Ẹ fi adura ran mi lọwọ ki n le ṣaṣeyọri- Oyetọla

Spread the love

Lasiko ti Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, gbe iwe aba-iṣuna, bọjẹẹti, to n gbero lọkan fun iṣakoso ipinlẹ Ọṣun lọdun to n bọ lọ sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun lọsẹ to kọja lo ti rọ awọn araalu lati ma ṣe dẹkun gbigbadura fun aṣeyọri ijọba rẹ lojoojumọ.

 

Oyetọla, ẹni ti apapọ eto iṣuna to ṣe jẹ biliọnu mejilelaaadọjọ Naira ati diẹ (#152, 756, 088, 830.00), ṣalaye pe oun ko wa lati ni awọn araalu lara rara, bi ko ṣe lati mu ara dẹ wọn ni gbogbo ọna.

 

O ni ọpọlọpọ nnkan idagbasoke lo wa ninu aba eto-iṣuna naa, nitori pe aimọye ọjọ ni awọn to dantọ nidii ọrọ iṣuna lo lori ẹ koun too gbe e wa sọdọ awọn aṣofin lati le buwọ lu u.

 

Gomina ni oniruuru ara lo wa ninu oun lati da niwọn igba toun yoo lo gẹgẹ bii adari nipinlẹ Ọṣun, idi si niyi toun fi nilo adura awọn araalu loorekoore.

 

Eto isuna naa to pe ni “Budget of Hope”, Isuna Ireti’ lo sọ pe finnifinni, lai ṣẹku sibi kankan niṣejọba oun yoo ṣamulo gbogbo akọsilẹ inu rẹ fun igbaye-gbadun awọn araalu.

 

O ni ko ṣee ṣe fun ijọba nikan lati ṣamuṣẹ gbogbo alakalẹ inu bọjẹẹti naa, idi niyẹn toun fi nilo iranlọwọ awọn ileeṣẹ alaadani, awọn ajọ ti ko rọgbọku le ijọba, ajọ idagbasoke kaakiri agbaye ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Gomina Oyetọla waa rọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lati tete ṣagbeyẹwo iwe aba eto iṣuna ọhun, ki iṣẹ idagbasoke le bẹrẹ lọgan kaakiri ipinlẹ Ọṣun lọdun 2019.

 

O ni ipilẹ ti wa fun oriṣiiriṣii awọn iṣẹ idagbasoke l’Ọṣun, ohun to ku bayii ni ki oun maa mọ le wọn lori, oun ko si ni asiko lati fi falẹ rara, idi si niyi tijọba oun yoo fi ṣagbekalẹ apero kan lori eto ọrọ aje, ‘The State of Osun Economic Summit’, ni kọta akọkọ lọdun 2019.

 

Nigba to n sọrọ, abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Ọnọrebu Najeem Salam, sọ pe aba eto iṣuna naa, eleyii to jẹ ikejidinlọgbọn iru ẹ latigba ti wọn ti da ipinlẹ Ọṣun silẹ, jẹ ara-ọtọ, nitori igba akọkọ niyi ti gomina tuntun, Oyetọla, yoo gbe e wa sile igbimọ aṣofin.

 

Salam waa fi gomina loju pe lọgan lawọn yoo bẹrẹ iṣẹ, awọn ko si ni i fi ọrọ naa falẹ rara nitori oun atawọn ọmọ ile to ku mọ pataki aba eto iṣuna naa.

 

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.