Ẹ fun wọn lowo wọn ki nnkan ma bajẹ o

Spread the love

Awọn oṣiṣẹ n palẹmọ rẹpẹtẹ bayii lati bẹrẹ iyanṣẹlodi, wọn oo tun daṣẹ silẹ, bi wọn ba si bẹrẹ tan, Ọlọrun lo mọ ọjọ ti wọn yoo pari rẹ. Ki i ṣe pe ijọba Naijiria ko mọ pe wọn fẹẹ da iṣẹ silẹ bayii o, ṣe wọn ti kọkọ fi odidi ọjọ marun-un kan kọ iṣẹ silẹ, ti wọn ni awọn n kilọ fun ijọba silẹ ni, nitori ti awọn ba bẹrẹ loootọ loootọ, ko sẹni kan ti yoo ṣe iṣẹ kankan o. Eleyii ti ṣẹlẹ to bii ọjọ meloo kan o, sibẹ ijọba ko ri ọrọ awọn oṣiṣẹ naa yanju, wọn ni awọn ko le san ọgbọn ẹgbẹrun Naira ti wọn n beere lọwọ awọn fun wọn. Eleyii ko daa to, bi wọn ko ba tilẹ le san owo naa, o ni alaye ti wọn yoo ṣe fun wọn, wọn si gbọdọ ri i pe awọn ṣe alaye naa titi ti wọn fi gba, ko ma di pe wọn tun da iṣẹ silẹ lasiko yii rara. Idaṣẹsilẹ maa n ba nnkan jẹ ni, yoo si ṣoro ki eto ọrọ-aje Naijiria too dide naro ni ọdun yii bi wọn ba fi le jẹ ki awọn oṣiṣẹ daṣẹ silẹ fun oṣu kan pere. Ọrọ ti awọn ijọba n sọ le ṣoro lati wọ awọn oṣiṣẹ leti, nigba ti wọn ri iye ti awọn oloṣelu n gba gẹgẹ bii owo-oṣu ati owo ajẹmọnu, nibi ti oṣiṣẹ to kawe rẹpẹtẹ to si fi bii ọdun marundinlogoji ṣiṣẹ ijọba ko ti ri owo ifẹyinti gba, ti awọn ti wọn ṣe oṣelu ọdun mẹjọ pere yoo gba ile ti wọn yoo gba mọto ati owo rẹpẹtẹ. Awọn nnkan wọnyi ni ijọba gbọdọ wo, ki wọn si ṣalaye fawọn oṣiṣẹ pe awọn funra awọn yoo din owo-oṣu ati owo ajẹmọnu orisiiriṣii ti awọn n gba ku, iyẹn lo le mu awọn oṣiṣẹ gbọ ohun ti wọn sọ. Bi a ba si ni ka tun un wo, oṣiṣẹ wo ni ọgbọn ẹgbẹrun to o na ni oṣu kan, ṣe ko lọmọ ni abi ko niyawo, ita ni yoo maa sun ni tabi oun funra rẹ ko ni i wọ mọto de ibi iṣẹ ọhun. Ijọba gbọdọ jokoo lati wo gbogbo awọn nnkan wọnyi, ki wọn ba awọn oṣiṣẹ ṣepade, ki wọn si sanwo oṣu to daa fun wọn. Iye ti wọn fẹẹ gba yii ko ti i pọ ju rara, ijọba ni ko mọ bi wọn yoo ti ṣe e ti wọn yoo le san iru owo oṣu bẹẹ. Ẹ ma jẹ ki wọn daṣẹ silẹ o, boṣiṣẹ ba tun da iṣẹ silẹ kun eyi to wa lara Naijiria bayii, nnkan yoo bajẹ kọja bo ti yẹ o.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.