Chigozie binu para rẹ nitori ọgẹdẹ

Spread the love

Ọmọkunrin, ọmọ ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Prince Chigozie, lo ti binu pa ara rẹ bayii, o ni ẹgbọn oun ko fun oun ni ọgẹdẹ jẹ.

Abule Mmakwum, ni Obosi, to wa ni ijọba ibilẹ Idemili, nipinlẹ Anambra, niṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ lanaa, ọjọ Aje, Mọnde. Inu yara ni wọn ni ọmọkunrin naa pokunso si. Iwadii awọn oniroyin si fidi rẹ mulẹ pe baba ọmọ naa lo ri oku rẹ ninu yara to so si.

Ẹni kan to ṣofofo iroyin naa fun awọn akọroyin sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe nitori ti ẹgbọn rẹ kan ko fun un ni ọgẹdẹ jẹ ni ọmọkunrin naa ṣe binu pa ara rẹ. Wọn ni ọjọ ti pẹ ti Chigozie ti maa n sọ pe ẹgbọn oun naa ki i ṣe daadaa si oun, nitori pe oun ko niṣẹ lọwọ, ibinu eyi ni wọn ni o si ṣee ṣe ki ọmọkunrin naa fi ro gbogbo rẹ pin.

Ṣa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Mohammed Haruna, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn o ni awọn ṣi n ṣewadii lọwọ lati fidi nnkan to ṣokunfa iku rẹ mulẹ.

 

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.