Buhari binu S’Ọbasanjọ patapata

Spread the love

Ohun to ṣẹlẹ wẹrẹ lọsẹ to lọ lọhun-un, lọjọ ti aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, dariji igbakeji rẹ, Alaaji Atiku Abubakar, to si pe e ni Aarẹ-lọla ti fẹẹ da nnkan mi-in silẹ bayii o, nitori ọrọ naa ka Aarẹ Muhammadu Buhari lara, o dun awọn abaniṣiṣẹ rẹ paapaa, wọn ni Baba Ọbasanjọ ti kọja aaye ara rẹ, awọn yoo si fi i wọlẹ daadaa. Nigba ti Ọbasanjọ ti kọwe ibinu si Buhari nibẹrẹ ọdun yii, to si ti sọ fun un pe oun ko ni i ba a ṣe, to si bẹrẹ igbesẹ lati ko ẹgbẹ oṣelu tuntun jọ ni inu ti n kan Buhari si i, o si ti ni ki wọn maa ṣọ gbogbo igbesẹ rẹ, ki wọn mọ boya yoo pa wọn lara tabi ko ni i pa wọn lara. Loootọ ni awọn ọmọọṣẹ rẹ n ṣọ ọ, ti wọn n wo o lọtun-un losi, ti wọn si n ṣọ awọn ohun to n ṣe fun Buhari. Amọ nigba ti wọn gbọ pe o fẹẹ da ẹgbẹ oṣelu silẹ, ẹrin ni wọn fi i rin.
Ohun ti wọn ṣe fi i rẹrin-in ni pe wọn mọ pe ko si ẹgbẹ oṣelu kan ti baba yii yoo ko jọ niwọnba igba to ku ki wọn dibo ti yoo ṣiṣẹ, wọn mọ pe wọn yoo kan ṣe kinni naa balabala, wọn yoo tuka ni. Iyẹn jẹ ki Buhari ati awọn ọmọlẹyin rẹ jokoo wọn, ki wọn si maa ba ere aniyan bọ, wọn ni to ba jẹ ti Ọbasanjọ ni, ko si kinni kan ti yoo le ṣe, baba ti dagba, o kan n japoro lasan ni. Nitori ẹ lo ṣe jẹ gbogbo bi Ọbasanjọ ti n rin kiri, ati bo ṣe n sọrọ si Buhari, ko sẹni kan to da a lohun mọ, wọn ti ro pe ara n kan an lasan ni, wọn ni ko da ẹgbẹ oṣelu rẹ silẹ ki awọn ri i. Wọn ti mọ pe ko si bi wọn yoo ti ṣe e ti yoo ba ẹgbẹ PDP ṣe, wọn si ti mọ pe bi ko ba ti ba PDP ṣe, ko si ẹgbẹ tuntun mi-in ti wọn yoo da silẹ ti yoo sare lagbara to PDP, ti yoo si le koju Buhari ni ọjọ idibo.
Amọ lọjọ ti Ọbasanjọ gba Atiku ati awọn ojiṣẹ Ọlọrun kan, pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu PDP lalejo, to si gba a wọle gẹgẹ bii ondupo aarẹ ti oun yoo ṣiṣẹ fun, ọrọ naa da ijaya nla sọkan Buhari ati awọn eeyan rẹ, nitori ohun ti wọn ko ro rara pe yoo ṣẹlẹ lo ṣẹlẹ, ibi ti wọn ko si fọkan si rara ni ọrọ naa ba yọ. Lati igba ti kinni naa ti waa ṣẹlẹ, ti wọn ti ro pe ere ni titi, to si ti han si wọn bayii pe ki i ṣe ere ni wọn ti bẹrẹ ija, wọn ni afi ki awọn wa ohun ti awọn yoo ṣe ti wọn fi le da Ọbasanjọ duro, ko sinmi ija to n ba Buhari ja, ko ma jẹ pe ọrọ to sọ tẹlẹ pe Buhari ko ni i pada wa yoo ṣẹ mọ awọn lara. Gbogbo ọna ni wọn ti ro pe yoo fi kọyin si Atiku, paapaa nigba ti wọn ti halẹ mọ awọn ojiṣẹ Oluwa ti wọn wa nibi ọrọ naa, ṣugbọn nigba ti wọn ri i pe ko ṣiṣẹ, wọn ni wọn yoo ba ibomi-in yọ si i.
Ohun ti wọn fẹẹ ṣe ni lati halẹ mọ Ọbasanjọ, ṣugbọn eleyii ki i ṣe ihalẹ lasan, wọn ni bi ko ba jawọ, wọn yoo gba ohun to fẹran ju lọwọ rẹ naa ni. Kin ni Ọbasanjọ fẹran ju to jẹ tirẹ. Awọn eeyan naa wadii pe ko sohun to fẹran ju to jẹ tirẹ ju Ibudo Ikawe Agbaye to gbe kalẹ si Abẹokuta lọ, iyẹn Obasanjo International Library. Budo yii tobi debii pe gbogbo aye lo n wa sibẹ, bẹẹ lo si jẹ pe awọn budo agbaye, ati ijọba agbaye gbogbo lo maa n ṣeto owo diẹdiẹ sinu apo budo agbaye ti Ọbasanjọ yii, ki awọn ohun ti wọn n ṣe nibẹ le maa tẹsiwaju. Ọpọlọpọ awọn olori orilẹ-ede Afrika ni wọn maa n wa sibẹ, awọn mi-in yoo sọ ni gbangba pe awọn n bọ, awọn mi-in ko si ni i sọ rara, nibẹ ni wọn yoo si wa ti wọn yoo fi ṣeto idagbasoke ti wọn yoo lo fun orilẹ-ede wọn. Nidii eyi, gbogbo aye lo mọ Obasanjo Library.
Obasanjo Library yii ni ijọba n gbiyanju lati lo awọn EFCC ki wọn ja gba lọwọ baba naa, nitori wọn ni ki i ṣe tirẹ, wọn ni ti ijọba ni. Alaroye gbọ pe awọn ti wọn wadii iṣẹ yii ti wọn si kọwe jade nipa rẹ lati le mọ ohun ti Buhari ati awọn eeyan rẹ yoo ṣe sọ pe ohun ti Ọbasanjọ ṣe yii, iru rẹ wa ni Amẹrika daadaa. Bi olori orilẹ-ede kan ba ṣejọba rẹ, to ṣe e daadaa tan ni Amẹrika, ijọba apapọ orilẹ-ede naa ni yoo lọ si ipinlẹ ti olori ijọba atijọ naa ba ti wa, wọn yoo si lọ si ilu rẹ nibẹ, wọn yoo si kọ budo agbaye kan sibẹ fun ikawe ati itọju-iwe ati awọn ohun eelo oriṣiiriṣii. Budo naa yoo tobi, yoo si dara debii pe gbogbo aye ni yoo maa lọ sibẹ, igba gbogbo ni ijọba yoo si maa ko owo sibẹ fun wọn. Ṣugbọn ijọba lo ni in o.
Nigba ti wọn ba n mura lati kọ ibudo nla yii, wọn yoo pe gbogbo ilu, awọn olowo ati mẹkunnu, awọn eeyan nla nla ti wọn ti ri towo ṣe daadaa, wọn yoo ni ki wọn waa dawo si eto naa, bi owo ba si ti pọ to ni budo naa yoo fi tobi to, ijọba yoo kan fi owo diẹ kun un ni. Nitori bẹẹ, owo araalu ni wọn fi maa n kọ awọn budo yii, olori ijọba to ba wa nipo lẹyin ti ẹni ti wọn n kọ ọ fun ti lọ ni yoo si ṣeto naa. Iyẹn ni pe bi ko ba si wahala ti Donald Trump to wa ni Amẹrika gbe lọwọ bayii ni, yoo ti maa ṣeto bi wọn yoo ti kọ Obama Library fun un. Ati pe to ba jẹ iru eto bẹẹ ti wa ni Naijiria, ijọba Yaradua tabi ti Jonathan ni yoo kọ budo agbaye Obasanjo Library yii, ki i ṣe Ọbasanjọ funra rẹ ni yoo kọ ọ.
Ṣugbọn eto naa ko ti i bẹrẹ ni Naijiria, Ọbasanjọ si ronu lati kọ kinni naa funra rẹ, ati lorukọ ara rẹ, ṣugbọn oun naa pe awọn araalu ki wọn ba oun da si i. Ni ọjọ kẹrinla, oṣu karun-un, ọdun 2005, ni ọjọ Satide kan bayii, ni wọn ṣe ifilọlẹ Obasanjo Library yii l’Abẹokuta. Lọjọ naa, ojo owo rọ ki i ṣe kekere, nitori Ọbasanjọ ni aarẹ Naijiria nigba naa, ko si si olowo kan to wa niluu yii ti ko debẹ, gbogbo wọn pata ni wọn si dawo nla nla. Awọn bii Aliko Dangote, Fẹmi Ọtẹdọla, Mike Adenuga, Alao Ariṣekọla, Oba Otudeko, ati awọn olowo ilẹ Ibo ati ilẹ Hausa gbogbo lo n fi owo taaka laarin ara wọn, bẹẹ lawọn ileeṣẹ nla nla naa waa da si ọrọ yii, nitori wọn mọ pe ẹni to n ṣe kinni naa, aarẹ Naijiria ni. Nigbẹyin, o le ni biliọnu mẹfa owo ti Ọbasanjọ ri ko jọ laarin oṣu naa. Eleyii ki i ṣe owo kekere rara.
Lati igba naa ni wọn ti n kọ Obasanjo Library, ti wọn si ṣẹṣẹ pari rẹ ni ọdun meji sẹyin. Ohun ti awọn Buhari waa fẹẹ fa yọ bayii ni pe budo nla naa ki i ṣe ti Ọbasanjọ, loootọ orukọ rẹ ni yoo wa nibẹ, ṣugbọn ki i ṣe oun ni yoo ni in, ijọba apapọ orilẹ-ede yii ni yoo ni in, ohun ti awọn ba fẹ ni awọn si le fi ibẹ ṣe. Awọn lawọn yoo maa yan olori ileeṣẹ naa, awọn lawọn yoo maa gba oṣiṣẹ ibẹ, awọn lawọn yoo si maa ṣe akoso ibẹ, nitori ti Ọbasanjọ kọ, ṣugbọn ti ijọba Naijiria. Njẹ ki lo fa eyi, wọn ni ki i ṣe owo rẹ lo fi kọ ọ ni, ko si lẹtọọ lati lo ipo rẹ fi kọ iru nnkan nla bẹẹ, ko lẹtọọ lati lo ipo rẹ lati ni ki awọn eeyan waa da owo kan foun, bo ba si ṣe bẹẹ, ko gbọdọ jẹ lorukọ ara rẹ, orukọ ijọba apapọ lo gbọdọ fi ṣe e.
Wọle Soyinka sọ bẹẹ nigba ti wọn n kọ budo yii, o ni Ọbasanjọ ko gbọdọ ṣe bẹẹ, bẹẹ ni Gomina Orji Uzor Kalu kọwe si awọn EFCC nigba naa pe ki wọn yẹdi Ọbasanjọ wo, o fẹẹ sọ Laibiri naa di tirẹ o. Awọn iwe yii, ati awọn ọrọ yii ni awọn eeyan Buhari n ṣa jọ bayii lati fi halẹ mọ Ọbasanjọ, tabi lati fi fiya ohun to fẹẹ ṣe fun Buhari jẹ ẹ, ki wọn gba ohun ti oun naa ba fẹ kuro lọwọ rẹ. Bi eleyii yoo ṣee ṣe, bi ko ni i ṣee ṣe o, o digba naa na o.

(68)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.