Dapọ Abiọdun fọwọ sọya, o ni Amosun yoo ṣe toun gbẹyin ni

Spread the love

Ondije dupo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun, ti fọwọ sọya pe toun ni Gomina Ibikunle Amosun yoo ṣe gbẹyin, o ni Amosun yoo nawọ oun soke gẹgẹ bii aayo ẹgbẹ Onigbaalẹ.

Ọjọ Iṣẹgun to kọja yii ni Dapọ Abiọdun sọrọ naa nile rẹ to wa ni Ipẹru-Rẹmọ, nigba to pe ipade oniroyin lati kede igbakeji ẹ, Abilẹkọ Nọimọt Salakọ Oyedele, ati lati sọ awọn eto to ni lọkan faraalu, bi wọn ba fibo gbe e wọle lọdun to n bọ.

Ondije dupo yii ṣalaye pe ija lo de lorin dowe laarin oun ati Amosun, o ni awọn ija abẹle si ni, ti yoo tan laipẹ, nitori idibo ti wọle tan, ipolongo si ti bẹrẹ. O ni ẹni to wa lori aleefa lọwọ ni yoo fa ẹni to fẹẹ wọbẹ le araalu lọwọ laipẹ.

Nigba to n sọrọ lori igbakeji ẹ to jẹ obinrin, Dapọ Abiọdun ṣalaye pe oun yan obinrin nitori oun mọ bi wọn ṣe pataki to. O ni obinrin lo pọ ju ninu awọn ondibo.

Ọmọ Ado-Odo-Ọta ni obinrin dudu giga to fi ṣe igbakeji yii, Abiọdun si ṣalaye pe igbakeji gomina ko ti i jade lati Iwọ-Oorun Ogun ri (Ogun West), ti obinrin naa ti wa, iyẹn loun ṣe yan an latọdọ wọn, bo tilẹ jẹ pe ọmọ Ogun East, Ila-Oorun Ogun loun ni toun.

Lori awọn ohun ti yoo ṣe faraalu, Dapọ ni gbogbo ẹka loun yoo fọwọ ba, latori ina mọnamọna, ati omi ẹrọ ti yoo de awọn igberiko gbogbo. Dapọ ni oun yoo maa ya awọn obinrin oniṣowo lowo lati fi taja, iṣẹ ọgbin, ẹkọṣẹ ọwọ ati ipese epo pẹlu ajọṣepọ NNPC, gẹgẹ bi gbogbo eeyan ṣe mọ pe ọga elepo loun yoo jẹ oun logun.

Ohun ti Dapọ Abiọdun sọ pẹlu idaniloju pe Amosun yoo ti oun lẹyin yii ni ko ti i fi gbogbo ara jọ pe yoo ri bẹẹ ṣa, nitori Gomina Ibikunle Amosun ti sọ gbangba pe bo tilẹ jẹ pe oun ko ni i kuro ninu APC, ṣibẹ, oun ko ni i ṣatileyin fun ondije dupo gomina ti wọn fa kalẹ, oun yoo ṣiṣẹ tako o ni.

Ipade meji ni wọn pe  niluu Eko lọsẹ to kọja yii, lati pẹtu si aigbọra ẹni ye to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ APC, paapaa nipinlẹ Eko ati Ogun.

Gomina Akinwunmi Ambọde ati ojugba ẹ lati ipinlẹ Borno, Kashim Shettima, ni wọn ṣe kokaari ipade akọkọ l’Ọjọruu, nile ijọba Eko to wa ni Marina.

Bi ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ APC si ti pọ nibẹ to, Amosun ko yọju ni tiẹ, bẹẹ lawọn ọmọ ẹyin rẹ naa ko si nibẹ.

Ipade keji ni eyi ti wọn kuku gbe lọ sile Amosun to wa n’Ikẹja, l’Ọjọbọ ti i ṣe ọjọ keji ipade akọkọ. Ipade ti wọn tilẹkun mọri ṣe yii ni Gomina Amosun ba wọn darapọ mọ, nibi ti Ambọde ati Sanwo-Olu naa wa, pẹlu Kashim Shettima, ohun ti gbogbo ẹ si da le lori naa bi Amosun yoo ṣe yi ipinnu ẹ pada, ti yoo ṣatilẹyin fun Dapọ Abiọdun, ti yoo si gbagbe nipa Adekunle Akinlade to tori ẹ kọyin si ondije APC funpo gomina nipinlẹ Ogun.

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.