Buhari bẹnu atẹ lu eeyan mẹrindinlaadọrin ti wọn pa ni Kaduna

Spread the love

Aarẹ Muhammadu Buhari bẹnu atẹ lu eeyan mẹrindinlaaadọrin ti wọn pa nijọba ibilẹ Kajuru, nipinlẹ Kaduna, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

Buhari sọrọ yii nipasẹ Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Garba Shehu, ni Satide ọsẹ to kọja pe ọrọ naa dun oun debii pe oun ko tilẹ mọ nnkan ti oun le sọ si i, ṣugbọn nnkan ti oun fẹẹ fi da awọn eeyan loju ni pe ọwọ awọn ẹṣọ alaabo yoo tẹ awọn ti wọn huwa buruku naa laipẹ, wọn yoo si fi wọn jofin.

Aarẹ ni iwa ti awọn eeyan wọnyi hu ko tumọ si nnkan mi-in ju iwa ojo lọ, tori ẹni to ba laya kan ko ni i lo iwa ipanle lasiko ibo, wọn yoo fun awọn araalu laaye lati yan ẹni ti wọn fẹ sipo aarẹ ni.

Ninu awọn eeyan mẹrindinlaaadọrin ti awọn agbebọrin naa pa ni ọmọde mejilelogun ati obinrin mejila wa, bẹẹ ni eeyan mẹrin to farapa latari iṣẹlẹ naa ṣi wa nileewosan, nibi ti wọn ti n gba itọju wọn.

Gomina ipinlẹ naa, Nasir El-Rufai, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ lori ikanni rẹ lori ẹrọ ayelujara Fesibuuku. O ba awọn mọlẹbi ti iṣẹlẹ aburu naa ṣẹlẹ si daro iku awọn eeyan wọn, o si rọ awọn eeyan naa pe ki wọn ma gbero lati gbẹsan o, awọn ẹṣọ alaabo ti bẹrẹ iṣẹ wọn lati ri i daju pe ọwọ ba awọn ọdaran naa, wọn si foju ba ile-ẹjọ.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ọrọ naa lọwọ kan oṣelu ninu nitori o ku ọla si ọjọ Satide ti ajọ INEC ti yan tẹlẹ lati dibo aarẹ ni iṣẹlẹ naa waye, bẹẹ ni awọn kan n sọ pe ko ri bẹẹ, awọn ti wọn kan fẹẹ da omi alaafia ipinlẹ ọhun ru ni wọn ṣiṣẹ naa.

(85)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.