Buhari pe Akinlade layanfẹ, lẹyin ọsẹ kan to fontẹ lu Dapọ Abiọdun

Spread the love

Lọjọ Sannde ijẹta yii, Aarẹ Muhammadu Buhari gba Gomina ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, lalejo nile ijọba l’Abuja, pẹlu ondije dupo ẹgbẹ Allied Peoples Movement(APM), iyẹn Ọnarebu Adekunle Abdulkabir Akinlade. Lọjọ naa ni Buhari sọ pe ayanfẹ ọmọ oun ni Akinlade, to si ni imulẹ oun ni Amosun.

 

Eyi waye lẹyin ọsẹ kan ti ondije dupo gomina lẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ṣabẹwo si Buhari, ti Aarẹ si nawọ rẹ soke, to ni ẹni toun fọwọ si niyẹn.

 

Amosun lo mu Akinlade de aafin Buhari lọjọ Aiku ijẹta yii, nibi ti aarẹ ti gba wọn tọwọ-tẹsẹ, to si sọ pe inu oun dun si Akinlade ti wọn tun n pe ni Triple A, oun yoo si ṣatilẹyin fun un pẹlu ẹgbẹ APM rẹ.

 

Bakan naa ni Buhari sọ pe eeyan oun pataki ni Gomina Amosun, o ni ọrẹ awọn ko ṣee fowo wọ, oun ko si ni i faaye gba ẹnikẹni lati da aarin awọn ru.

 

Ko pẹ naa ni aworan to ṣafihan Buhari, Akinlade ati Amosun gori afẹfẹ, nibi ti aarẹ wa ti n bọ Akinlade lọwọ, ati tibi tawọn mẹtẹẹta ti naka mẹrin soke, eyi to tumọ si ọdun mẹrin si i fun Buhari.

 

Abẹwo awọn alejo to de ba Buhari lati ipinlẹ Ogun yii, ati fọto to gbode lẹyin ẹ lo mu ọrọ jade latọdọ awọn awoye oṣelu.

 

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe ọgbọn Hausa ni Buhari n lo f’Amosun ati Akinlade to gbe lẹyin lọọ ba aarẹ. Wọn ni Buhari ko ni atilẹyin kan ti yoo ṣe fun ọkunrin ọmọ Ipokia to n dupo gomina Ogun yii, o kan fi ohun to sọ pe oun yoo ṣatilẹyin fun un ti i siwaju ni.

 

Bi Buhari ko ṣe nawọ Akinlade soke, gẹgẹ bo ṣe ṣe fun Dapọ Abiọdun tun jẹ kawọn eeyan maa sọ pe otubantẹ ni atilẹyin ti aarẹ loun yoo ṣe fun Akinlade ati ọga rẹ, Amosun, wọn ni irọ gbuu ni.

 

Amosun ko yee leri pe Akinlade ni ipo gomina Ogun yoo ja mọ lọwọ, eyi naa si ni wọn ṣe ṣabẹwo si Aarẹ. Triple A paapaa ti fọkanbalẹ pe ko si kinni kan ti yoo ṣẹlẹ, oun yoo di gomina ṣaa ni.

 

Idibo ku si dẹdẹ ṣa, ọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun 2019, ni. Ṣugbọn ko too digba naa, ọkan-o-jọkan iran yoo maa waye ni.

 

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.