Dẹrẹba ni Emmanuel, ṣugbọn ibọn oloju meji ni wọn ba lọwọ ẹ ni Badagry

Spread the love

Adefunkẹ Adebiyi

Iṣẹ ọkọ wiwa lawọn eeyan mọ ọkunrin kan, Emmanuel John, mọ ni Badagry, nipinlẹ Eko. Ṣugbọn lọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun yii, tawọn eeyan n ṣayẹyẹ dẹmokiresi ni Naijiria, ibọn oloju meji lawọn ọlọpaa ba lọwọ Emmanuel lai niwee aṣẹ, ohun ti wọn mu un fun niyẹn.

Ẹni ọdun mejilelọgbọn ni Emmanuel tọwọ ba yii, oju ọna marosẹ Badagry ni wọn ti mu un pẹlu ibọn ilewọ oloju meji naa. Yatọ sibọn ọhun, ọta ibọn meji tun wa ninu apo ẹ, bẹẹ ko si lansẹnsi kankan lọwọ dẹrẹba to n wakọ yii, ko si si idi kankan fun un lati maa gbe ibọn rin bi wọn ṣe ba a lọwọ   ẹ.

Ẹsun ti ko le ṣalaye kankan nipa ẹ yii naa lawọn ọlọpaa ka si i lẹsẹ ni kootu Majisireeti to wa n’Ikẹja, nibi ti wọn gbe e wa l’Ọjọruu to kọja yii, ti wọn ti ni ko waa ṣalaye idi to fi n gbe ibọn rin lojumọmọ lai ni iwe aṣẹ fun un.

Adajọ Adegun ni bi ko ba ni ero ibi lọkan, tabi ko si jẹ pe boju-boju lasan niṣẹ awakọ to loun n  ṣe yii, Emmanuel ko ni i maa gbe ibọn rin kiri ilu, nigba to jẹ ofin ilẹ wa ko faaye gba iru ẹ. Nidii eyi, ko gba ipẹ olujẹjọ yii, alaye rẹ kankan ko si ṣiṣẹ pẹlu.

Oju ẹsẹ lo paṣẹ pe ki wọn maa gbe Emmanuel lọ sọgba ẹwọn Kirikiri, ibẹ ni yoo wa titi di ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, nigba ti igbẹjọ rẹ yoo maa tẹsiwaju.

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.