Ẹ ṣamin, Ọlọrun ma jẹ ki Naijiria bọ sọwọ Boko Haram o

Spread the love

Aṣofin kan wa ni ile-igbimọ aṣofin kekere ni ilu Abuja, Sanai Zoro lorukọ rẹ. Aṣofin yii sọrọ kan ni ọsẹ to kọja ninu ile-igbimọ nibẹ, ọrọ to yẹ ko ba gbogbo Naijiria lẹru ni. O ni oun ati awọn ẹlẹgbẹ oun kan lọ si awọn ilu kan ni ipinlẹ Borno ati Yobe, o ni ohun ti awọn ri ko dara. O ni ilẹ Hausa ti bajẹ o, awọn Boko Haram ti ba ilẹ naa jẹ pata. Zorro ni awọn adugbo kan wa ti awọn funra awọn foju ri, to jẹ awọn eeyan ti wọn wa nibẹ ko pe ọgọrun-un meji, bẹẹ ilu nla to ti ni bii ogoji ẹgbẹrun awọn eeyan ni wọn tẹlẹ. O ni yatọ si eyi, awọn agbegbe kan wa nibẹ to jẹ awọn Boko Haram ni wọn n ṣejọba nibẹ, ni tọsan-toru, awọn ni olori ijọba ibẹ, nitori gbogbo awọn eeyan ti awọn ara agbegbe naa dibo yan ni wọn ti sa lọ. O ni lọsan-an gangan lawọn Boko Haram yii maa n wọ awọn ilu ti wọn ba fẹẹ kọlu, ti wọn yoo si ko ounjẹ wọn, ti wọn yoo ji awọn ọmọbinrin wọn gbe, ti wọn yoo si sa lọ. O ni ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin ni wọn n ji gbe ti ẹnikẹni ko gbọ nipa wọn rara, eyi si fihan pe awọn Boko Haram naa n bimọ si i lojoojumọ ninu agbegbe ibẹ, bo ba si n lọ bo ṣe n lọ yii, agbegbe naa yoo di ti Boko Haram pata. Sani Zorro sọ pe gbogbo ọrọ ati ariwo ti ijọba Naijiria n pa lori ọrọ yii, ti awọn eeyan wọn n sọ pe awọn ti rẹyin awọn Boko Haram, o ni irọ buruku ni o, kaka ki wọn rẹyin wọn, wọn n gbilẹ si i ni. O ni awọn eeyan naa ko de itosi ibi ti awọn Boko Haram wa rara, Abuja ni wọn jokoo si ti wọn ti n sọ gbogbo ohun ti wọn n sọ. Akọkọ ni pe Sani Zorro to n sọrọ yii, ọmọ ilẹ Hausa ni. Lọna keji, ki i ṣe oun nikan lo lọ si agbegbe ti awọn Boko Haram wa yii, ile-igbimọ aṣofin lo ran igbimọ alabẹṣekele kan lọ sibẹ, iṣẹ ile-igbimọ aṣofin Naijiria ni wọn lọọ ṣe. Lọna kẹta, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Zorro. Eyi ja si pe ọkunrin naa ko le deede maa sọrọ lati ba ilẹ Hausa jẹ, nigba to jẹ ọmọ ibẹ ni, bẹẹ ni ko le deede sọ ohun ti ko ri, nigba ti ki i ṣe oun nikan lo lọ sibẹ, ko si le maa sọrọ ti yoo tabuku fun APC, nigba to jẹ aṣofin APC loun alara. Eyi fihan pe ododo ọrọ pọnnbele ni gbogbo ohun ti ọkunrin yii sọ. Ibẹru to wa nibẹ ni pe Sani ni bi ijọba Naijiria ba ṣe bii ẹni pe awọn ko mọ tabi awọn ko gbọ ohun to n ṣẹlẹ, tabi ti apa kan awọn eeyan Naijiria ba ro pe ọrọ yii ko kan awọn, ko le pẹ ko le jinna ti kinni naa yoo fi kuro ni ilẹ Hausa nikan, ti yoo si kaari gbogbo Naijiria, nitori o jọ pe imura awọn Boko Haram yii ni lati gba Naijiria pata, ki wọn si fi agbegbe yii ṣe ibugbe ati ile agbara wọn. Bi eleyii ba waa ṣẹlẹ, nibo ni a o gba! Nibo ni ọmọ Naijiria yoo gba! Nibo ni mẹkunnu ilẹ yii yoo gba! Kin ni yoo ṣẹlẹ si awọn ọmọde ati awọn obinrin wa! Kin ni yoo ṣẹlẹ si alaboyun ati awọn ọmọ-ọwọ! Kin ni yoo ṣẹlẹ si awọn arugbo ati awọn alailera! Ijọba Buhari, ọrọ yii ki i ṣe ọrọ ti a le maa fi ṣe oṣelu, ọrọ yii ki i ṣe ọrọ ere, ẹ dide kẹ ẹ gba wa lọwọ Boko Haram, ẹ ma jẹ ki wọn sọ Naijiria di orilẹ-ede ti yoo parẹ lawujọ awọn orilẹ-ede agbaye gbogbo!

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.