Chinenye pa ọmọ tẹnanti ẹgbẹ rẹ l’Ekoo, o ni baba rẹ lo ba ile ọmọ oun jẹ.

Spread the love

Iwa ilara ti ko ọmọbinrin Ibo kan, Chinenye Ndubuife, si wahala nla bayii, nitori niṣe lo wo sunsun, to si ṣe bẹẹ ṣeku pa Wisdom, ọmọ tẹnanti ẹgbẹ rẹ, Ọgbẹni Promise Samuel. Lẹyin naa lo si gbe oku rẹ pamọ sinu ṣalanga.

Chinenye, ọmọ bibi ipinlẹ Anambra, ti wa ni teṣan ọlọpaa Tolu, l’Apapa, niluu Eko. Gẹgẹ bi alaye ti awọn ọlọpaa ṣe, Chinenye lo ranṣẹ pe ọmọ ọdun meji naa to n gbe pẹlu Promise. Nigba ti Wisdom wa lọdọ Chinenye, ọmọbinrin naa loun ran awọn ọmọ to ku to wa lọdọ oun lati lọọ ra Indomie wa fun oun, oun si ni ki Wisdom ma tẹle wọn lọ, oun fẹẹ ba a ṣere. Lẹyin ti awọn ọmọ naa lọ tan ni Chinenye, ẹni to ti bimọ meji, mu ọmọde yii lọ sẹyinkule, to si la ori rẹ mọ ara ogiri, obinrin naa si jẹwọ pe oun tun fọ okuta mọ ọn lori titi tọmọ ọhun fi gbẹmii-mi.

Nigba ti Wisdom ku tan ni Chinenye gbe oku rẹ pamọ si tọilẹẹti ile wọn, o si ṣoju furu bii pe nnkan kan ko ṣẹlẹ, ko too di pe baba ọmọ naa ri oku rẹ nibi to sọ ọ si.

Chinenye ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe oun ko ni i lọkan lati pa ọmọ naa, oun kan fẹẹ da apa si i lori ni, ki baba rẹ le maa ri nnkan nawo le lori. Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita lọsan-an ijẹta, Sannde, wọn ni ọmọbinrin naa ṣalaye pe idi ti oun fi pa ọmọ yii ni pe baba rẹ, Samuel, lo ba ile ọmọ oun jẹ, nitori oun pẹlu baba ọmọ naa jọ n yan ara awọn lale, ọpọlọpọ oyun ni awọn si ti ṣẹ, to fi jẹ pe ile ọmọ oun bajẹ.

Ọmọbinrin naa sọ pe inu oun ki i dun ti oun ba n ri i ti ọkunrin to ba ile ọmọ oun jẹ ti oun ko fi le loyun yii ba n ba ọmọ rẹ ṣere, idi toun fi huwa toun hu naa niyẹn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti n tẹsiwaju lori iwadii wọn nipa iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi Chike Oti ti i ṣe agbẹnusọ wọn ṣe fidi rẹ mulẹ fun akọroyin wa.

 

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.