BUHARI N F’ỌBASANJỌ ṢE YẸYẸ O O ni ‘Baba ẹ lọọ sẹmpẹ!’

Spread the love

Bi Ọlọrun ba gbọ adura igbakeji aarẹ ilẹ yii tẹlẹ, Alaaji Atiku Abubakar, nnkan ko ni i rọgbọ fun ẹgbẹ APC lasiko ibo ọdun 2019 to n bọ yii. Ṣugbọn Ọlọrun ko ri bii eeyan o, nitori bẹẹ ni ko ṣe sẹni to le sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ loju ija, nigba ti Atiku ba tun koju Aarẹ Muhammadu Buhari lẹẹkan si i. Ọkunrin naa lẹni akọkọ ti yoo jade lati inu ẹgbẹ PDP pe oun fẹẹ du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn. Ni Yola, nipinlẹ Adamawa, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, Atiku ko fi bo rara, gbangba lo ti kede pe oun ko ba nnkan meji wa ju lati gbajọba kuro lọwọ Buhari lọ. O ni, “Labẹ ijọba APC, iye awọn eeyan to ti ku ni Naijiria ju iye awọn to ku ni Afghanistan, nibi ti wọn ti n jagun ẹsin lọ. Bẹẹ ni eto ọrọ aje gbogbo lo ti bajẹ, ti ohun gbogbo si ri rudurudu. Awa kan ko le fọwọ lẹran maa woye bayii mọ, dandan ni ka le Buhari lọ!”

Bo ti n sọrọ lawọn ero rẹpẹtẹ ti wọn pe n pariwo “Atiku! Atiku!”, bẹẹ ni alaga ẹgbẹ PDP, Uche Secondus, duro lẹgbẹẹ rẹ gbagbaagba, pẹlu Ọtunba Gbenga Daniel ti i ṣe adari agba pata fun eto ipolongo Atiku. Ẹni to ba ri i bi ero ti pọ to, ati bi wọn ti n pariwo orukọ ọkunrin yii, ati bi awọn mi-in ti n sọrọ naa nigboro lẹyin tọkunrin oloṣelu yii to kede pe oun fẹẹ di aarẹ tan, yoo mọ pe iṣẹ wa lọwọ Buhari lati ṣe ko too le pada si ipo to wa yii, nitori ogunlọgọ awọn ọta ni wọn ti dide si i, ọpọ ninu wọn ko si fẹẹ gba, wọn ni eyi ti awọn ṣe lẹyin ọkunrin naa ti to. Ọpọlọpọ awọn ti wọn wa ninu APC ni wọn ti n bọ silẹ ninu mọto naa, ti wọn n wọ mọto PDP, lara wọn si ni Sẹnetọ Dino Melaye, ẹni to jẹ bii aja Bukọla Saraki ti i ṣe olori ile igbimọ aṣofin agba lo ṣe maa n ṣe.

Eyi ni pe nibikibi ti Saraki ba fẹẹ lọ, paapaa to ba ti ni ọwọ oṣelu ninu, Dino Melaye yii ni yoo kọkọ ṣaaju lọ, nigba ti ọkunrin naa si ti bẹrẹ si i kọrin O-mai-o fun ẹgbẹ APC, to ni oun n pada lọ sile oun, iyẹn PDP, lawọn eeyan ti mọ pe Saraki ko ni i pẹẹ lọ. Saraki ko mọ bi yoo ṣe rin irin naa tẹlẹ, iṣoro wa lọrun rẹ gan-an nitori ẹjọ ti ijọba apapọ n ba a ṣe lọwọ, ẹjọ pe o ko owo nla jẹ lasiko to fi n ṣe gomina ipinlẹ Kwara. Ẹjọ yii ka Saraki lọwọ ko pupọ, gbogbo iya to si n jẹ ẹ ninu APC ati iwọsi to n kọlu u gẹgẹ bii olori ile-igbimọ aṣofin, niṣe lo n mu un mọra. Ṣugbọn lọsẹ to lọ lọhun-un ni ile-ẹjọ da a lare, wọn sọ ni gbangba pe omulẹmofo ni gbogbo ariwo ti ijọba apapọ n pa kiri, Saraki ko lẹjọ kankan lati jẹ. Niṣe ni Saraki fo soke, latigba naa lo si ti n ko awọn aṣofin jọ, wọn fẹẹ fi APC silẹ. Alaga ti ẹgbẹ APC ṣẹṣẹ yan, Adams Oshiomhole, ko duro ṣaa o, niṣe lo bẹrẹ si i sare kiri, bo ti n lọ sọtun-un lo n lọ sosi, ọdọ Saraki lo si kọkọ sare gba lọ ati awọn aṣofin, nitori o ti mọ pe bi Saraki ba n lọ bo ṣe n palẹmọ yii, ọpọlọpọ awọn aṣofin ni yoo sare tẹle e lọ. Oshiomhole bẹ Saraki pe ko ma binu, awọn yoo yanju ohun to wa nilẹ yii. Bẹẹ lo tun sare lọ lati ri Shehu Sani, ọkan ninu awọn sẹnetọ lati Kaduna. Ọkan ninu awọn to gba ti Saraki, to si koriira ohun ti Buhari ati awọn kan ninu APC n ṣe ni, nitori iru iya ti wọn fi n jẹ Saraki yii naa ni gomina tiwọn ni Kaduna, Nasir El-rufai, n fi jẹ oun naa, to si mu un lọtaa pata. Oun atawọn sẹnetọ meji to ku lati Kaduna yii atawọn aṣoju-ṣofin wọn nibẹ si ti mura lati fi APC silẹ fun El-Rufai, ohun ti wọn si sọ fun Oshiomhole ree, wọn lo ti pẹ ko too de.

Bi awọn aṣofin yii ti kuro ni APC yii, bẹẹ ni Gomina Benue, Samuel Ortom, naa loun n lọ o, wọn ti le oun lẹgbẹ. Kia ni Adams Oshiomhole tun sare lọ sibẹ, o ni ko jọọ, ko ma ti i lọ.  Eyi to da jinnjinni bo Buhari, Ọṣinbajo ati awọn olori ẹgbẹ APC to ku ni ipade kan to waye ni Kwara laarin awọn oloṣelu nla nla ati Saraki lọsẹ to kọja. Kinni naa ki i ṣe ipade tẹlẹ, saraa oku ni wọn n ṣe fun iya Kawu Baraje, nibẹ lawọn oloṣelu nla-nla gbarajọ si, bi wọn si ti jẹ akara oku tan, ile Saraki ni wọn gba lọ. Alaga ẹgbẹ PDP wa nibẹ atawọn aṣofin PDP to pọ rẹpẹtẹ, bẹẹ lawọn APC, nitori ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ APC tuntun ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ ni Kawu Baraje i ṣe, gbogbo eeyan lo si mọ pe ojulowo ọmọlẹyin Saraki ni. O jọ pe nibi ipade yii ni wọn ti fẹnu ọrọ jona pe awọn Saraki yoo lọ nipari oṣu keje yii.

Ọrọ yii ta de etiigbọ Oshiomhole, ni ọkunrin kukuru bii iku naa ba sare sẹsẹ, o di ọdọ Buhari, o si ba a sọrọ pe ohun to fẹẹ ṣẹlẹ yii, bo ba ṣẹlẹ tan, apa awọn ko ni i ka a. Njẹ ki lo de, Oshiomhole ni Saraki n lọ o, yoo si ko awọn aṣofin pupọ lọ, bo ba si ṣe bẹẹ lọ, wahala yoo ṣẹlẹ nibi yoowu to ba sọ ẹru rẹ kalẹ si. Ni Buhari ba sare ronu, o ranti owe awọn Yoruba to sọ pe ẹni ti yoo ba eṣu jẹun, afi ki ṣibi rẹ gun daadaa, ọrọ gbigbogun ti iwa ibajẹ kọ leyi to ṣẹlẹ yii, ọrọ bi wọn yoo ti ṣe yanju ọrọ ibo to n bọ yii ti yoo si yọri si ọdọ oun ni. N lo ba yaa ranṣẹ pe Saraki, o ni ko jọọ, ko maa bọ waa ri oun, ọrọ pataki kan wa ti awọn fẹẹ sọ. Nigba ti Saraki yoo debẹ, o ba Buhari, o ba Ọṣinbajo, o si ba Oshiomhole pẹlu awọn gomina kan. Nibẹ ni wọn ti bẹrẹ si i bẹ Saraki pe ko ma ṣe bo ti to o.

Latigba ti wọn ti ba Saraki sọrọ yii ni ko ti mọ eyi ti yoo ṣe mọ, ṣugbọn Buhari ko sinmi sisa sọtun-un sosi, gbogbo ohun ti Oshiomhole ba si sọ fun un lọwọ yii lo n ṣe. Ohun ti Baba, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ri lọsẹ to kọja niyi ti oun fi tun ju bọmbu ọrọ ranṣẹ si Buhari. O ni ṣibaṣibo ti ba ọkunrin arugbo naa, ko mọ ibi ti yoo ya si mọ, idi ti oun si fi sọ pe o ti dagba ju ko lọọ wabi kan jokoo si jẹẹ niyẹn. O ni ẹni to ni oun n gbogun ti iwa ibajẹ to jẹ labẹ rẹ ni owo nla nla ti n sọnu, awọn oloṣelu ole lo si n sare le kiri bayii nitori o fẹẹ ṣejọba lẹẹkeji. Baba yii ni ko si bi Buhari yoo ti ṣe e, idi niyẹn ti oun si fi n ko awọn toun jọ, awọn eeyan ti oun n ko jọ yii naa ni wọn yoo gbajọba lọwọ rẹ, nitori dandan ni ki Buhari lọ.

Oshiomhole binu si ọrọ yii. O ni awọn wo ni Baba Ọbasanjọ n ko jọ. O ni awọn to n kojọ yii ko yatọ si awọn agbabọọlu to ti rẹ, to waa n fi tipatipa wọ wọn si ori fiidi pe ki wọn waa gba bọọlu lati gba ife-ẹyẹ, o ni ta ni ko ti mọ pe ofo ni wọn yoo mu lori papa. Ọrọ yii lo mu awọn Buhari naa fi baba ti wọn n pe ni Ẹbọra Owu naa ṣe yẹyẹ nigba ti Fayẹmi lọọ gbe satifikeeti to fi wọle ibo fun un l’Abuja. Buhari ni baba yii kan n ko ara rẹ si wahala ni, o ti yẹ ko lọọ jokoo jẹẹ, ko wabi kan fagba ara rẹ kalẹ si (ko sẹnpẹ), ko jẹ ki alaye ṣe e. O ni ibo ti wọn di l’Ekiti yii yẹ ko ti fi han an pe gbogbo aye lo n gba toun Buhari, bi itakun ko ba si ja, ọwọ ko ni i ba ọkẹrẹ, bi ko ba lọwọ nnkan mi-in ninu, oun Buhari loun yoo wọle ibo ni 2019, aarẹ titi di 2023 loun.

Ọbasanjọ naa mọ pe awọn Buhari n foun ṣe yẹyẹ ni o. Ṣugbọn Baba Iyabọ ko ti i fesi kan.

(39)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.