Dele Belgore kede erongba rẹ lati dupo gomina labẹ APC

Spread the love

Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Kwara labẹ asia ẹgbẹ ACN ninu eto idibo ọdun 2011, Amofin Agba Mohammed Dele Belgore, ti kede erongba rẹ lati dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC lọdun to n bọ.

Belgore nireti wa pe ẹgbẹ APC fẹẹ fa kalẹ, nitori ipa to ti ko ninu eto idibo to kọja, nibi to ti dije dupo gomina.

Lasiko to n ba awọn alatilẹyin rẹ sọrọ niluu Ilọrin lopin ọsẹ to kọja, Belgore sọ pe asiko ti to bayii ti ipinlẹ Kwara yoo gba ipo rẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn ipinlẹ to n lewaju.

O gboṣuba fun awọn alatilẹyin rẹ fun bi wọn ṣe n pongbẹ iṣejọba rere nipinlẹ Kwara.Ọkunrin naa sọ pe, ‘lọwọlọwọ bayii, ipinlẹ wa ṣi wa nisalẹ ninu idagbasoke ọrọ-aje, bo tilẹ jẹ pe o ti pẹ ti wọn ti da a silẹ. Erongba wa ni lati jẹ ko wa laarin awọn ipinlẹ to ṣiwaju nipa idagbasoke ati ọrọ-aje.

“Mo dupẹ lọwọ yin tẹ ẹ ṣi duro fun iṣejọba rere. Mo n lo asiko yii lati sọ fun yin pe mo ti gba fọọmu lati dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ wa, APC”.

O ni o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pe awọn adari nipinlẹ Kwara ti sọ awọn araalu di ẹru, to si jẹ owo araalu ni awọn eeyan perete kan fi n ṣe ọla, ti wọn si n pọnla lai ka iya to n jẹ awọn araalu si.

“Ọpọlọpọ awọn ọmọ wa lo kawe, ṣugbọn o jẹ ibanujẹ ọkan pe wọn ko ri iṣẹ ṣe. Awọn ileewosan ijọba nipinlẹ Kwara ti di pakute iku, nitori aisi itọju ati awọn ohun eelo to peye nibẹ. O da mi loju pe ẹyin naa ti le ni iriri ohun to n ṣẹlẹ ni awọn ileewosan yii. Bẹẹ la n ka a ninu iwe iroyin pe owo to n wọle labẹle si apo ijọba Kwara ti pọ si i, sibẹ, a ko mọ ohun ti wọn fi n ṣe”.

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.