Ẹ ẹ si yọ ọkunrin yii danu

Spread the love

Gomina ni Abdullahi Ganduje, Gomina ipinlẹ Kano ni. Ṣugbọn o fẹrẹ jẹ pe ko si gomina kan ti aṣiri ẹ tu saye lọwọ to bayii ri lati igba ti ijọba dẹmokiresi ti a wa ninu ẹ yii ti bẹrẹ ni bii ogun ọdun sẹyin. Gomina naa gba owo ẹyin ni. O n gba owo lọwọ awọn kọntirakitọ ti wọn ba gbe iṣẹ fun ni Kano. Bo ṣe n ṣe e ni pe bi ijọba rẹ ba fẹẹ gbe iṣẹ agbaṣe fun kọntirakitọ kan, oun yoo sọ fun awọn kọntirakitọ naa pe ki wọn fi owo toun kun un. Iyẹn ni pe nigba ti awọn kọntirakitọ ba sọ pe ọgọta Naira lawọn yoo gba fun iṣẹ ti awọn fẹẹ ṣe yii o, gomina yoo ni ki wọn ṣe owo naa ni ọgọrun-un, yoo si gba ogoji to le lori rẹ sapo ara rẹ bi wọn ba ti n sanwo naa fun awọn agbaṣẹṣe. Bẹẹ ni Gomina Ganduje ṣe n ji owo ori tutu, owo ori gbigbẹ gba, to n ji owo oniru, owo alata ko ni Kano to ti n ṣejọba. Bi ẹ ba si beere lọwọ rẹ, yoo ni oun n ṣiṣẹ fun gbogbo ilu ni, awọn oniranu kan yoo si maa pariwo lẹyin rẹ, wọn yoo maa jo kiri pe ko sẹni to ṣe daadaa fun ipinlẹ rẹ ju ọkunrin ole yii lọ. Inu lo bi awọn kan ninu awọn kọntirakitọ yii, ni wọn ba ya fidio ọkunrin naa nibi ti wọn ti n ko owo fun un, oun ko si mọ pe wọn gbe ẹrọ ayaworan naa sinu agbada ti wọn wọ, gbogbo bo ṣe n gbowo lọwọ wọn ni ẹrọ naa n ya fọto rẹ, fọto naa si ni wọn gbe han si gbogbo aye lori ẹrọ ayelujara. Ki i ṣe ẹẹkan tabi ẹẹmeji lo gba owo bayii, nitori fidio meji ọtọọtọ ni wọn gbe jade, oun lo si wa ninu rẹ, to n gba owo lọwọ awọn eeyan naa to n ko o sinu agbada. Awọn ile-igbimọ aṣofin ti gba ọrọ naa, wọn si n wadii ẹ lọ lọwọ, awọn kọntirakitọ ati awọn ti wọn ya fidio naa si ti jẹrii, wọn ni ole ni gomina, loootọ lo n gba owo lọwọ awọn. Ohun to tun waa n da awọn eeyan yii duro ti wọn ko yọ ọ danu ni ko ye ẹnikan. Wọn ni awọn oloṣelu kan ti n sare kiri pe ki wọn ma yọ ọkunrin naa, koda, awọn alagbara Aso Rock kan si ti dide pe ọmọ awọn daadaa ni Ganduje n ṣe. Ẹni ba n ṣe iru eleyii, Ọlọrun yoo mu oun naa. Bi ẹ ba ri ole to n ji owo araalu ko ti ẹ ba n fọwọ pa a lori, ti ẹ ni ko sewu, ti ẹ da a duro sipo, ko si ki ina Ọlọrun ma jo iru ẹni bẹẹ, nitori owo araalu lo n ji ko, owo to le din iya awọn mẹkunnu ku, owo to le din iku ojiji ati aisan rẹpẹtẹ ku ni ipinlẹ Kano ni Ganduje n ko sapo ara tirẹ nikan. Ẹ ma fọwọ bo ọrọ Ganduje mọlẹ! Ẹ ma fọwọ pa Ganduje lori. Ẹ tete le yẹyẹ danu! Mọla to n ji owo Mọla ko ni Ganduje, ẹni aburu ni!

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.