Buhari ti tun lọ si London

Spread the love

Lati igba ti iroyin ti jade pe Aarẹ Muhammadu Buhari tun n lọ si London lawọn eeyan ti n kun hunrunhunrun, wọn ni ki lo tun n lọọ ṣe. Loootọ alaye ti wọn ṣe lati Aso Rock ni pe Sai Baba n lọ si London lati lọọ ṣe ipade pẹlu awọn olori orilẹ-ede kan ni, yoo si tun ri olori ilẹ UK, ati Biṣọọbu agba ibẹ, awọn kan sọ pe awọn eeyan Aarẹ ko jẹwọ ohun to n ṣe wọn, wọn ni baba naa n lọ fun itọju ni.

Ohun to fa a ti awọn yii fi n sọ bẹẹ ni pe ko too di igba naa ni wọn ti kọkọ kede pe o fẹẹ lọọ sinmi diẹ ni London, afi bi wọn si ti yi kinni naa pada, ti wọn ni ipade lo n lọ. Ju gbogbo rẹ lọ Aarẹ Buhari ti gbera lanaa yii, o si ti wa ni London. O daju pe yoo ṣepade, yoo si tun gba itọju nibẹ, ko sa tete pada de ladura ọmọ Naijiria gbogbo.

(49)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.