Ẹ jẹ ka beere ibi ti Mimiko n lọ gan an

Spread the love

Oluṣẹgun Mimiko ti loun ko ṣe purẹsidẹnti mọ, o ni ile-igbimọ aṣofin agba loun fẹẹ lọ. Bẹẹ ni ko si ninu ẹgbẹ Labour, ko si ninu PDP, ko si si ninu APC, awọn ẹgbẹ to ti ba ṣe tẹlẹ ree, ko too waa di ọmọ ẹgbẹ ZLP. Ko ti i ju ọdun kan lọ ti ọkunrin yii fi ileejọba silẹ, ṣugbọn awọn irin to n rin lati igba naa, irin to fihan pe awọn oloṣelu yii o le ṣe nnkan meji laye wọn ju ki wọn wa nidii iṣẹ ijọba ti wọn yoo ti maa gba owo ọfẹ, ti wọn yoo ti maa jẹun ọfẹ, ti wọn yoo ti maa ṣe oun gbogbo lọfẹẹ lọfẹẹ, ti wọn yoo maa nawo araalu, ti wọn yoo si maa ṣe bii ẹni pe awọn ni Ọlọrun wọn. Bi ọrọ ẹni kan ba si wa ti yoo yaayan lẹnu, ti Mimiko yii, ọkan ni. Idi ni pe oniṣegun oyinbo ni Mimiko, dokita ni. Ohun tawọn eeyan yoo ro ni pe ni gbogbo igba ti Mimiko fi n ṣe gomina, yoo tọju owo to ba ri, iyẹn owo to jẹ owo tirẹ, yoo si lo ipo rẹ lati fi ni awọn eeyan to le ran an lọwọ, bo ba ti n kuro nileejọba bayii, ọsibitu agbayamuyamu kan ni yoo da silẹ, ọsibitu naa yoo si jẹ eyi ti gbogbo agbaye yoo maa waa gba itọju nibẹ. Nigba to jẹ dokita ni, to si ni oun ṣeto ilera to daa fawọn eeyan Ondo nigba ti oun fi n ṣejọba, ki lo waa de ti oun ko le da ọsibitu nla kan silẹ, nibi ti awọn araalu yoo ti ri iṣẹ ṣe, ti yoo ti gba awọn akọṣẹmọṣẹ, ti ọsibitu naa yoo si gbe orukọ ilu Ondo, ti ipinlẹ Ondo ati ti Naijiria pẹlu Afrika ga. Abi nigba ti gbogbo aye ba mọ pe ọsibitu kan wa l’Ondo to jẹ to o ba ti debẹ, iwosan de ni, wọn ni irinṣẹ igbalode, awọn dokita to wa nibẹ si gbona, ṣebi gbogbo ẹni to ba fẹ ilera lati origun mẹrẹẹrin Afrika ni yoo maa lọ sibẹ. Bi wọn ba waa sọ pe Mimiko lo ni iru ọsibitu bẹẹ, ṣe iyẹn ko dara ju ko maa ta ragbaragba bayii kiri lọ. O ti ṣe kọmiṣanna, o ṣe akọwe ijọba, o ṣe minisita, o si fi ọdun mẹjọ ṣe gomina, ipo wo lo tun ku ti ọkunrin yii tun n wa o. O ṣe ẹgbẹ AD to jẹ ibẹrẹ APC, o ṣe PDP, o ṣe Labour, inu ẹgbẹ oṣelu wo lo tun n lọ o! Awọn eeyan ki i mọ bi wọn ti to afi nigba ti wọn ba tẹ patapata, bẹẹ ni oloṣelu Naijiria ki i fẹẹ ṣe iṣẹ mi-in ju oṣelu rẹ lọ, nitori nibẹ nikan ni wọn ti le ri owo ko jẹ ati ti wọn le ni agbara nla ti ko tọ si wọn lati fi ṣe ohun yoowu ti wọn ba fẹ, o daa ko daa. Ẹyin ọrẹ Mimiko, ẹ sọ fun un ko jokoo jẹẹ jare, abi ki lo n wa kiri gan-an!

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.