Bọọlu eti okun: Naijiria gba ipo keji lẹyin aṣekagba pẹlu Senegal

Spread the love

Ikọ agbabọọlu eti okun ilẹ Naijiria, Super Sand Eagles, ti gba ipo keji nibi aṣekagba idije Africa Beach Soccer Cup of Nations to waye lorilẹ-ede Egypt lopin ọsẹ to kọja. Nibi ayo naa ni Naijiria ti jiya ami-ayo mẹfa si ẹyọ kan.

Abu Azeez lo gba bọọlu wọle fun Naijiria laarin iṣẹju kan ti ayo bẹrẹ, aṣe mo-yo iya ni Super Sand Eagles yoo jẹ lọwọ Senegal. Lati iṣẹju keji ni Mamour Diagne ti ṣide goolu fun Senegal, bẹẹ ni Lansana Diassy, Babacar Fall ati Raoul Mendy ju bọọlu sawọn, ki Diagne too pada fọba le e.

Eyi lo mu Naijiria padanu ipo kin-in-ni, bẹẹ ni Egypt di ipo kẹta mu lẹyin ti wọn lu Morocco lami-ayo mẹta si meji.

Ni bayii, Senegal, Naijiria ati Egypt ti yege lati lọ si idije agbaye ọdun to n bọ nilẹ Paraguay.

Ilẹ Senegal lo ṣe daadaa ju ninu idije Afrika yii latigba to ti bẹrẹ, nitori awọn lo gba kọọpu lọdun 2008, 2011, 2013, 2016 ati tọdun yii, nigba ti Naijiria gba a lọdun 2007 ati 2009.

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.