Buhari pada de lati London

Spread the love

Aarẹ Muhammadu Buhari ti pada de lati London. Ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, ni Aarẹ ti fi orileede yii silẹ fun abẹwo ẹnu iṣẹ si olori ijọba ilẹ Gẹẹsi, Theresa May, nibi ti wọn ti jọ sọrọ nipa ajọṣe to wa laarin orileede mejeeji. Bakan naa lo tun kopa nibi ipade awọn olori orileede ajọ Commonwealth, eyi ti wọn ṣe laarin Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin, si ogunjọ, oṣu naa.
Ibi ipade yii ni Aarẹ Buhari ti sọ kobakungbe ọrọ si awọn ọdọ ilẹ wa. Lasiko to n sọrọ nibi awọn olokoowo ajọ Commowealth ọhun. Nigba ti wọn bi i leere ohun ti ijọba orileede yii n ṣe lati fi waṣẹ fun awọn ọdọ ti ko riṣẹ ṣe, Aarẹ fesi pe ọlẹ lo pọ ju ninu awọn ọdọ ilẹ Naijiria, to si jẹ pe oju ijọba ni wọn n wo lati jẹun. O ni nnkan ọfẹ ni awọn ọdọ Naijiria fẹran, alapa maa ṣiṣẹ ni ọpọ wọn.
Ọrọ yii ni awọn ọdọ ti n gba bii ẹni gba igba ọti, ti ọpọ ọdọ si ti n yọ ara rẹ kuro pe awọn ki i ṣe ọlẹ ni tawọn.
Ṣa, awọn oludamọran Buhari ti sọ pe aṣigbọ ni nnkan ti Aarẹ sọ naa, ki i ṣe bo ṣe sọ ọ gan-an lawọn eeyan ṣe n gbe e kiri.

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.