Ẹgbẹ ADP ipinlẹ Ọyọ rọ alaga wọn loye, wọn lo fẹẹ ba ẹgbẹ awọn jẹ

Spread the love

Alaga ẹgbẹ oṣelu Action Democractic Party (ADP), ni ipinlẹ Ọyọ, Oloye Fọlaranmi Owolabi, ti jokoo le eṣo pẹlu bi igbimọ alaṣẹ apapọ ẹgbẹ ọhun ṣe rọ ọ loye, wọn lo n huwa to le ba ẹgbẹ awọn jẹ.

 

Iwe irọniloye ti wọn fi sọrọ yii di mimọ ni igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Lati Arowoṣaye, fọwọ si, to si fi ranṣẹ si alaga ti wọn rọ loye naa lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

 

Ẹsun mẹfa ọtọọtọ ti wọn fi kan an lo ni i ṣe pẹlu owo ẹgbẹ ati bo ṣe n ṣaṣepọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu mi-in. Pẹlu eyi, wọn gba pe gbogbo aṣiri ẹgbẹ ADP lọkunrin naa ti tu si awọn alatako wọn lọwọ tan pata.

 

ALAROYE gbọ pe alaga ADP yii ko yọju si ibi awọn nnkan pataki ti wọn n ṣe ninu ẹgbẹ ọhun mọ, aarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC atawọn ADC lo si ku ti wọn ti n gburoo ẹ lọpọlọpọ igba lasiko yii.

 

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu lẹta ọhun, eyi ti wọn fi ẹda ẹ ranṣẹ sawọn oniroyin n’Ibadan, “nitori awọn ẹsun ta a fi kan ọ (Owolabi), wọnyi, igbimọ alaṣẹ apapọ ẹgbẹ yii ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣewadii nipa ọrọ rẹ. Gbogbo dukia ẹgbẹ to ba wa lọwọ rẹ la si fẹ ki o ko silẹ kiakia titi digba ti igbimọ oluwadii naa yoo fi pari iṣẹ wọn.”

 

A ko ti i gbọ tẹnu Oloye Owolabi lori ọrọ yii nitori akọroyin wa ko ti i lanfaani lati ba oloṣelu ọmọ ijọba ibilẹ Afijio, lagbegbe ilu Ọyọ, naa sọrọ titi ta a fi kọ iroyin yii pari.

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.