Ẹ le Buhari lọ, oun lo sọ Naijiria di ilu to toṣi ju lagbaaye- Atiku

Spread the love

Pẹlu bi eto ipolongo idibo apapọ ilẹ yii ṣe bẹrẹ lọsẹ to kọja, oludije fun ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), Alhaji Atiku Abubakar, ti ṣapejuwe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), gẹgẹ bii ẹgbẹ to kun fun kikida opurọ, to jẹ pe niṣe lo yẹ ki awọn ọmọ orileede yii fi ibo le wọn danu lasiko idibo apapọ ọdun 2019.

 

Atiku sọrọ yii ni gbọngan Mapo, n’Ibadan, nigba ti ọkọ ipolongo ẹ gunlẹ si ipinlẹ Ọyọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.

 

O ṣalaye pe,  “Buhari gbọdọ lọ, irọ apakuakata gbọdọ dopin. Lati ọdun 1999 ti eto iṣejọba awa-ara-wa ti bẹrẹ, asiko iṣejọba PDP lo ti i san wa ju. lọdun 2015, awọn opurọ de lati tan wa, wọn ni awọn maa pese iṣẹ, aabo ati owo, a si gba wọn gbọ.

 

“Ṣugbọn dipo ki wọn pese iṣẹ, nnkan bii miliọnu mejila eeyan lo ti padanu iṣẹ wọn lasiko iṣejọba wọn (APC). Dipo ki wọn pese aabo, niṣe leto aabo tubọ n mẹhẹ si i, ti ọpọ eeyan si n ku lojoojumọ. Wọn ni awọn maa tun eto ọrọ aje wa ṣe, ṣugbọn ni ilẹ toni to mọ, awọn oluwadii ti fidi ẹ mulẹ pe Naijiria ni orileede to toṣi ju lagbaaye. Ṣe ohun to yẹ wa ni Naijiria niyẹn?”

 

Atiku, ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ orileede yii sọ siwaju pe “gbogbo aye lo mọ pe mo ti dari eto ọrọ aje to dara julọ lorileede yii sẹyin. Nnkan ta a tun le pada ṣe ni. Awọn ọlọpọlọ pipe eeyan ni mo maa ko jọ lati dari eto ọrọ aje ilẹ yii.

 

“Ka ṣe atunto nikan lohun to le pé wa ju lorileede yii. Mo ṣeleri pe lẹyin oṣu mẹfa ti mo ba bẹrẹ ijọba temi, ma a bẹrẹ eto atunto Naijiria.”

 

Bakan naa ni Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba nilẹ yii, Sẹnitọ Bukọla Saraki, ran ni leti pe ni gbọngan Mapo, n’Ibadan yii naa ni Aarẹ orileede yii, Muhammadu Buhari, ti ṣeleri eto aabo, ipese iṣẹ ati eto ọrọ aje to fẹsẹ mulẹ, ṣugbọn ti ko mu ọkankan ṣẹ ninu gbogbo ẹ, to jẹ pe iya lo tun fi n jẹ awọn araalu pẹlu bi ohun gbogbo ti ṣe di ọwọngogo lọja, ti ati-jẹ ati-mu si di nnkan fun mẹkunnu.

 

Ninu ọrọ tiẹ, Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọmọọba Uche Secondus, ṣapejuwe iṣejọba ẹgbẹ APC to wa lode bayii gẹgẹ bii eyi ti ko bikita nipa awọn araalu pẹlu bi wọn ṣe n paayan ni ipinlẹ Benue, ṣugbọn ti Aarẹ Buhari sọ pe oun ko mọ pe nnkan kan n ṣẹlẹ gẹgẹ bo ṣe kọkọ sọ pe oun ko mọ pe awọn Boko Haramu ji awọn omọọleewe gbe ni Dapchi nigba kan.

 

Secondus, ẹni to royin ijọba Buhari gẹgẹ bii eyi to n bo ọpọlọpọ iwa ibajẹ mọ abẹ aṣọ rọ awọn ọmọ orileede yii lati fi ibo wọn le ijọba naa danu lasiko idibo aarẹ ọdun 2019.

 

Peter Obi to jẹ oludije fun ipo igbakeji aarẹ ninu idibo ọdun to n bọ pẹlu awọn gomina ilẹ Yoruba nigba kan ri bii Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla (Ọṣun), Ọtunba Gbenga Daniel (Ogun) ati Ayọdele Fayoṣe tipinlẹ Ekiti wa lara awọn agba oṣelu to kopa ninu eto ipolongo ibo ọhun, to fi mọ Sẹnetọ Ademọla Adeleke to dije dupo gomina ipinlẹ Ọṣun laipẹ yii.

 

Bakan naa la ri Ẹnjinia Ṣeyi Makinde to n dije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Buruji Kashamu to n dije fun ipo gomina ipinlẹ Ogun lorukọ ẹgbẹ ọhun atawọn agba oṣelu ọmọ ẹgbẹ PDP min-in bii Alhaji Yẹkini Adeọjọ, Alagba Wọle Oyelẹsẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

 

 

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.