Bukọla Saraki n lọ, o n lọ diẹdiẹ

Spread the love

O kan jẹ pe awọn eeyan ki i mọ igba ti nnkan ba bẹrẹ si i daru mọ wọn lọwọ ni, bi wọn si mọ paapaa, wọn yoo sọ pe ko to nnkan, wọn yoo maa purọ fun awọn ti wọn jọ n ṣe ni. Pe ni Kwara lasiko yii, Raheem Ọlawuyi, ọmọ ẹgbẹ APC, yoo wọle mọ awọn Saraki ti wọn sọ pe PDP lo ni Kwara lọwọ ki i ṣe apẹẹrẹ daadaa fun ọkunrin naa, o si jọ pe asiko ipalẹmọ lo wa yii, o n lọ diẹ diẹ nidii oṣelu Kwara lẹ n ri yẹn. Tabi ta ni yoo ronu pe ẹnikan le de lojiji ko doju ija kọ Saraki atawọn eeyan rẹ, ko si bori wọn, ṣebi awọn ni wọn n pe ara wọn ni Ọlọrun, ti wọn n sọ pe ko si ohun ti awọn ko le ṣe, awọn lawọn ni Kwara, ibi ti Saraki ba lọ ni Kwara n lọ. Ko si bi eeyan yoo ṣe mu awọn eeyan lọbọ to, bo pẹ bo ya, wọn yoo gbọn naa ni. O pẹ ti awọn Saraki ti n ro pe awọn ara Kwara ko lọgbọn, ka fi ounjẹ ati burẹdi pẹlu abọ irẹsi ṣekele-ṣekele ati ankara ọpa marun-un tan wọn nile Baba Oloye ni wọn ro pe awọn yoo fi maa mu wọn sin titi lae, ṣugbọn o jọ pe ọgbọn awọn eeyan naa ti n ju tiwọn lọ. Ọgbọn tuntun ti wọn gbọn ni lati gba owo lọwọ wọn, ki wọn si dibo fun ẹni to ba wu wọn. Ko ju bẹẹ lọ, nitori ọmọ to ba ni iya oun ko ni i sun ni, ko yẹ ki oun naa foju kan oorun. Oloṣelu to ba fẹẹ niyi pẹ titi laarin awọn eeyan, oloṣelu to ba n ṣe daadaa ni. Ṣugbọn oloṣelu ti wọn n pariwo ole mọ lojoojumọ, ti awọn ara Kwara naa mọ pe ko ni iṣẹ gidi kan to da silẹ lọdọ wọn, tabi ohun kan ti yoo mu idẹrun ba awọn eeyan to gbe wa si Kwara, yatọ si ko maa fun wọn ni burẹdi lasan jẹ, yoo ṣoro ki oloṣelu bẹẹ too maa niyi lọ titi aye, yoo ṣoro ko too wa nipo agbara fun igba pipẹ. Nigba ti wọn ba dibo lọdun to n bọ ni Saraki yoo mọ ipo rẹ, yoo si le boju wẹyin wo awọn aburu gbogbo to ṣe fun awọn eeyan to yẹ ko ṣetọju. Bo ba jẹ bi ibo ile aṣofin ti wọn di kọja yii ṣe ṣẹlẹ naa ni ti ọdun to n bọ ṣẹlẹ, afaimọ ki APC ma gba Kwara pata, bi wọn ba si ti gba a, ki Saraki ko ẹru ẹ gba ibomi-in lọ ni, nitori ijọba naa yoo beere awọn aburu to ṣe fawọn eeyan ipinlẹ wọn. Ọgbọn awọn ara Kwara yii wuuyan, bo ti yẹ kawọn araalu maa ṣe fawọn oloṣelu onijẹkujẹ yii niyẹn o jare.

 

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.