Ẹ ẹ si yọ wọn kuro lori oye, awọn ọba raurau

Spread the love

Ọrọ ti eegun ba sọ, ṣe ẹ mọ pe ara ọrun lo sọ ọ, nitori ibi to sọ pe oun ti wa niyẹn. Bi ẹ ba fẹẹ gbọ ọrọ nipa eto aabo, lọdọ ẹni to ti ṣe olori awọn ọtẹlẹmuyẹ ri lẹ oo ti gbọ ọ. Eyi lo ṣe jẹ pe ọrọ yoowu ti ẹ ba gbọ lẹnu Ọgagun Kunle Togun nipa eto aabo, kẹ ẹ ti mọ pe bo ti ri lẹ gbọ yẹn. Nigba to jẹ olori ọtẹlẹmuyẹ fawọn ṣọja loun naa tẹlẹ, ifun wo lo waa wa ninu oromọdiẹ ti awodi ko mọ, ko si kinni kan ti ko mọ nipa awọn ọdaran ati bi eto aabo ṣe yẹ ko ri. Eyi lo ṣe jẹ ọrọ to sọ nipa awọn ọba agbegbe Oke-Ogun kan gba apero gidi. Ọgagun Togun ni a kan n pariwo ‘Fulani’, ‘Fulani’ ni o, eyi ti awọn ọba wọnyi n ṣe ninu ọrọ naa lo buru ju. Ọkunrin yii ni awọn ọba Oke-Ogun yii ni wọn n ta ilẹ ni owo to pọ fun awọn Fulani. O ni bi awọn yẹn ba ti gbe owo wa pe awọn fẹẹ ralẹ, oju wọn yoo ran wọn-ọn, wọn yoo si maa ṣa owo le awọn yẹn, bẹẹ lawọn yẹn yoo maa sanwo ọhun, kẹrẹkẹrẹ bẹẹ ni wọn fi n gba ilẹ mọ wọn lọwọ laduugbo naa. Ohun to n ba ọkunrin ologun yii lẹru ni pe ọrọ RUGA RUGA ti wọn n pariwo rẹ kiri yii, bi ijọba ba wa gbogbo ọna ti wọn ko ba ri i, afaimọ ki wọn ma gbẹyin fun awọn Fulani onimaaluu ati ajinigbe yii lowo, ti wọn yoo ni ki wọn lọọ maa dọgbọn ra ilẹ lọwọ awọn ọba ti ijẹkujẹ ti wọ lẹwu yii. O ni wọn yoo maa ta ilẹ fun wọn, wọn o si ni i mọ pe RUGA lawọn n ta ilẹ fun, titi ti wọn yoo fi gba ilẹ to pọ rẹpẹtẹ kuro lọwọ wọn, ti yoo si di ọran si araalu lọrun nigbẹyin, nigba ti awọn ko ba ri ilẹ dako si mọ. Ọrọ ko ṣee fi si abẹ ẹnu sọ mọ ni asiko ti a wa yii, ọba to ba ya ajẹru bẹẹ yẹn, ki Togun ma fi orukọ bo o laṣiiri mọ, ko kọ orukọ ọba bẹẹ, ko si mu un lọ sọdọ awọn agbaagba Yoruba, wọn yoo mọ ohun ti wọn yoo ṣe si i. Ọrọ ọlọpaa tabi awọn agbofinro, tabi lẹta si ijoba apapọ ko ni i ran eleyii, nitori ẹyin iru ẹni bẹẹ ni awọn to fẹẹ ṣe wa laburu yoo wa. Amọ bi lẹta naa ba de ọdọ awọn agbaagba Yoruba, wọn yoo mọ ọna ti wọn yoo gba ti wọn yoo fi yọ iru ọba bẹẹ danu nipo, ti wọn yoo si le oniyẹyẹ eeyan naa kuro laafin. Bi nnkan ṣe le fun Yoruba to yii, ọba ti ko ba mọ ohun to n lọ, to ni oun ko si ri ẹni ti oun yoo lọọ ta ilẹ fun to jẹ awọn Fulani onimaaluu ni, iyẹn ki i ṣe ọrẹ awọn araalu rẹ, koda ko nifẹẹ wọn rara, ọta wọn ni. Nidii eyi, ki Ọgagun Togun ma duro mọ, ẹ fi orukọ wọn ranṣẹ sawọn agbaagba, wọn yoo si le wọn danu laarin ọjọ kekere. Awọn akinyẹyẹ ti wọn n ko ilẹkẹ ọdalẹ sọrun, awọn ọba onijẹkujẹ!

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.