Dariye ti bẹwu iyi silẹ, agbada ẹwọn lo ko si

Spread the love

Ọdun mẹrinla ni yoo fi ṣẹwọn. Dariye ni o, Joshua Dariye, gomina ipinlẹ Plateau tẹlẹ. Owo gidi lo ko jẹ lasiko to fi n ṣejọba. Bi ẹ ba ranti ọrọ gomina yii, oun ni wọn mu nigba kan ni ilu oyinbo, ti wọn lo ko owo buruku kan wa sọhun-un, lo ba jabọ kuro lọwọ wọn, lo sa wa sile, ọrọ naa si da itiju ba wa. Ijọba Ọbasanjọ ṣeto wọn yọ ọ nipo gomina nitori ọrọ naa, ṣugbọn awọn adajọ da a pe ko pada si ipo naa, o si ṣejọba rẹ pari lọdun 2007. Ati ọdun naa lo ti n jẹ ẹjọ yii, ko too waa di lọsẹ to kọja yii ti wọn kangi mọ ọn nimu. Nigba ti wọn yẹ ẹ ni idajọ lile naa, o bu sẹkun, koda, o bẹbẹ pe ki wọn ṣaanu oun. Ṣugbọn aanu wo ni wọn fẹẹ ṣe ẹni to wa nipo gomina to n jale, to si ko owo ilu jẹ to bẹẹ yẹn. Bo ṣe di pe nigba ti wọn ju u sẹwọn, gbogbo awọn jiipu nla nla to ko wa ko le ṣe e lanfaani, nitori wọn ko jẹ ko wọ inu rẹ, mọto ṣaalaaake awọn agbofinro ni wọn rọ ọ wọ, bo ṣe dero ẹwọn niyẹn. Iru eleyii daa, o daa gan-an ni paapaa. Bi awọn oloṣelu ba n ṣe bayii ṣẹwọn, koda, ko jẹ ogun ọdun ni wọn fi ṣẹjọ ọhun, yoo jẹ ikilọ fawọn ti wọn ba wa nipo, wọn yoo mọ pe wọn le yẹ iwe wọn wo lọla kan. Awọn gomina atijọ bẹẹ ti wọn n rin kiri ilu, ki wọn tete ṣe idajọ awọn naa, ki oju afẹfẹ oṣelu ilẹ yii le mọ, ki awọn ọjẹlu le faaye silẹ fun awọn oloṣelu to fẹẹ ṣe araalu lanfaani, ko ma jẹ kidaa awọn ole to kungboro yii nikan ni a oo maa ri nile ijọba, tabi nile-igbimọ aṣofin. Ẹ jẹ rọra maa kowo jẹ o, Banjokoo n bọ waa da yin jokoo sọgba ẹwọn, nibi ti ẹ o ti lo pupọ ninu aye yin. Ẹyin alailojuti, ọmọ ole gbogbo!

(32)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.