Ẹ gbọrọ sira yin lẹnu o

Spread the love

Bi Ọlọrun ba ran ẹnikan si Aarẹ Muhammadu Buhari, ti ko fẹ ki Naijiria fọ mọ ọn lori, o da bii pe Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje, ni. Boya nitori ti ọkunrin naa ki i ṣe Fulani, ti oun jẹ Hausa ni. Oun yatọ si awọn eeyan bii El-Rufai ti i ṣe gomina Kaduna, to jẹ gbogbo ohun to wa lọkan tirẹ ni lati tan Buhari jẹ, nitori ipo to n wa, ati ijẹkujẹ to wa lọwọ wọn bayii. Ṣugbọn Ganduje lo n sọ ootọ lori ọrọ awọn Fulani yii, o si di ẹẹkeji ti yoo sọrọ naa. Akọkọ ni igba to sọ pe ki ijọba apapọ da awọn onimaaluu to n daran lati ilẹ Hausa lọ si ilẹ Ibo ati ilẹ Yoruba duro, ki wọn paṣẹ pe ki wọn ma da maaluu wọn lọ sibẹ mọ, ki wọn ko maaluu wọn duro si ilẹ Hausa, ki wọn si maa ṣe iṣẹ wọn nibẹ. Ọkunrin naa ni ki awọn fi ọrọ ro ara awọn wo, o ni njẹ o ṣee ṣe ki awọn ara ilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo maa waa sin ẹlẹdẹ ni ọdọ tawọn, bo tilẹ jẹ pe awọn ti wọn n jẹ ẹlẹdẹ naa wa ni awọn agbegbe ilẹ Hausa. O ni o daju pe ijọba ati awọn eeyan ilu ko ni i gba fun awọn Yoruba ati Ibo ti wọn ba fẹẹ ṣe iru òwò bẹẹ yẹn lọdọ wọn, wọn yoo binu, ọrọ naa yoo si di ariwo gidi, iyẹn ti ko ba mu itajẹsilẹ lọ. O ni nigba ti awọn ko ba ti le gba iru rẹ, ko yẹ ki awọn naa lọọ ko Fulani sọrun awọn ara Ilẹ Ibo ati ilẹ Yoruba, ki awọn ni ki wọn lọọ maa sin maaluu wọn nibẹ tipatipa. O ni ko daa. Ẹẹkeji lo tun sọrọ lọsẹ to kọja yii, ohun to si wi ni pe kijọba ma gbe RUGA to loun fẹẹ ṣe lọ si ilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo, ko ma si fi tipatipa mu ẹnikẹni lati ṣe RUGA si agbegbe wọn, ẹni to ba fẹ RUGA lọdọ wọn ni ko waa ṣe e si. O ni ko daa lati lọọ da abule awọn Fulani si agbegbe tiwọn ki i ti i ṣe Fulani, o ni ija ni iru nnkan bẹẹ yoo mu wa lọjọ iwaju. O ni bi Buhari ba fẹẹ ṣe RUGA rẹ, ibi ti awọn Fulani ba n gbe lo yẹ ko ti ṣe e, ko si si ibi ti Fulani n gbe ju ilẹ Hausa lọ. Bo ba ṣe pe wọn yoo gbọ ọrọ ọkunrin yii, ṣe iba dara. Nitori bo tilẹ jẹ pe oun naa ni awọn iwa tirẹ lọwọ, sibẹ ọrọ to n sọ lori ọrọ awọn Fulani ati ijọba Buhari yii, ọrọ ọlọgbọn to yẹ ki awọn ti wọn n ṣejọba gbe yẹwo lọkan ara tiwọn ni. Ohun to ku ti Ganduje ko fi kun un ni pe ko si ohun to kan ijọba apapọ lati da abule onimaaluu silẹ fawọn Fulani ti wọn n fi maaluu ṣe iṣẹ aje tiwọn. Bi wọn ba fẹ abule onimaalu, ki wọn ko owo wọn kalẹ, ki wọn ra ilẹ sibi to ba dara, ki wọn si yawo ni banki, nigba to jẹ iṣẹ okoowo tiwọn ni wọn fẹẹ fi i ṣe. Ki lo kan ijọba lati fi owo awọn ọmọ Naijiria ṣiṣẹ aje fawọn Fulani, nitori kin ni? Aye ko tilẹ da maaluu kiri igboro tabi aarin ilu mọ, ibi ti wọn ti n sin maaluu ki i ṣe inu igbo jingbunjingbun. Irinṣẹ oriṣiiriṣii ti wa, koda, eeyan le sin maaluu lori ilẹ eeka kan, ti wọn yoo maa jẹ, ti wọn yoo si maa ṣe ere wọn kiri. Gbogbo eyi ti awọn Buhari n ṣe yii, ọgbọn ati ẹtan ni, wọn fẹẹ lo maaluu lati fi gba ilẹ wa lọwọ wa ni. Wọn fẹẹ lo maaluu lati fi sọ awọn Fulani di olori ni agbegbe kọọkan. Ṣugbọn Oluwa Ọba to ni ọjọ oni ko ni i gba fun wọn o, yoo da wọn lẹbi gbẹyin, yoo si gba gbogbo agbara ti wọn ni ti wọn fi n ṣe aburu yii kuro lọwọ wọn.

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.