fulani yii, to n jẹ ki wọn pa wọn bii ẹran. Eyi to buru nibẹ ni pe bi awọn kan ba dide ti wọn gbeja ara wọn, Buhari ati ijọba rẹ yoo tun binu, wọn yoo ni wọn n pa Fulani, alejo ti ko lẹni kan. Ẹni ti ko lẹni kan to n paayan, ẹni ti ko lẹni kan to n gbebọn kiri. Ki Buhari ati awọn ti wọn n ba wọn ṣiṣẹ ma jẹ ki ọrọ yii ka wọn lara rara, ohun to yẹ ki wọn ṣe ni ki wọn ṣe. Awọn Fulani n paayan, wọn n pa awọn ti wọn niluu wọn jẹẹjẹ, wọn ko si ṣe kinni kan fun wọn. Ohun to yẹ ki ijọba gidi ṣe ni lati dẹkun iwa ika, iwa aburu bayii, ko si le gbogbo oloriburuku ẹda kuro ni ilẹ wa. Ṣugbọn Buhari ko ṣe bẹẹ nitori Fulani loun naa, o waa n binu pe wọn ba oun sododo. Eleyii ko daa o, eleyii ki i ṣe iwa daadaa o. Gbogbo ohun ti Buhari n ṣe yii le pada da le oun ati awọn eeyan rẹ lori nijọ kan, ati ọmọ ati idile rẹ paapaa, nigba naa ni yoo mọ iru inira ti ijọba rẹ n ko ba gbogbo ilu, nitori Ọlọrun ẹdẹ lọba Ọlọrun!

 

(37)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.