Ẹ jẹ ka mọ o, ki lo n ṣe Baba Buhari gan-an?

Spread the love

Ni gbogbo ọsẹ to kọja yii, iroyin to gba ilu kan lẹyin ti awọn ọlọdun ti ṣọdun tan ni irin ti ko to idaji maili ti AarẹMuhammadu Buhari rin lati yidi to ti kirun pada si ile rẹ. Ọrọ naako yẹ ko di ariwo rara, abi ki lo yẹ ko di wahala ninu pe eeyan kirun tan, o si rin lati ibi to ti kirun pada si ile rẹ, irin naako si to maili kan, bẹẹ ni ko ju irin iṣẹju mẹwaa lọ, bo ba to bẹẹ rara. Ṣugbọn awọn ọmọọṣẹ Buhari funrawọn ni wọn da kinni naa silẹ, Garba Shehu, ọkan ninu awọn ẹnu-n-ja-waya to yi Buhari ka lo sare gbe e sori ẹrọ ayelujara pe, “Ẹ waa wo o, Aarẹ Buhari ti rin irin idaji maili lẹyin to kirun tan. Eyi lo fi han pe ara baba da pe lati ṣe aarẹNaijiria lọdun 2019.”Ọrọ naada bii ọrọẹnikan ti ori rẹ ko pe, ṣugbọn nitori ipo ti Garba di mu, to si jẹ awọn ni wọn n ri Buhari lojoojumọ, eeyan ko le sọpe ori rẹ ko pe, o mọ ohun to n sọ. Ohun to n sọ ni pe ara Buhari ko ya, aiya-ara naa si pọ debii pe wọn ko mọ peyoo le rin iru irin to to bẹẹ yẹn ko tooṣubu. Ṣugbọn loju Garba, Buhari rin irin bii idaji maili, o rin fun odidiiṣẹju mẹwaa ko ṣubu, eleyii to ọpẹ, o ju ọpẹ lọ, bẹẹ losi jẹ idi pataki ti gbogbo ọmọ Naijiria fi gbọdọ mọpe ara baba yii da ṣaka, o si leṣe aarẹ wọn fun odidiọdun mẹrin mi-in si i. Awa mọ pe ara Buhari ko ya, gbogboilu lo si mọ, bi aiya-ara naa ti pọ to lawọn ti wọn yi i ka, ati baba naa funra rẹ kọ lati sọ fun gbogboọmọ Naijiria. Ṣugbọn Buhari ko gbadun. Ko gbadun rara paapaa. Ẹni to ba woye ohun to maan ṣẹlẹ niwọnba igbato ba jade kuro niluu yoo mọpe ko gbadun. Niwọnba igba to fi lọ yii, awọn ayipada kan sare ṣẹlẹ to jẹ niṣe lomu ilu rọ pẹsẹ, ti iṣẹ ijọba si sare lọ fun saa diẹ ko too di pe o pada de. Ṣugbọn bo ti pada de ni nnkan ti tun lọ sẹyin pada, o si daju pebi yoo ti maabajẹ si i titi ti yoo fi tun lọ niyẹn. Gẹgẹ biiroyin Buhari ti a ti gbọ tẹlẹ, o ṣee ṣe ki ijọba rẹ daa, o ṣee ṣe ko le ṣejọba to daa, bo ba jẹ ara rẹ ya daadaa, to si le ṣe kebekebe. Titi di bi a ṣe n wi yii ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ n gba bọọlu ẹlẹyin, bẹẹ lon sare, bẹẹ lo n jo, o si le rin yi gbogbo Abẹokuta ka ti wọn ba gba a laaye. Ki waa ni awọn oponu kan yoo maa gbeọrọ gẹgẹ pe Buhari rin irin idaji maili! Ko ye wọn ni.Awọn ro pe wọn fi ọrọ naapọn Buhari le ni, wọn ko mọ pe wọn fi tu aṣiri ara wọn sita ni. Nnkan n ṣe Buhari, ara rẹ ko ya, awọn kan si wa ti wọn ko fẹ ko lọọ jokoo sile rẹ ko sinmi, wọn fẹ ko maaṣe ijọba Naijiria lọ bẹẹ. Ẹni to ba ro pe ki Naijiria le dara lawọn yii ṣe n ṣe bẹẹ, wọn ko da nnkankan mọ rara ni, oju wọn si ti di nitoriọrọ oṣelu ti wọn ko ri jẹ nibẹ ti wọn kan n pariwo ẹnu kiri. Awọn tiwọn fẹ ki Buhari maaṣejọba lọ pẹlu aiya-ara mọpe ki i ṣe Buhari lo n ṣejọba, awọn funra wọn ni wọn n ṣejọba, ẹẹkọọkan ti Buhari ba si raaye da wọn lohun, lẹẹkọọkan to ba ṣẹṣẹ lo oogun rẹ tabi to ba gba abẹrẹ ipa ti i mu ni ṣiṣẹ abaadi, ohun ti wọn ba ṣe ni yoo fọwọ si, ko si aaye lati ronu jinlẹ fun un. Iru eleyii ko daa, awọn eleyii ko bẹru Ọlọrun ni, wọn mọ pe ara Buhari ko ya, wọn n ti i mọ wa lọrun, nitori ijẹkujẹ ti wọn n jẹ. Ọlọrun yoo da wọn lẹjọ, ori ọmọNaijiria yoo da wọn lẹjọ, idajọ naa yoo si le pupọ fun wọn.

 

(78)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.