Ẹṣẹ aimọdi lo gbe mi dẹwọn, nibẹ ni mo si ti pade ẹni to fọna iṣẹ ole han mi

Spread the love

Florence Babaṣọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti ṣafihan ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Oyelakin Oyewumi, atawọn ikọ ẹlẹni-mẹrin rẹ ti wọn jọ n digunjale nipinlẹ Ọṣun ati nipinlẹ Ondo, bẹẹ ni wọn tun mu awọn ọrẹbinrin rẹ meji.

Gẹgẹ bi kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Abiọdun Ige, ṣe ṣalaye, lati ọdun to kọja ni wọn ti n dọdẹ Oyelakin to jẹ olori awọn adigunjale naa, ọwọ ti tẹ diẹ lara wọn tẹlẹ, ti wọn si ti foju bale-ẹjọ, ko too di pe ọwọ pada tẹ Oyelakin.

Ige sọ siwaju pe ọkọ Toyota Corolla ni awọn adigunjale naa fẹran lati maa ji gbe, wọn si ti ṣiṣẹ ọwọ wọn laṣeyọri lẹẹmẹjọ kọwọ too tẹ wọn. Awọn ọmọlẹyin Oyelakin to ku ni Adebayọ Yẹmi, Adeyẹye Ọpẹyẹmi, Ọlawale Munirudeen, wọn si tun mu Sunday Ogbemudia ti wọn n ta awọn mọto naa fun.

Kọmisanna yii ni awọn ọlọpaa ẹka Special Anti-Robbery Squad ni wọn mu Oyelakin atawọn ikọ rẹ, mọto marun ọtọọtọ ni wọn si ri gba lọwọ wọn.

Nigba ti Oyelakin n ba Alaroye sọrọ, o ni iṣẹ awọn ti wọn maa n tun nnkan eelo to n lo ina inu ile ṣe (electrician) loun kọ ni kete toun kuro nileewe, oun si n ṣiṣẹ naa niluu Ifẹtẹdo, nijọba ibilẹ Guusu Ifẹ.

“Lọjọ kan, ọrẹ mi ti a jọ n gbenu ile lọọ jale ni ṣọọbu awọn alasọ, o si sa lọ, idi niyẹn tawọn ọlọpaa fi mu mi, lẹyin atotonu fun ọpọ ọjọ ni kootu, adajọ ni mo jẹbi, wọn si ju mi si ẹwọn ilu Ileefẹ lori ẹsun ole jija, bi mo ṣe dero ọgba ẹwọn niyẹn.

“Lọgba ẹwọn Ileefẹ ni mo ti ṣalabaapade ọkunrin kan, o sọ fun mi pe ọkọ loun n ta, o si sọ bi mo ṣe le maa ji ọkọ ọlọkọ gbe pẹlu idaniloju pe oun yoo maa ran mi lọwọ lati tun wọn ta, ni kete ti owo mi ba si ti pọ loun yoo ba mi san ọna lati kọja siluu oyinbo.

“Inu mi dun, a si gba adirẹsi ara wa, latibẹ naa ni mo si ti pinnu pe mọto ni ma a maa ji gbe ni kete ti mo ba ti jade lọgba ẹwọn. Bi mo ṣe jade ni mo da ẹgbẹ adigunjale temi silẹ loṣu kọkanla, ọdun to kọja, a si ti lọ soko ole lẹẹmẹjọ ko too di pe ọwọ tẹ wa.

“Mọto Toyota Corolla eleyii ti owo wọn jẹ miliọọnu meji naira la maa n ji gbe, ṣugbọn ẹẹdẹgbẹta Naira la maa n ta wọn. Meji ti a kọkọ ji, mo gbe e lọ sọdọ ọkunrin ti mo ba pade lẹwọn, ṣugbọn ko fun mi lowo, idi niyẹn ti mi o fi lọ sọdọ rẹ mọ.

“Inu ọgba ẹwọn naa ni mo ti ṣalabapade Adeyẹye Ọpẹyẹmi ko too di pe mo mu un mọra lati maa ba mi ṣiṣẹ. Sunday Ogbemudia lo maa n ba wa ta awọn ọkọ yẹn n’Ibadan, a si ti ṣiṣẹ daadaa lagbegbe Ọrẹ, nipinlẹ Ondo, Gbọngan ati Iwo, nipinlẹ Ọṣun. 

“Ilu Ibadan lawọn ọlọpaa ti ri emi atawọn ọrẹbinrin mi mejeeji mu, ṣugbọn ko si eyi to mọ pe iṣẹ adigunjale ni mo n ṣe laarin awọn mejeeji. 

Ninu iroyin mi-in, ọwọ tun tẹ Lasisi Isiaka, ẹni ọdun mọkandinlogoji. Ọkada jiji ni iṣẹ tiẹ, awọn nnkan ija oloro lo si fi maa n gba ọkada lọwọ awọn to ba da lọna.

Lẹyin ti wọn mu un lo jẹwọ pe Samuel Johnson ati Isiaka Fatai ni wọn maa n ba oun ta awọn ọkada toun ba ti ji gbe. Nigba tawọn ọlọpaa de ile awọn mejeeji, wọn ba ọkada marun-un lakata Samuel, wọn si gba mẹta lọwọ Fatai.

Kọmisanna ṣalaye pe ni kete tiwadii ba ti pari lori ọrọ wọn ni wọn yoo foju bale-ẹjọ lati le jẹ ẹkọ fawọn ọdọ ti wọn ko fẹẹ fọwọ ṣiṣẹ rara, afi ki wọn nawo.

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.