Dokita obinrin akọkọ ni Naijiria, Abimbọla Awoliyi

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami ▶️ to wa nisalẹ yii.

Nigbakigba ti awọn onpitan Naijiria ba jokoo lati royin awọn obinrin pataki ninu iṣẹ iṣegun oyinbo, ko si bi wọn ṣe fẹẹ yọ ọrọ Dokita Abimbọla Awoliyi sẹyin o, tori oun gan-an ni ọmọ Naijiria akọkọ lobinrin ti yoo di oniṣegun oyinbo lorilẹ-ede rẹ. 

A bi arabinrin Abimbọla sipinlẹ Eko lọdun 1910. David Akerele lorukọ baba rẹ, Rufina Akerele si ni iya rẹ n jẹ. Ilu Eko yii naa lo ti bẹrẹ eto ẹkọ rẹ ni St. Mary’s Catholic School. Lẹyin to ṣetan nibẹ lo tẹsiwaju ni ile-ẹkọ girama Queens College kan naa to wa ni Yaba. Bo ṣe n pari ẹkọ girama yii ni o gba ile-ẹkọ giga University of Dublin lọ, ibẹ lo si ti kawe gboye Degree akọkọ ninu imọ iṣegun oyinbo. 

Nile-ẹkọ giga Dublin yii, ipo awọn ti esi idanwo wọn daa julọ ni wọn to o si, eyi ti wọn pe ni First Class Honors. O gba awo fun iṣẹ apoogun, awọn oyinbo funra wọn si kọ ọ sinu esi idanwo rẹ pe ayasọtọ ni imọ rẹ nipa ẹya ara eniyan nibi to daa de.

Sibẹ Abimbọla ko duro, o ṣi tun tẹsiwaju ninu imọ iṣegun oyinbo yii ni Royal College of Physicians, Royal College of Obstetricians and Gynaecology ati Royal College of Paediatrics and Child Health. 

Ẹyin to pari awọn ẹkọ yii lo ṣe too pada si Naijiria gẹgẹ bii oṣiṣẹ eleto ilera to n mojuto ọrọ nipa ile ọmọ obinrin (Gynaecologist) nileewosan Massey Street Hospital to wa l’Ekoo. Ipo oniṣegun kekere lo fi bẹrẹ titi to fi di ọga patapata nileewosan naa lati ọdun 1960 titi di 1969. Lọdun 1962 ni ileeṣẹ eto ilera Naijiria yan an gẹgẹ bii agba akọṣẹmọṣẹ ninu imọ nipa ile ọmọ obinrin (Gynaecologist) ati igbẹbi (Obstetrician). 

Oriṣiiriṣii ami-ẹyẹ lo gba nigba aye ẹ, lara awọn ami-ẹyẹ to gba ni MBE (Most Excellent Order of the British Empire), OFR (Officer of the Order of the Federal Republic of Nigeria). Nidii iṣẹ rẹ naa ni wọn ti fi oye Iya Abiye Gbogbo Eko da a lọla, Alaafin Ọyọ naa si fi i jẹ Iyalaje ilu Ọyọ. 

Yatọ si iṣẹ iṣegun oyinbo to mumu lọkan rẹ yii, Abimbọla tun na ọwọja rẹ sidii iṣẹ agbẹ. O ni oko adiẹ silu Agege, nibi ti wọn ti n sin awọn ẹranko oniyẹ, ti wọn si gbin igi ọsan si rẹkẹrẹkẹ. 

Elizabeth Awoliyi ni oludasilẹ ati aarẹ akọkọ ẹgbẹ obinrin ti wọn pe ni National Council of Women Societies ẹka Eko. Oun si ni ẹni keji ti yoo di aarẹ gbogbo fun ẹgbẹ naa lọdun 1964.

Ifarasin ati aṣeyọri Abimbọla lẹnu iṣẹ to yan laayo yii ko ni ko padanu aṣeyọri ti ọpọ obinrin maa n ṣe. Abimbọla lọkọ, bẹẹ lo si bimọ. Dokita S. O. Awoliyi lo fẹ, wọn si bimọ meji fun ara wọn, ọkunrin kan ati obinrin kan. 

Lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an ọdun 1971 ni Abimbọla jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọta (61). 

Ni iranti rẹ ni wọn da ileewosan Dr. Abimbọla Awoliyi Memorial Hospital silẹ. 

Abimbọla jẹ ọkan ninu awọn akọni obinrin to lo igbesi aye rẹ lati fi ṣiṣẹ gbe ogo ilẹ Yoruba ati orilẹ-ede Naijiria ga ni.

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.