Buruji Kashamu ni yoo dije dupo gomina Ogun bayii

Spread the love

 

Buruji Kashamu, Sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun Ila-Oorun ipinlẹ Ogun l’Abuja, ni yoo dupo gomina ipinlẹ Ogun labẹ PDP bayii. Adeleke Shittu ti INEC gbe orukọ ẹ jade tẹlẹ ti loun ko dije mọ.

ALAROYE gbọ pe funra Adeleke Shittu lo ni oun ko dije dupo mọ, lo ba fa kinni naa le ọga rẹ ti i ṣe Buruji Kashamu lọwọ pe ko maa ba a lọ.

 

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni agbẹnusọ Kashamu lori eto iroyin, Ọgbẹni Austin Oniyokor, sọ ọ di mimọ pe Sẹnẹtọ Kashamu ni yoo ṣoju PDP fun ipo gomina bayii, bẹẹ ni igbesẹ to yẹ lori eyi ti waye lọdọ awọn ajọ eleto idibo ilẹ wa. 

 

O ni awọn agba ninu ẹgbẹ PDP labala tawọn yii ni wọn forikori, ti wọn fẹnuko pe Buruji Kashamu lo yẹ ni ondije awọn.

 

Abala Bayọ Dayọ ni Adeleke Shittu ti jade gẹgẹ bii oludije tẹlẹ, Kashamu naa si ni baba isalẹ awọn eeyan yii ninu ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ogun to ti pin. 

 

Ohun ti a gbọ pe o fa ayipada ojiji yii ni pe gedegbe lo foju han pe ẹgbẹ PDP ko le rọwọ mu ninu ibo ọdun to n bọ yii, bi wọn ko ba tete paarọ Shittu pẹlu eeyan nla mi-in ni igun wọn. 

 

Nigba ti ko si tun sẹlomi-in to jẹ olori ẹgbẹ ju Sẹnẹtọ Kashamu lọ, iyẹn lo ṣe jẹ oun ni wọn fi paarọ Adeleke Shittu, ti yoo si dije funpo gomina lọdun to n bọ.

 

Tẹ o ba gbagbe, igun meji ni PDP pin si nipinlẹ Ogun, eyi ti i ṣe ti awọn Kashamu yii ati ti Alaga Sikirulahi Ogundele. 

 

Abala tawọn Kashamu ni ajọ INEC lawọn fara mọ, wọn ko gba ti Ọladipupọ Adebutu toun naa fẹẹ dupo gomina kan naa labala tawọn Ogundele. 

 

 

Ọrọ ọhun ṣi wa ni kootu, ko too di pe Adeleke Shittu loun ko dije mọ yii, to ni Kashamu ni ko maa ṣe e lọ.  

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.