Ẹ fi ẹjọ ọga ileewe to ba gba ju ẹgbẹrun meji aabọ Naira owo idanwo lo sun wa- Ijọba Kwara

Spread the love

Ijọba ipinlẹ Kwara ti ke si awọn obi ti wọn ni ọmọ lawọn ileewe ijọba lati ma ṣe san ju ẹgbẹrun meji aabọ Naira, (#2,500), lọ gẹgẹ bii owo idanwo akẹkọọ to fẹẹ ṣe idanwo JSSCE tọdun 2019.

Kọmiṣanna fun eto ẹkọ, Hajia Bilikisu Oniyangi, sọ pe kawọn obi wa sileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ẹkọ lati fi to wọn leti ti ọga kankan ba beere owo to ju bẹẹ lọ lọwọ wọn.

Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin rẹ, Kamaldeen Aliagan, gbe jade lo ti ṣekilọ pe ọga ileewe to ba gba ju iye tijọba la kalẹ fun idanwo naa yoo jiya to tọ labẹ ofin.

O ṣekilọ fun awọn ọga ileewe to ti n gba owo aitọ lọwọ awọn obi lati tete bẹrẹ si i da a pada kiakia, tabi ki wọn ri ibinu ijọba.

Kọmiṣanna ọhun koro oju si bi awọn kan ṣe n gba owo ti ijọba ko paṣẹ fun wọn lati maa gba, eyi to si ti n da wahala silẹ laarin igboro.

Lasiko to ṣabẹwo si awọn ileewe kan nijọba ibilẹ Kaiama, lo ṣakiyesi pe awọn ileewe kan ṣi n gba ju iye tijọba ni ki wọn maa gba lọwọ awọn akẹkọọ lọ.

Lara awọn ileewe to ṣabẹwo si ni: Government Day Secondary School, Kaiama, Mora Tasude Secondary School, Government Unity College ati GSS Tonda Aboki.

 

 

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.