Ẹgbẹ APC ko rẹsẹ walẹ nipinlẹ Ọṣun ati Ọyọ mọ- Ọtẹgbẹyẹ

Spread the love

Oludije dupo gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Providence People’s Congress (PPC), Pasitọ Taiwo Ibiyẹmi Ọtẹgbẹyẹ, ti ṣapejuwe idibo gomina to waye ni ipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii eyi ti ko mọyan lori, ati pe idibo ọhun ti fi han pe awọn ara ipinlẹ naa ko gba ti ẹgbẹ APC mọ, bẹẹ ni nnkan yoo buru fun ẹgbẹ naa ninu idibo ipinlẹ Ọyọ lọdun to n bọ ju bẹẹ lọ.

Ọtẹgbẹyẹ sọrọ yii ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin wa l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, lẹyin to jawe olubori ninu idibo abẹle ti awọn aṣoju ẹgbẹ PPC ipinlẹ Ọyọ di lati yan awọn oloye atawọn ti yoo dije ipo oṣelu lọlọkan-o-jọkan lorukọ  ẹgbẹ naa ninu idibo gbogboogbo ọdun  2019

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Bi oludije lorukọ ẹgbẹ APC ko ṣe wọle lati ọjọ Satide ti wọn ti kọkọ dibo yẹn fi han pe ẹgbẹ yẹn ko rẹsẹ walẹ ni ipinlẹ Ọṣun mọ. Ta a ba si yọwọ owo ati agbara kuro, to jẹ pe wọn ni lati ṣe idokoowo

oṣelu pẹlu Omiṣore to dije dupo yẹn lorukọ ẹgbẹ SDP, APC iba tí wọle atundi ibo ti wọn di l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yẹn.

“Ohun to mu ki nnkan ri bayii fun APC nipinlẹ Ọṣun ninu idibo yẹn, o daju pe nnkan ko le ṣẹnuure fun ẹgbẹ yẹn ni ipinlẹ Ọyọ naa, nitori awọn ọmọ ẹgbẹ APC to ti binu kuro ninu ẹgbẹ yẹn ni ipinlẹ yii ki i ṣe kekere, bẹẹ lawọn mi-in tun maa fi ẹgbẹ yẹn silẹ lẹyin ti wọn ba dibo abẹle wọn lati fa awọn oludije kalẹ tan.

“Nnkan to tun maa koba wọn ni ipinlẹ yii ni pe wọn o le ri ọlọpaa to to ẹgbẹrun lọna ogoji (40,000 ) lo ninu idibo ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe l’Ọsun, nitori bi idibo ba ṣe n waye ni Ọyọ naa ni wọn yoo di i ni ọpọlọpọ ipinlẹ lorileede yii lọjọ kan naa. Nitori naa, awọn APC ko le ri owo ati agbara dibo ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe l’Ọṣun. Ati pe awọn ara ipinlẹ yii ko ni i dibo fun awọn ẹgbẹ to ti tan wọn jẹ ṣaaju, ẹgbẹ to maa mu ayipada rere ba ilu bii tiwa ni wọn maa dibo fun.”

Diẹ ninu awọn ti wọn wọle idibo gẹgẹ bii adari ẹgbẹ PPC ipinlẹ Ọyọ ni: Ọgbẹni Taiwo Arẹmu Oduọla (Alaga), O. Dairo (Igbakeji Alaga), Ọnarebu Alabi Arẹwa (Akọwe), Adeọla Olootu (Akapo), Gbolagade Aderonmu (Akọwe owo). Rotimi Oduniyi (Alukuro). Abilekọ Lọla Oyedepo ni adari awọn obinrin ninu ẹgbẹ naa.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.