Buhari, awọn wo gan-an ni ẹlẹmi-in eṣu o

Spread the love

Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ kan lọsẹ to kọja, ọrọ naa si fi han bo ṣe mu ọrọ awọn Fulani apaayan to n da gbogbo agbegbe ni Naijiria laamu, ati ironu to ni nipa ohun to n ṣẹlẹ gan-an. Aarẹ Buhari ni gbogbo ẹni yoowu to ba n sọ pe oun ko ṣe nnkan kan nipa ọrọ awọn apaayan yii, tabi to ba n sọ pe oun n gbe lẹyin wọn, bi a ba wo iru ẹni bẹẹ daadaa, Buhari ni ẹlẹmi-in eṣu kan ni yoo jẹ, o ni eṣu lo n gbe inu ẹni to ba sọ pe oun wa lẹyin awọn apaayan to n pa wọn ni Benue ati Plateau. O ni bawo loun ṣe le jẹ ki wọn maa pa awọn to wa nibẹ, ti oun yoo sọ pe ki wọn pa wọn run, nigba to ṣe pe ibo rẹpẹtẹ ni wọn di foun lati ibẹ wa. Lara iṣoro ti Buhari ni gan-an niyẹn, ọrọ to wa nilẹ yii, wọn ko moju to o nitori wọn ti sọ ọ di ọrọ oṣelu. Ṣe ọrọ to wa nilẹ yii, ṣe ọrọ ibo ni abi ọrọ iku ati iye! Ọrọ ibo la n sọ yii ni abi ọrọ aabo fun gbogbo Naijiria, nigba to ṣe pe ohun ti wọn n tori ẹ yan ijọba sipo niyẹn. Ọrọ ibo didi la n sọ yii ni abi ọrọ pe ki ẹni to wa lori aga ijọba ṣe ohun to yẹ ko ṣe. Buhari gan-an ni ko yẹ ara rẹ wo, ko si yẹ ọrọ to wa nilẹ yii wo, ko too maa pe ẹnikan ni ẹlẹmi-in eṣu, tabi ko too sọ pe gbogbo ẹni to ba pe oun lapaayan, eṣu lo n ba tọhun ja. Bi Buhari ba yẹ ọrọ naa wo, yoo ri i pe oun loun ko ṣe ohun to yẹ ki oun ṣe, idi si ree ti gbogbo eeyan fi tẹnu mọ ọn pe oun gan-an lapaayan. Buhari doju ija kọ awọn Boko Haram, gbogbo aye si ri i bo ṣe ja ija naa, ko si sẹnikan ti yoo sọ pe ko ṣe ohun to yẹ ko ṣe, nitori o da awọn ṣọja sibẹ, ija naa si lọ rẹpẹtẹ, lẹsẹkẹsẹ si ni awọn Boko Haram naa fẹyin rin lọ, ti agbara wọn si dinku si ti bo ṣe wa tẹlẹ. Nigba ti awọn ọmọ Ibo ti wọn ko ni ohun ija oloro rara, ti wọn ko si pa ẹnikẹni, ti wọn ko si ba ẹnikẹni ja n leri kiri pe awọn fẹẹ da Biafra silẹ, ṣebi lẹsẹkẹsẹ ni ijọba Buhari yii kan naa ṣeto awuruju kan, to ko awọn ṣọja lọ sibẹ, ti awọn yẹn paayan rẹpẹtẹ, ti wọn si ji olori awọn ọmọ Biafra naa gbe lọ, titi di bi a ti n wi yii, ẹnikẹni ko gburoo wọn mọ. Ki lo waa de ti Buhari ko le ṣe bẹẹ fun awọn Fulani to n paayan kiri. Lojoojumọ ni wọn n paayan, lojoojumọ ni ijọba n sọ pe awọn daro, lojoojumọ ni Buhari n sọrọ tutu fawọn eeyan pe ki wọn ni suuru fawọn Fulani yii, ṣe awọn Fulani yii ni suuru fẹnikan ni. Ohun ti gbogbo awọn ti wọn ni Buhari ni apaayan ṣe n pe e bẹẹ niyẹn, ti wọn si n wo o pe ko ṣe kinni kan si ọrọ awọn Fulani. Bi ọrọ naa ba ka aarẹ lara, ko si ohun meji ti ko ṣe ju ko paṣẹ fun awọn ṣọja bayii bayii lọ, ko paṣẹ naa ki gbogbo aye gbọ, ko sọ pe ki wọn mu gbogbo Fulani apaayan ti wọn ba ri nibikibi balẹ, ko si fi awọn ṣọja naa silẹ lati ṣe iṣẹ wọn. Bo ba ti ṣe bẹẹ, ti awọn Fulani to n paayan kiri yii naa ba bẹrẹ si i ku lojiji, ti wọn n run awọn naa tọmọtọmọ ati ti maaluu ti maaluu, iwọnba awọn to ba ku yoo gbe jẹẹ, wọn ko si ni i paayan kiri ilẹ yii mọ. Iyẹn gan-an lo le ko Buhari yọ. Ṣugbọn to ba fawọn Fulani apaayan silẹ ti wọn n paayan kiri, ti oun naa si jẹ Fulani, apaayan ni wọn yoo maa pe e titi lae. Ko ju bẹẹ lọ.

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.