Dẹrẹba dero kootu l’Abẹokuta, wọn lo fi miliọnu kan owo ọga ẹ ralẹ ati mọto tuntun

Spread the love

Ni kootu Majisireeti to wa n’Iṣabọ, l’Abẹokuta ni Dẹrẹba kan, Ọgbẹni Abọlade Ọpẹoluwa Jibọna, ti n kawọ pọnyin rojọ bayii. Owo ọga ẹ, Abilekọ Magret Ibiṣọla Oyebolu, ni wọn lo fọgbọn alumọkọroyi ko, to si fi ralẹ ati mọto tuntun.

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni wọn foju Abọlade han ni kootu naa, ẹsun mẹta ti wọn si ka si i lẹse ni pe lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, o lo ọna igbalode ti wọn fi n fowo ṣọwọ (Transfer), o si ko owo to le ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna aadọta Naira, o le ẹẹdẹgbẹta (1,053, 500), lati akaunti mama to ti le lọgọrin ọdun naa, iyẹn Abilekọ  Oyebolu.

Ẹsun keji ni pe o fi owo naa ralẹ pulọọti kan l’Orile-Ibara, Abẹokuta, bẹẹ lo tun ra mọto ayọkẹlẹ Nissan Almera ti nọmba ẹ jẹ JBD 790 XA, ẹgbẹrun lọna irinwo ni wọn lo ra mọto naa.

Ẹjọ kẹta ti Ọpẹoluwa jẹ ni kootu ni ti foonu rẹ ti i ṣe Nokia 3310, to lo lati taari owo iya naa lati inu aṣunwọn 0032604291, Banki GT, to si taari rẹ sọdọ ara tiẹ lori ibi ti mama naa maa n sanwo oṣu rẹ si.

Ẹgbẹrun lona ọgbọn Naira ni Ọpẹoluwa n gba loṣu, ṣugbọn laarin oṣu kẹrin ọdun si ọsu keje ti iya agba naa fi fura pe o n ji oun lowo, owo to le ni miliọnu ti wọ akaunti dẹrẹba yii, o si ti n ṣe faaji ara rẹ lọ.

Nigba to n ṣalaye ara rẹ, Abọlade sọ pe ọkọ ọga oun to ti dagba gidi lo maa n fowo ṣọwọ si akaunti oun. O ni ti baba naa ba fẹẹ ran oun niṣẹ nigba mi-in, o le taari ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira si akaunti oun, oun yoo si lọọ ba a jiṣẹ naa.

Lori mọto to ra, o loun ti ni mọto koun too maa wa mama, koda, o maa n to ẹgbẹrun lọna aadọta toun maa n ri loṣu, pẹlu bo ṣe jẹ pe san an diẹ-diẹ loun sanwo ọkọ naa pada to (Instalmental).

O ni ṣugbọn nitori ati maa rowo gbọ bukaata iyawo atọmọ oun lai ni i sanwo pada fẹnikẹni mọ loun ṣe lọọ gbaṣẹ dẹrẹba alaadani lọdọ Mama Oyebolu. O loun ko ji wọn lowo ra mọto, oun ko si ralẹ kankan.

Agbefọba Famous Edigbue to ṣoju ijọba beere lọwọ ẹ pe ṣe o ṣee ṣe keeyan fiṣẹ ẹlẹẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun silẹ, ko si waa lọọ gba ti oni ẹgbẹrun lọna ọgbọn pere. O ni ọgbọn ati ja mama agba naa lole bii eyi to n jẹjọ ẹ yii ni Ọpẹoluwa da to fi gbaṣẹ naa, ṣugbọn ko le bọ nibẹ, nitori ofin ipinlẹ Ogun ko faaye gba iwa ole bii eyi to hu yii.

Abọlade ti wọn fẹsun kan loun ko jẹbi, ohun to ṣẹlẹ loun ṣalaye yẹn.

Adajọ agba Aliu Ṣonẹyẹ to gbọ ẹjọ naa sun igbẹjọ rẹ siwaju di ọjọ keje ati ikẹsan-an, oṣu kin-in-ni, ọdun 2019.

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.